Ìṣègùn ìbílẹ̀

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Is̩é̩ ìs̩ègùn jé̩ ò̩kan gbòógì nínú is̩é̩ ìs̩è̩ǹbáyé Yorùbá, ààbò è̩mí àti dúkìá pè̩lú wíwa ojútùú sí onírúurú ìs̩òro è̩dá ni kókó tí is̩é̩ ìs̩ègùn dálé. Ewé, egbò àti gbogbo è̩dá yàlá abè̩mí, tí ó wà ní orí – ilè̩ àti inú omi ni wó̩n ń lò fún is̩é̩ ìs̩ègùn.  

Àjò̩ ètò ìlera àgbáyé (World Health Organization sọ pé Oògùn ìbílè̩ ni ìlànà ìs̩èwòsàn tó ti wá tipé̩tipé̩ fún bí o̩go̩ò̩gò̩rún-un o̩dún s̩áájú ìdàgbàsókè àti ìtànkalè̩ oògùn ìgbàlódè. Ìlànà yìí tún wà ní lílò títí di òní ní ò̩pò̩lo̩pò̩ orílè̩èdè. Àjo̩ àgbáyé s̩àkíyèsí pé ó wà ní ìbámu pè̩lú ìlànà amúlùdúùn àti às̩à àjogúnbá onírúurú orílé̩èdè àgbáyé (WHO 1991.

ÌPÍNSÍSÒ̩RÍ ÌṢÈGÙN ÌBÍLẸ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

ARE̩MO̩[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí ni wó̩n ń lò fún aboyun láti ìgbà tó tí ń wá o̩mo̩, títí tó fí dá os̩ù sí; do̩jó̩ ìkúnlè̩ rè̩, àti ní kété tí á bá gbóhùn ìyá gbó̩ to̩mo̩, wó̩n ń lò ó bákan náà láti fi to̩jú o̩mo̩dé.

  1. Oògùn abíwé̩ré̩
  2. Oògùn agbè̩bí
  3. Oògùn apàrùn aboyún
  4. Aró̩mo̩bí
  5. Ìmú aboyún lára dá
  6. Ìmú ara fúyé̩
  7. Ìmú è̩jè̩ dúró
  8. Ìmú obìnrin bímo̩
  9. Ìmú obìnrin lóyún
  10. Ìmú-oyún dúró
  11. Oògùn aràn obìnrin
  12. Oògùn è̩dà
  13. Oògùn è̩yo̩
  14. Oògùn o̩mú
  15. Díde àbíkú.

ÌWÒSÀN[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wó̩n fi irúfé̩ èyí kojú àìsàn tàbí àrùn tí ó ń bá è̩dá jà. Àwo̩n èmí àìrí tàbí àìsàn yòówù tí ìbá máa bé̩dàá jà ni às̩afò̩ yóò máa ró̩ o̩fò̩ lé lórí, kí àlááfíà ba lè padà sí ara aláìsàn. Lára àwo̩n àìsàn tí wó̩n fí ń wò ní wò̩nyìí:

  1. È̩fó̩rí
  2. Oró – ejò
  3. Inú rírun
  4. Ikó̩ wíwú
  5. Ibà ati bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ

ÌS̩Ó̩RA[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìs̩ó̩ra: Yorùbá bò̩, wó̩n ní onílé o̩wó̩ o̩tún kò fojú ire woni, ìmò̩ràn ìkà ni tòs̩ì ń gbà. Tí ò̩rò̩ ebi bá kúró nínú ìs̩é̩, tí è̩dá kó táwó̩ná, nǹkan tí è̩dá yóò máa lé pè kí òun má kú ní rèwèrèwe àti pé kí apá àwo̩n pare – dà- so̩ré dibí má ka òun. Ló̩rò̩ kan s̩áá, è̩dá máa ń fé̩ kí òun dé ‘òké – e̩ni – apá – ò – ká.   Ìs̩ó̩ra ni è̩dá lè lò láti gbá ara rè̩ sílè̩ ló̩wó̩ àwo̩n e̩ni ibi. Ènìyàn tún lè lo as̩ààbò láti kápá àjàkálè̩-àrùn tí àwo̩n ajogun lè fi báni jà. Orísìí irúfè̩ isora ti o wa ni:

  1. Agbélépòtá
  2. Àyà-kò-gbèdì
  3. Apàs̩e̩
  4. Aró̩bi
  5. È̩rò̩ S̩àngó
  6. È̩rò̩ mágùn
  7. È̩rò̩ ìránsí s̩ànpò̩nná
  8. È̩rò̩ ìránsí ejò

ÀWÚRE[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àwùre o̩ló̩ja oògùn jé̩ èyí tó ń fa ìdágìlò̩ ire bá è̩dà. Oògùn tí a fi ń wú ìre lá à pè ní àwúrè, ire sì lè̩dá ń fé̩ kó te̩ òun ló̩wó̩. Tí ènìyàn bá  ip é òun wà láyé bí aláìsí, nǹkan tó kàn ni pé kí ó wá wò̩rò̩kò̩ fí s̩àdá nípa s̩ís̩e àwúre láti fa ò̩pò̩ló̩pò̩ ire tí ó ń wá bá a. Tí è̩dá bá sì rí I pé è̩mí òun dè lórí àrùn tàbí ikú, nńkan tó kan irúfé̩ è̩dá  bé̩è̩ máa lé ire ilé ayé. Níwò̩n ìgbà tó jé̩ pé orís̩iírìs̩íí ni àwúre tí a lè bá pàdé, orís̩iírìs̩íí ìtàn àmús̩agbára rò̩ mó̩ àwúre pò̩ lo̩ jàra:

  1. Atórís̩e (èyí ní I tún orí tí  kò sunwò̩n s̩e)
  2. Ìyàsí (Ó wà fún yíyà òs̩ì kúrò lára è̩dá)
  3. Ìfé̩ràn
  4. Ìtajà
  5. Awó̩rò
  6. Ìsangbèsè
  7. Ipò gíga
  8. Olúpòkìkí
  9. Ìfé̩yàwó/Ìló̩ko̩
  10. Bámikó̩le (àwúre tí è̩da fí n rí e̩ni tí yóò kó̩lé fún un)

AKÒ̩YÀ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

O̩mo̩ awo kì í jìyà, bí ò̩nà bá sì fé̩ dí mó̩ o̩mó̩ awo, dandan ni kó s̩e ìs̩e awo. Bí ìyá bá fé̩ to̩ lé o̩mo̩ awo, dandan ni kó gbo̩n ìyà náà nù. Ìyá kíkò̩ mìíràn lè la ti è̩mí nígbà tí a ń gba ara e̩ni kúrò nínú ìyo̩nu. Nǹkan tí ó ń fà á tí wó̩n fí ń lo irúfé̩ ìtàn àmús̩agbára yíì nígbà mìíràn lè jé̩ pé as̩afò̩ fé̩ fi ajulo̩ hàn e̩ni tó fi o̩wó̩ pa idà rè̩ lójú, e̩ni bá juni lo̩ lè juni nù. Díè̩ lára wo̩n ni:

  1. Afò̩ran
  2. Títa è̩dá ní ìjàmbá
  3. Ìsàsí
  4. Èèdi
  5. Abilù
  6. È̩fún
  7. Gbètugbètu
  8. Àpèpa/Àpèta
  9. Títé̩ è̩dá {ki eda siwahu

DÁN – ÀN – GÙN[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Èyí ni àwo̩n pidán pidán/onídán máa ń lò látí fi s̩e is̩é̩ kàyéfì lójú agbo. Wó̩n máa ń lo irúfé̩ èyí láti jé̩ kí nǹkan tí kò s̩éé s̩e dí s̩ís̩e.


Ìwé Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orímòògùnjé̩ C.O. (1996), Lítírés̩ò̩ Alohùn Yorùbá Lagos: Káróhunwí Nigeria Enterprises.


Diméjì Ajíkòbi: (2013), Ìs̩ègùn Ìbílè: E̩ja n bákàn?

Fábùnmi M.A. (1976), Àyájó̩ Ìjìnlè̩ Ohùn Ifè̩ Oníbo̩nòjé Press.

Pierre F. V. (1995), Ewé: The Use of Plants in Yoruba Society, Oderbrecht, Brazil.