INEC Nigeria
INEC Nigeria ni àjọ elétò ìdìbò lorílẹ̀-èdè Nàìjíríà ni a dá sílẹ̀ ní ọdún 1998. Ìjọba àpapọ̀ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà da a sílẹ̀ láti mójú tó ètò ìdìbò gbogbo lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ìtàn bí àjọ yìí ṣe bẹ̀rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìdásílẹ̀ àjọ yìí bẹ̀rẹ̀ kí Nàìjíríà tó gba omìnira. Wọ́n dáa sílẹ̀ láti ṣètò ìdìbò lọ́dún 1959 wọ́n pè é ní lédè gẹ̀ẹ́sì ní Electoral Commission. Lọ́dún 1960, lẹ́yìn òmìnira, wọ́n tún dá àjò elétò ìdìbò mìíràn silẹ̀ tí wọ́n pè ni Federal Electoral Commission (FEDECO). Fẹ̀dẹ́kò (FEDECO) yìí ló ṣe ètò ìdìbò lẹ́yìn òmìnira orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sí àwọn ipò ìjọba àpapọ̀ àti àwọn ìjọba ẹlẹ́kùnjẹkùn tí Nàìjíríà ní nígbà náà lọ́dún 1964 àti 1965. Àwọn ìjọba ológun tí wọ́n fipá gba ìjọba lọ́dún 1966 ni wọ́n tú àjọ ìdìbò FEDECO ká. Lọ́dún 1978, ìjọba ológun tí Ààrẹ Olúṣẹ́gun Ọbásanjọ́ dá àjò elétò ìdìbò mìíràn sílẹ̀ tí wọ́n pè ní Federal Electoral Commission, (FEC). Àjọ yìí ni ó ṣètò ìdìbò tí ó gbé Alhaji Shehu Shangari wọlé gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ orílẹ̀ èdè Nàìjíríà lọ́dún 1979. Àjọ tuntun yìí ló tún ṣètò ìdìbò lọ́dún 1983. Nígbà tí ó di oṣù kejìlá ọdún 1995, ìjọba ológun Sani Abacha dá àjọ elétò ìdìbò mìíràn sílẹ̀ tí ó pè ní National Electoral Commission of Nigeria, àjọ yìí ló ṣètò ìdìbò lásìkò náà, ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n wọlé ìbò kò ṣe ìbúra sípò kí Sani Abacha tó kú lọ́dún 1998. Ní kété tí ìjọba ológun Abdulsalam Abubakar gba ìjọba, ó tú àjò ìdìbò yìí ká, ó sì ṣe àtúnda àjọ elétò ìdìbò mìíràn tí ó pè ní Independent National Electoral Commission (INEC). Àjọ ìdìbò INEC yìí ló ṣètò ìdìbò ní fún àwọn adíje lọ́dún 1999, tí wọ́n sì búra wọlé fún wọn ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù karùn-ún ọdún 1999, èyí tí ń ṣe ètò ìṣèjọba àwarawa ẹlẹ́kẹrin. Àjọ elétò ìdìbò INEC yìí ló sì ń ṣètò ìdìbò lorílẹ̀ èdè Nàìjíríà títi di báyìí.[1] [2] [3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "INEC Nigeria – Independent National Electoral Commission". INEC Nigeria – Independent National Electoral Commission (in Èdè Hungaria). 2019-09-30. Retrieved 2019-11-18.
- ↑ "ELECTORAL COMMISSION THROUGH THE YEARS". Nigerian Voice. 2010-06-07. Retrieved 2019-11-18.
- ↑ "Nigeria’s 2003 Elections - The Unacknowledged Violence". Human Rights Watch. 2004-06-01. Retrieved 2019-11-18.