Àwọn ènìyàn Nambya

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àwọn ènìyàn Nambya jẹ́ àwọn ẹ̀yà kan tí iye wọn tó ọgọ́rùn-ún ẹgbẹ̀rún 100,000 people, tí wọ́n sì ń gbé ní apá àríwá ìwọ̀ oòrùn Zimbabwe àti ní apá àríwá ìlà oòrùn ti Botswana . Wọ́n wà ní Hwange, ní àyíká Victoria Falls àti ní àwọn ìlú àríwá ìlà oòrùn Botswana bi: Pandamatenga, Chobe, Maremaoto, Gweta, Shorobe, Tsienyane, Zoroga, Chumo, Makalamabedi, Sankoyo, Lesoma, Xhumo, Mopipi, Broadhurst, Rakops, Shoshong, Palapye àti Maun. [1] Wọ́n so ìlú Hwange àti Hwange National Park lórúkọ tẹ́lé ọba BaNambya tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sawanga , tí àwọn ènìyàn Nambya sì padà ń pè ní Hwange.

Àwọn ènìyàn BaNambya tún ń gbé ní agbègbè Hwange National Park, èyí tí ó tóbi sìkejì jùlọ ní Áfríkà lẹ́yìn Kruger National ParkSouth Africa. Àwọn ènìyàn Nambya tún tan mọ́ Kalanga. Wọ́n wá láti Zimbabwe, wọ́n sì ségun àwọn ẹ̀yà kọ̀kan bi àwọn ẹ̀yà Kalanga nígbà tí wọ́n ń kó lọ Hwange, Victoria Falls àti àríwá ìlà oòrùn Botswana.

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. Hasselbring, Sue; Segatlhe, Thabiso; Munch, Julie; Project, Basarwa Languages (2001-01-01) (in en). A sociolinguistic survey of the languages of Botswana. Tasalls. pp. 6. ISBN 9789991293271. https://books.google.com/books?id=OnVkAAAAMAAJ&dq=nambya+hwange&q=hwange.