Ìfipá gba Maersk Alabama
Ìfipá gba Maersk Alabama jẹ́ àtẹ̀léra ìṣẹ̀lẹ̀ orí omi tì ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ajalèlókun merin tí wọ́n fi ipá gba ọkọ̀ ojú omi ẹ̀lẹ́rù, MV Maersk Alabama ogòjílénírinwó máìlí (440 km; 280 mi) gúúsù-ìlàoòrùn Eyl, Somalia. Ìdíwọ́ yìí parí lẹ̀yin akitiyan Ológun ojú omi U.S. lati gbàwọn sílẹ̀.[1] Ó jẹ́ àkọkọ́ àṣeyọrí ìfipá gba ọkọ̀ ojú omí tí yio ṣélè́ lati bíi ọ̀kànlélógun ọgọrún ọdún sẹ́yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìyábọ̀ ìròyìn jẹ́ kó di mímọ̀ wípé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bíì tó ṣẹlẹ̀ kẹ́yìn wáyé ní ìgbà Ogun Barbary Kejì ní ọdún 1815, b́ótilẹ̀jẹ́ wípé irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ ti wáyé bí ọdún 1821 sẹ́yìn.[2] Ó jẹ́ ìkẹfà ọkọ̀ ojú omi ẹ̀lẹ́rù, tí àwọn ajalèlókun tí wọ́n ṣẹ̀sẹ̀ gba owó ìdásílẹ̀ rọgùrọ́gù mílíọnù dọ́là máa dojú kọ.
Ìtàn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí di àkọsílẹ̀ ní 2010 nínú ìwé A Captain's Duty: Somali Pirates, Navy SEALs, and Dangerous Days at Sea tí Stephan Talty àti Captain Richard Phillips tí wọ́n jẹ́ ọ̀gá nínú ọkọ̀ yìí nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀ kọ́. ìfipá gbà ọkọ̀ yìí tún jẹ́ ìwúrí fún eré Captain Phillips tí wọ́n ṣe ní ọdún 2013.
Àwọn àkíyèsí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Sanders, Edmund; Barnes, Julian E. (9 April 2009). "Somalia pirates hold U.S. captain". Los Angeles Times. http://articles.latimes.com/2009/apr/09/world/fg-somali-pirates9. Retrieved 12 April 2009.
- ↑ McShane, Larry (8 April 2009). "Americans take back cargo ship Maersk Alabama after it was hijacked by Somali pirates". New York Daily News. http://www.nydailynews.com/news/us_world/2009/04/08/2009-04-08_somali_pirates_seize_usflagged_cargo_ship_with_21_american_sailors_says_diplomat.html. Retrieved 8 April 2009.