ÌWÚRE NÍBI ÌFỌBA ALÁDÉ JẸ
ÌWÚRE NÍBI ÌFỌBA ALÁDÉ JẸ
Oyè jíjẹ tí ó jẹ́ ti Ọba aládé ni ó jẹ́ olúborí gbogbo àwọn oyè yòókù. Ṣé ọba Aladé ni yóo fi àwọn ti yóó bá jẹ oyè kékéèké yòó kù jẹ, kì báà ṣe oyè àdúgbò ní ìlú ni, tàbí èyí tó jẹ mọ́ baálẹ̀ ní àwọn ìlú kéréje. Tí a bá sì fẹ́ fi oyè dá èniyàn lọ́lá, Ọba Aládé ní àṣẹ láti fi oyè dá ẹni tó bá wù ú lọ́lá.
Ní ayé àtijọ́ àwọn tí a mọ̀ ní ilẹ̀ Yorùbá gẹ́gẹ́ bí Ọba, Aládé kò pọ̀. Nínú wọn ni Aláàfin, Aláké, Ọ̀ràngún, Ọọ̀ni, abbl.
Ní ayé òde-òní , ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ si fún ọ̀pọ̀ àwọn ọba ní adé. Eléyìí tó mú àwọn Ọba tí ń dádé pọ̀ si i. Ẹni tí wọn yóó bá fi joyè ní láti jẹ́ akọni, kí ó sì ní iwà rere. Yàtọ̀ sí èyí, ó ní láti ti ìdílé tí ó n jẹ oyè wá. Àwọn Ọba aládé ni ó ń ṣe àkóso ìlú ńláńlá, àṣẹ wọn sì tún múlẹ̀ ní àwọn ìletò pẹ̀lú.
Ìgbadé ọba kì í ṣe nǹkan tó máa n wáyé nígbà gbogbo, nítorí wí pé bí ọba kan kò bá kú tàbí kí àwọn ará ìlú kọ̀ ọ́ kí wọn ó sì rọ̀ ọ́ lóyè, ọba kan kò jẹ. Lẹhin tí ọba kan bá ti gbésẹ̀, àwọn ìdílé tí ń fọba jẹ yóò fi ọmọ oyè sílẹ̀. Its Ìta yóò sì jẹ́rìí sí i wí pé wọn tọ̀nà. Lóde òni, ìjọba ní ń fi àṣẹ sì i. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ igbésẹ̀ ni ó wà tí ọba yóò gbé kí ó tó di wi pé ó jẹ ọba, èyi sì yàtọ̀ láti ilú kan sí èkeji. Ohun tó dájú ni wí pé nígbà tí wọ́n bá fẹ́ fi adé fún ọba, wọn yóò wúre fún un.
ÌWÚRE NÍBI ÌFỌBA JẸ̀
Ìbà àwọn ará ìṣáájú,
Kábiyèsi.
Adé á pẹ́ lórí,
Bàtà á pẹ́ lẹ́sẹ̀,
Ìrùkẹ̀rẹ̀ á pé lọ́wọ́ o.
Aláṣekù yóó ba yín ṣe é;
Ẹ ò ní fi ọ̀kùnrùn s'Ọba,
Àlàáfíà lo ó máa fi ṣe é.
O ó ṣe é pẹ́ títí o.
Àláṣekù yóò máa ba yín ṣe é.
Àwọn ìlú, wọn ò ní kọhùn yín;
Ẹ̀yin náà, ẹ ò ní kohùn àwọn ilú o.
Adé á pẹ́ lórí,
Bàtà á pẹ́ lẹ́sẹ̀
A ò ní fi elòmíràn ṣe yín o.
Ìgbà ẹrù, ìgbà òṣùká,
Ọlọ́run ní í bá ni gbé e;
Ẹ é rù ú lárùyè o,
Kò ní wọ̀ yín lọ́rùn o.
Asikò tiyín, ìlú á tòrò,
jlú á rójú,
Gbogbo ọmọ ìlú tí ń bẹ ní ìdálẹ̀,
Wọn ó máa kóre délé.
Wọn ó máa lọ láyọ̀,
Wọn ó máa bọ̀ láyọ̀
Ẹ ẹ̀ ní sìṣe,
Àwọn áboyún, wọn á bí tibi tire,
Àwọn àgàn, wọn á tọwọ́ ààlà bosùn.
Àwọn abiyamọ, Olúwa á dá ọmọ wọn sí.
Kábíyèsí,
Ìlú á tòrò lásìkò tiyín,
Asikò tẹ́ ẹ wà lórí oyè yií,
llú á máa gbòòrò ni.
Ẹ ẹ̀ ní ṣíṣe,
Àwọn tó ń lọ, tó ń bọ̀,
Àti ará ilé,
Àti ará oko,
Àti èrò ìdálẹ̀,
Asikò tiyín,
Wọn yóo mọ̀ ọ́n sí rere.
Kígbà tiyín ó tù wá lára;
Àwọn aláṣekù, wọn ó máa ba yín ṣe o.
Àṣẹ.