Èdè Gẹ̀ẹ́sì Áfríkà Amẹ́ríkà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

Àpèjá AAVE duro fun African-American Vernacular English, ìyen ni, ede Geesi tí àwon ọmọ Afrika Amerika n so ni ile Amerika. Òkan nínú àwon èdè àdúgbò ni. Àwon orúko mìíràn tí wón tún ń pe èdè yìí ni Black English Vernacular (BEV), Afro-American English àti Black English. Àwon àmì ìdámò èdè yìí ni pé won kì í lo ‘s’ tí ó jé àtóka eni kéta eyo, bí àpeere, She walk , won kìí lo be, bí àpeere, They real fine. wón sì máa ń lo be láti tóka ibá atérere bárakú, bí àpeere, Sometime they be walking round here. A kò le so pàtò ibi tí èdè yìí ti sè. Àwon kan so pé láti ara kirio (Creole) ni sùgbón àbùdá rè kòòkan tí a ń se àkíyèsí rè lára èdè Gèési tí won ń so ní gusu Àméríkà jé kí àwon kan gbà pé láti ara èdè Gèésì ni ó ti wáyé. Èdè yìí wá ní àbùdá tirè nígbà tí àwon dúdú kojá sí àwon ìlú ńláńlá. wón wá ń lo èdè yìí gégé bí àmì àdámò fún ara won.


Ọmọ Afrika Amerika