Jump to content

Àkàyé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àkàyé èyí ni kíkà àpilẹ̀kọ kan ní àlàyé yálà fún ìdánwò, bí ó bá jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tàbí fún ìgbádùn ara ẹni. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà ní ìṣòro ma ń dojúkọ àwọn olùkó láti kọ́ àwọn ọmọ ní àkàyé. Lára irú àwọn ìṣòro tí ó ma ń wáyé nínú ìwé kíkà ní wi pé ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́ lè dá ìró mọ̀ yàtọ̀ sí ara wọn. Ní ọ̀pọ̀ ìgbà ni ó tún jẹ́ wípé ọkàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kìí sábà sí nínú ohun tí wọ́n ń kà, eléyí yóò fa ìṣòro àti lè dáhun ìbéèrè tí ó bá wà lórí àkàyé bẹ́ẹ̀.[1] Olùkọ́ tí ó fẹ́ kọ́ àkàyé pàá pàá gbọ́dọ̀ jẹ́ olùkọ́ tí ó lè sọbèdè Yorùbá dára dára, tí ó sì pegedé nínú rẹ̀, tí ó si jẹ́ ẹni tí ó mọ òwe àti ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú èdè Yorùbá. Olùkó tún gbọ́dọ̀ ko àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn nkan wònyí (a) Kíkà ìwé fún ìtumò (b) Ọgbón íkèwe (d) Ọgbón ibeere (e) Ọgbón ìdáhùn (e)Kíko Akẹ́kọ̀ọ́ ní Òrò àti Ìtumò. Wàyí o, láti wa kó àkàyé gan-an-gan, olùkó níláti gbẹ́ àwọn ìgbésì wònyí:

  • Kíkà ìbí àyokà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́
  • Pípé ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ka àyokà
  • Dídáhùn àwọn ibeere pèlú ohùn ẹmu
  • Gbígbà àwọn ìdáhùn sílè nínú ìwé won.
  • Gbígbà ìwé àwọn akẹ́́kọ̀ọ jó fún ìfówósí
  • Lílò àwọn fokabulari titun ni òrò.

Àwọn Ìtọ́ka sí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]