Amos Tutuola
Amos Tutuola | |
---|---|
Ọjọ́ìbí | Abeokuta, Nigeria | Oṣù Kẹfà 20, 1920
Aláìsí | June 8, 1997 Nigeria | (ọmọ ọdún 76)
Orílẹ̀-èdè | Nigerian |
Gbajúmọ̀ fún | Author |
Amos Tutuola (Yorùbá: Ámósì Tutùọlá; tí wọ́n bí ní 20 June 1920, tó sì ṣaláìsí ní 8 June 1997) jẹ́ òǹkọ̀wé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tó kọ ìwé lórí àwọn àlọ́ Yorùbá.
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ayé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Amos Olatubosun Tutuola Odegbami ní 20 June 1920, ní Wasinmi, èyí tó jẹ́ ìlú tí ò jìnà púpọ̀ sí Abeokuta, ní Nàìjíríà. Ibẹ̀ ni àwọn òbí rẹ̀ Charles Tutuola Odegbami àti Esther Aina Odegbami, tí wọ́n jẹ́ àgbẹ̀ oníkòkó ń gbé.[1][2] Wasinmi jẹ́ ìlú kékeré tí wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ oko, tí wọ́n dásílẹ̀ ní ọdún 1845 wọ 1880[3] láti ọwọ́ Egba subethnic group láti Abeokuta. Bàbá Tutuola àti bàbá-bàbá rẹ̀ jẹ́ ọmọ-ẹgbẹ́ yìí.
Amos jẹ́ ọmọkùnrin bàbá rẹ̀ tó kéré jù lọ, ìyá rẹ̀ ni ìyàwó kẹta. Bàbá-bàbá rẹ̀ ni Odafin ti ìlú Egba, Chief Odegbami (c. 1842–1936). Òun sì ni bàbá-ńlá àwọn ìdílé Odegbami, wọ́n jẹ́ olóyè àti ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀.[4] Àkọ́lé rẹ̀ "Odafin" (túmọ̀ sí "ẹni tó dá òfin" tàbí "aṣòfin"), ó sì tún jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Iwarefa ti Ogboni.
Ìgbà tí Amos di ọmọdún méje, ní ọdún 1927, ó di ìránṣẹ́ fún F. O. Monu, tó jẹ́ ọmọ Igbo. Ẹni yìí ló ran lọ ilé-ìwé Salvation Army pẹ̀lú owó-oṣù rẹ̀. Ní ọmọdún méjìlá, ó lọ Anglican Central School ní Abeokuta. Ọdún mẹ́fà ló fi kàwé, láti ọdún 1934 wọ 1939).[5] Ìgbà tí bàbá rẹ̀ kú ní ọdún 1939, Tutuola fi ilé-ìwé lè láti lọ kọ́ṣẹ́ àgbẹ̀dẹ. Ó kọ́ iṣẹ́ yìí láti ọdún 1942 wọ 1945 fún Royal Air Force ní Nàìjíríà lásìkò WWII. Lẹ́yìn náà, ó gbìyànjú iṣẹ́ mìíràn bí i títa búrẹ́dì àti ṣiṣe ìránṣẹ́ ní Nigerian Department of Labour. Ní ọdún 1946, Tutuola parí ìwé rẹ̀, tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ The Palm-Wine Drinkard, láàárín ọjọ́ méjì.[6] Ní ọdún 1947, ó fẹ́ Victoria Alake níṣu lọ́ka, wọ́n sì jọ bí ọmọkùnrin mẹ́rin àti ọmọbìnrin mẹ́rin, ó sì tún padà fẹ́ ìyàwó mẹ́ta mìíràn.[7] Òun ni àbúrò bàbá agbábọ́ọ̀lù Segun Odegbami ài Wole Odegbami.[8]
Àá̀yàn àwọn ìwé rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- The Palm-Wine Drinkard (1946, published 1952)
- My Life in the Bush of Ghosts (1954)
- Simbi and the Satyr of the Dark Jungle (1955)
- The Brave African Huntress (1958)
- Feather Woman of the Jungle (1962)
- Ajaiyi and his Inherited Poverty (1967)
- The Witch-Herbalist of the Remote Town (1981)
- The Wild Hunter in the Bush of the Ghosts (1982)
- Yoruba Folktales (1986)
- Pauper, Brawler and Slanderer (1987)
- The Village Witch Doctor and Other Stories (1990)
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Amos Tutuola". biography.yourdictionary.com (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 5 March 2022. Retrieved 2022-03-05. Unknown parameter
|url-status=
ignored (help) - ↑ Gale, Cengage Learning (2016). A Study Guide for Amos Tutuola's "The Village Witch Doctor". Gale, Cengage Learning. ISBN 9781410361806. https://books.google.com/books?id=jNp5DQAAQBAJ&q=victoria+alake+odegbami&pg=PT6.
- ↑ Harunah, H. B. (1983). "Sodeke: Hero and Statesman of the Egba". Journal of the Historical Society of Nigeria 12 (1/2): 109–131. JSTOR 41971356. https://www.jstor.org/stable/41971356. Retrieved 29 November 2020.
- ↑ Timothy T. Ajani (Fall 2012). ""He Being Dead Yet Speaketh": The Legacy of Amos Tutuola". Journal of Nigeria Studies 1 (2). http://www.unh.edu/nigerianstudies/articles/Issue2/The_Legacy_of_Amos_Tutuola.pdf. Retrieved 18 February 2020.
- ↑ Fatunda, Tayo (June 16, 1997). "Weaver of fantasy". The Guardian (London): p. 13. https://www.newspapers.com/clip/107837855/tayo-fatunda-weaver-of-fantasy-the/.
- ↑ "Amos Tutuola". The Daily Telegraph (London): p. 33. June 19, 1997. https://www.newspapers.com/clip/107838317/amos-tutuola-the-daily-telegraph/.
- ↑ Gale, Cengage Learning (2016). A Study Guide for Amos Tutuola's "The Village Witch Doctor". Gale, Cengage Learning. ISBN 9781410361806. https://books.google.com/books?id=jNp5DQAAQBAJ&q=victoria+alake+odegbami&pg=PT6.
- ↑ Segun Odegbami (2014). Me, Football and More: A Selection of the Media Writings of "Mathematical" Segun Odegbami. AuthorHouse. ISBN 9781491886335. https://books.google.com/books?id=7GY6AwAAQBAJ&q=tutuola&pg=PT24.
- Pages with script errors
- Pages with citations using unsupported parameters
- CS1 Èdè Gẹ̀ẹ́sì-language sources (en)
- Pages containing cite templates with deprecated parameters
- Pages using infobox person with unknown parameters
- Infobox person using ethnicity
- Pages to import images to Wikidata
- Articles containing Yorùbá-language text
- Àwọn ọjọ́ìbí ní 1920
- Àwọn ọjọ́aláìsí ní 1997
- Àwọn ará Nàìjíríà
- Àwọn olùkọ̀wé ará Nàìjíríà