Jump to content

Àwùjọ Haúsá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àwùjọ Haúsá

Àwọn òpìtàn bíi Basil (1981), gbìyànjú láti ṣàlàyé bí àwọn Hausa ti sẹ̀. Agbede méjì ni ó ti mú ìtàn sọ. Pàtàkì ohun tí ó sọ ni ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹ̀ ní ìlú kan tí ń jẹ́ Daura. A gbọ́ pé kanga kan ṣoṣo ló wà nínú ìlú yìí àti pé ejò kan wà ní inú kanga ọ̀hùn ti kì í jẹ́ kí àwọn ará ìlú pọnmi àyàfi tí ó bá jẹ́ ọjọ́ jímọ́ọ̀. Ìtàn ọ̀hún ṣàlàyé pé àjòjì kan tí ń jẹ Bayajidda wọ ìlú wá, ó pa ejò yìí. Ọba ìlú náà tí ó jẹ́ obìnrin sì di ìyàwó àjòjì ọ̀hún. Ṣe ẹní bá ni ẹrú ni ó ni ẹrù, ẹní fẹ́ ọba ti di ọba. Ìtàn sọ pé àwọn ọmọ mejé tí ọkùnrin ọ̀hún bí ni wọ́n dá àwọn ìsọ̀rí méje tí Hausa ní sílẹ̀. Wọ́n ní àwọn ọmọ méje ti àlè rẹ̀ bí ni wọ́n tẹ ìlú méje yòókù dó. Méje tó jẹ́ ojúlówó ni ‘Hausa Bakwai’ nígbà ti méje yòókù jẹ ‘Banza Bakwai’. Awọn Hausa Bakwai ni Biram, Daura, Katsina, Zaria, Kano, Rano ati Gobir. Àwọn méje yòókù ni Zamfara, Kebbi, Gwari, Yauri, Nupe, Yorùbá àti Kwararafa.

Ìtàn ti Stride àti Ifeka (1982) sọ ni a fẹ́ mú lò nínú iṣẹ́ yìí. Ìtàn tó wà lókè yìí náà ni wọ́n sọ ṣùgbọ́n wọn ṣe àfikún díẹ̀. Wọn tọ́ka sí àkọsílẹ̀ kan tí ọjọ́ rẹ̀ ti pé jọjọ tí ń jẹ́ “Kano chronicles”. Wọ́n lo àkọsílẹ̀ yìí láti ṣàlàyé pé ọkùnrin kan tí ń jẹ Bàgódà ni ó kọ́kọ́ jọba ní ìlú Kano. Wọn ni nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni ọba ọ̀hún jẹ (A.D. 1000). Wọn ní àkókò yẹn ni ìgbà tí àwọn Hausa bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọ sí abẹ́ àkóso ìlú síṣe. Àtúnsọ ìtàn tí wọ́n sọ gbà pé ọmọ Bayajida ni gbogbo Hausa ka ara wọn kún. Wọ́n ní Abuyazid gan-an ni orúkọ rẹ̀. Wọ́n ní ọmọ ọba ìlú ‘Baghdad’ ni. Wàhálà àna rẹ ló jẹ́ kó sá kúrò ní ìlú. Ó ṣe àtìpó díẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn ìran Kànúrí (ìpínlẹ̀ Borno). Nígbà tí ó dé ibi kan tí ń jẹ́ ‘biram ta gabas’, O fi iyawo re sílẹ̀ nibẹ. Onítọ̀hún sì bí ọmọkùnrin kan síbẹ̀. Ní ìlú Gaya (Ìpínlẹ̀ Kano) ó ṣe alábàábàdé àwọn alágbẹ̀dẹ kan tí wọ́n jáfáfá púpọ̀, wọ́n bá a ṣe ọ̀kọ̀ kan. A gbọ́ pé ọ̀kọ̀ yìí ni ó lò láti fi pa ejò tí ń dààmú àwọn ará ìlú Daura tí ó sì fi bẹ́ẹ̀ di ọba wọn. Ìtàn yìí sọ fún wa pé Gwari ni orúkọ ẹrúbìnrin tí ó bi àwọn ọmọ méje tí wọ́n wà ní ìsọ̀rí kejì fún un. Ìtàn yìí tàn ìmọ́lẹ̀ díẹ̀ sí ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Hausa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pe iran Hausa ti tan kálẹ̀ kaakiri àgbáyé àwọn Hausa tí wọ́n jẹ́ onílé àti onílẹ̀ ni apá òkè ọya ni orílẹ̀èdè Nàìjíríà ni a ní lọ́kàn nínú iṣẹ́ yìí. Lára àwọn ìpínlẹ̀ ọ̀hún ni Sokoto, Katsina, Zamfara, Kebbi, Kano, Jigawa, Kaduna, Gombe àti Plateau.