Jump to content

Àrùn Chagas

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àrùn Chagas
Àrùn ChagasPhotomicrograph of Giemsa-stained Trypanosoma cruzi
Àrùn ChagasPhotomicrograph of Giemsa-stained Trypanosoma cruzi
Photomicrograph of Giemsa-stained Trypanosoma cruzi
Ìpínsọ́wọ̀ àti àwọn òkunfà ìta
ICD/CIM-10B57. B57.
ICD/CIM-9086 086
DiseasesDB13415
MedlinePlus001372

Àrùn Chagas /ˈɑːɡəs/, tàbí àrùn traipanosomiasisi Amẹrika, jẹ́ irúfẹ́ àrùn ajẹlójú-onílé kan ni ilẹ̀-olóoruabẹ̀mí protosoa tí a tún mọ̀ sí Trypanosoma cruzi[1] n ṣe okùnfà rẹ̀. Irúfẹ́ Àwọn kòkòrò eégbọn kan ni í máa n tàn án káàkiri.[1] Ìmọ̀lára àrùn náà máa n yípadà bí àrùn náà bá ti bọ́ sí ará ẹnìkan. Ní ìbẹ̀rẹ̀ rẹ̀, aláìsàn kì í sáàbà mọ̀ ọ́ lára tàbí kí ó máa ṣe é fẹ́ẹ́rẹ́fẹ́, tí ó sì lè mú àìsàn ibà, ará-wíwú àwọn kànga omi-ẹ̀jẹ̀, tàbí ẹ̀fọ́rí lọ́wọ́, tàbí kí ojú ibi tí kòkòrò náà ti buni jẹ wú.[1] Lẹ́yìn ọ̀ṣẹ̀ 8 sí 12, ni onítọ̀hún náà yóò bọ́ sínú àìsàn náà gan an gan an, tí ó sì jẹ́ pé ìdá 60 sí 70 ninu ọgọ́rùn ún ni kì í rí ìmọ̀lára àrùn tí ó ju èyí náà lọ.[2][3] Tí ìdá 30 sí 40 ninu 100 àwọn ènìyàn sì máa n ní àwọn ìmọ̀lára àrùn míràn sí lẹ́yìn ọdún 10 sí 30 tí àrùn náà ti kọ́kọ́ wọ wọ́n lára.[3] Díẹ̀ lára àwọn ìfarahàn àrùn yìí ni kí àwọn fẹ́ntíríkù ọkàn-ènìyàn tóbi gan an tí bí i 20 sí 30 ninu 100 sí máa n yọrí sí kí ọkàn ṣíwọ́-iṣẹ́.[1]gògò-n-gò gbẹ̀ǹgbẹ̀ kan tàbí abọ́dìí kọlọbọ náà sì lè jẹ́ àrùn tí yóò ṣe àwọn 10 ninu 100 àwọn ènìyàn míràn.[1]

Okùnfà ati Ìtọpinpin

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

"Kòkòrò eégbọn" mùjẹ̀mùjẹ̀ tí í ṣe ìbátan awọn kòkòrò-àrùn Triatominae ni ó máa n tan ààrùn T. cruzi sí ara àwọn ènìyàn ati ti àwọn ẹranko-abirun-lára míràn.[4] Àwọn kòkòrò yii ní oríṣiríṣi orukọ tí wọn máa n pè wọn ní awọn agbegbe kọọkan,bí i: vinchuca ní ilẹ̀ Arjentina, Bolifia, Shile ati Paraguay, barbeiro ( onígbàjámọ̀) ni wọn n pè é; ní ilẹ Brasili, wọn n pè é ní pito ní ilẹ̀ Kolombia, ò n jẹ́ chinche ní Ààrin-gbùngbùn Amẹrika, ati chipo ní ilẹ Fenesuela. Awọn ààrùn náà a tún máa tàn kálẹ̀ nípaṣẹ̀ gbigba ẹjẹ sí ara, pípààrọ̀ ẹya-ara, jìjẹ ounjẹ tí ó ní awọn kòkòrò àrùn yii nínú, àti láti ara ìyà sí ọlẹ̀.[1] Ìtọ́pínpín àrùn yìí ṣeéṣe tí àrùn náà kò bá tí ì pẹ́ lára nípa lílo ẹ̀rọ máíkrósíkópù fún ṣiṣe àwárí kòkòrò àrùn nàá.[3] Tí àrùn náà bá ti pẹ́ lára, nípasẹ̀ títọ́pínpín àwọnakọ́dà-ara tó máa n bá T. cruzi jà nínú ẹ̀jẹ̀ ni a tún fi lè ṣe àyẹ̀wò àrùn yìí.[3]

Dídèná Àrùn náà àti Gbígba Ìtọ́jú

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Pípa àwọn kòkòrò eégbọn run àti kí a má ṣe jẹ́ kí wọn bù wa jẹ ni ọna kan pátákì láti dènà àrùn yìí.[1] Àwọn ọna ìgbìyànjú míràn láti dènà àrùn náà tún ni yíyẹ ẹ̀jẹ̀ wò kí a tó gbà á sára.[1] Kò sì tí ì sí abẹ́rẹ́ àjẹsára kan fún un títí di ọdun 2013.[1] Àísàn naa ṣe é wò tí kò bá tí ì wọra dáadáa pẹlu lílo ògùn benznidazole tàbí nifurtimox.[1] Àwọn ògùn yìí lè mú àrùn náà kúrò lára pátápátá tí a bá tètè bẹ̀rẹ̀ sí ní lò wọn sugbọn iṣẹ́ wọn yoo dinkù bí àrùn Chagas bá ti n pẹ́ lára.[1] Tí a bá lo àwọn ògùn yìí fún àrùn tí ó ti pẹ́ lára, wọn lè dá àwọn ìmọ̀lára òpin àrùn dúró tàbí kí wọn dènà ìfarahàn wọn.[1] Benznidazole àti nifurtimox tún máa n fa àwọn àìbáradọgba kan tí kò pẹ́ títí lára àwọn eniyan 40 ninu 100 [1] àwọn bí i ìṣáká ara, májèlé ọpọlọ àti dídá wahala sílẹ̀ fun àkópọ̀ àwọn ẹ̀yà-ara tí n mú oúnjẹ dà lára.[2][5][6]

Ìtànká àti Ìdẹ́kun Àrùn náà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ó fẹ̀rẹ̀ tó miliọnu 7 sí 8 ènìyàn, pàápáá ní ilẹ Meksiko, Ààrin-gbùngbùn Amẹrika àti ilẹ Gúsù Amẹrika ti wọn ní àrùn Chagas.[1] Èyí yọrí sí ikú àwọn ẹ̀gbẹ̀rún mejila àbọ̀ ènìyàn ní ọdun 2006.[2] Ọ̀pọ̀ àwọn tí àrùn náà mú ni wọn jẹ́ akúṣẹ̀ẹ́[2] tí ó tún jẹ́ pé ọ̀pọ̀ nínú wọn ni kò tilẹ̀ mọ̀ pé àwọn ní àrùn náà lára.[7] Òbítíbitì àwọn ènìyàn tí n ṣí lọ láti ibikan sí òmíràn tún mú àwọn agbègbè tí àrùn Chagas náà ti n ṣe ọṣẹ́ fẹ̀ sì i, tí Ilẹ́ Gẹẹ̀́sì àti Ilẹ̀ Amẹrika sìn bẹ lára wọn pẹ̀lú.[1] Ọ̀pọ̀ àwọn agbègbè náà sì ni àrù yìí tún ti gbilẹ̀ sí i títí dé ọdún 2014.[8] Carlos Chagas ni ó kọ́kọ́ ṣàpéjúwe àrùn yìí ní ọdun 1909. Òun náà sí ni a ṣe n fi orúkọ rẹ̀ pe àrùn náà.[1] Àrùn yìí pẹlu a máa wà lára irúfẹ́ àwọn ẹranko bí i àádọ́jọ míràn.[2]

Àwọn Àtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.00 1.01 1.02 1.03 1.04 1.05 1.06 1.07 1.08 1.09 1.10 1.11 1.12 1.13 1.14 1.15 "Chagas disease (American trypanosomiasis) Fact sheet N°340". World Health Organization. March 2013. Retrieved 23 February 2014. 
  2. 2.0 2.1 2.2 2.3 2.4 Rassi A, Rassi A, Marin-Neto JA (April 2010). "Chagas disease". Lancet 375 (9723): 1388–402. doi:10.1016/S0140-6736(10)60061-X. PMID 20399979. 
  3. 3.0 3.1 3.2 3.3 Rassi A, Jr; Rassi, A; Marcondes de Rezende, J (June 2012). "American trypanosomiasis (Chagas disease).". Infectious disease clinics of North America 26 (2): 275–91. doi:10.1016/j.idc.2012.03.002. PMID 22632639. 
  4. "DPDx – Trypanosomiasis, American. Fact Sheet". Centers for Disease Control (CDC). Retrieved 12 May 2010. 
  5. Bern C, Montgomery SP, Herwaldt BL, et al. (November 2007). "Evaluation and treatment of chagas disease in the United States: a systematic review". JAMA 298 (18): 2171–81. doi:10.1001/jama.298.18.2171. PMID 18000201. 
  6. Rassi A, Dias JC, Marin-Neto JA, Rassi A (April 2009). "Challenges and opportunities for primary, secondary, and tertiary prevention of Chagas' disease". Heart 95 (7): 524–34. doi:10.1136/hrt.2008.159624. PMID 19131444. http://heart.bmj.com/cgi/pmidlookup?view=long&pmid=19131444. 
  7. Capinera, John L., ed (2008). Encyclopedia of entomology (2nd ed. ed.). Dordrecht: Springer. p. 824. ISBN 9781402062421. http://books.google.ca/books?id=i9ITMiiohVQC&pg=PA824. 
  8. Bonney, KM (2014). "Chagas disease in the 21st Century: a public health success or an emerging threat?". Parasite 21: 11. doi:10.1051/parasite/2014012. PMC 3952655. PMID 24626257. //www.pubmedcentral.nih.gov/articlerender.fcgi?tool=pmcentrez&artid=3952655.  open access publication - free to read