Jump to content

Ègé ìró

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ègé ìró ní ìgbàkúùgbà tí ènìyàn bá ń tàkurọ̀sọ, ìró ni  a máa ń gbọ́. Ohun kan pàtàkì tí ó ya ènìyàn sọ́tọ̀ sí àwọn ẹ̀dá mìíràn ni ìró èdè/ìfọ̀. Ìró ni ẹni tí ó sọ̀rọ̀ lò láti gbé èrò rẹ̀ jáde, ìró yìí kan náà ni ẹni tí ó gbọ́ ọ gbọ́, tí ó sì fún un ní ìtumọ̀ láti ní òye ohun tí ẹni tí ó ń sọ̀rọ̀ ń sọ.

Ó yẹ kí á mọ̀ pé, kìí ṣe gbogbo ìró tí ènìyàn lè dá pè tàbí gbé jáde ni ìró èdè/ìfọ̀. Àpẹẹrẹ ni bí ọmọdé bá ń sunkún tàbí bí ènìyàn bá yán, àwọn ìró wọ̀nyí kìí ṣe ìró èdè/ìró ìfọ̀. Owólabí (2013:14) ki ìró ifọ̀ báyìí:

Ìró ifọ̀ ni ègé tí ó kéré jùlọ tí a lè (fi etí) gbọ́ nínú èdè

Ohun tí ó ṣe pàtàkì nínú oríkì yìí ni: ègé ìró tí ó kéré julọ, ohun kejì ni nínú èdè. Ìyẹn ni pé ìró tí kò bá ti ní nǹkan ṣe pẹ̀lú èdè, kò lè ṣe é kan mọ́ ìró èdè kan. Àpẹẹrẹ kan tí ènìyàn lè fi sí ọkàn ni àwàdà tí àwọn kan máa ń ṣe nípa ọmọ kan tí ó sunkún pàdé ọlọ́dẹ orí kan. Wèrè yìí bi ọmọ yìí ìdí rẹ̀ tí ó fi ń sunkún, ọmọ náà fẹ̀sì pé olùkọ́ ohun ní òun ò mọ̀wé. Wèrè yìí bá fa ọmọ náà lọ́wọ́ lọ bá olùkọ́, ó bi olùkọ́ bí ó bá lè sípẹ́lì gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó wà nínú èdè rẹ̀. Olùkọ́ fi ìdánilójú dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni. Wéré bá pòsé, ó ní kí olùkọ́ sípẹ́lì rẹ̀. Ọ̀rọ̀ bá di wò mí, kí ń wò ọ́.

A ó ṣàkíyèsí pé, olùkọ́ náà kò lè sípẹ́lì òsé nítorí pé òsé kìí ṣe ègè ìró ìfọ̀, ìdí nìyí tí Owólabí (2013) fi ṣàlàyé pé, yàtọ̀ sí oríkì, ohun mìíràn tí a gbọdọ̀ fi sọ́kàn nípa ìró ifọ̀ ni pé, wọ́n ṣe é dàkọ. Ọ̀nà méjì ni a lè gbà láti da àwọn ìró yìí kọ. Àwọn náà ni lílo lẹ́tà àti lílo àmì. Bí a bá wa lo òsùnwọ̀n dida ìró kọ ti à ń sọ yìí, a jẹ́ pé a lè pín ìró èdè Yorùbá sí ìsọ̀rí méjì gbòòrò. Ìsọ̀rí méjéèjì náà ni ègé ìró àti ègé ìró alágbèékà.

   Ègé Ìró

Ègé ìró ni ìró tí a máa ń dà kọ nípa lílo lẹ́tà. Ẹ̀yà méjì sì ni irú àwọn ìró bẹ́ẹ̀ pín sí. Ẹ̀yà kan ni àwọn ìró tí à ń pè ní Kọ́nsónáǹtì. Ẹ̀yà kejì sì ni àwọn ìró tí à ń pè ni fáwẹ́lì (wo Owólabí 2013:14).

Ègé ìró alágbèékà

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwọn ìró tí a máa ń dà kọ nípa lílo àmì yàtọ̀ sí lẹ́tà ni a mọ̀ sí ègé ìró alágbèékà. Àpẹẹrẹ irú ìró bẹ́ẹ̀ nínú èdè Yorùbá ni ìró ohùn. Ẹ̀yà mẹ́ta ni wọ́n pín sí: òkè [ ́ ], àárín  àti ìsàlẹ̀ [`].

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]