Jump to content

Ìhun sílébù

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìhun sílébù, odo àti apààlà sílèbù ni à ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Owólabi (2013:137) ṣàlàyé pé bí a bá pe sílébù sí ìta, odo sílébù ni a máa ń gbọ́ ju apààlà sílébù lọ. Ó tún ṣàlàyé pé, odo sílébù yìí ni agbátẹrù ohùn àti pé, kò sí sílébù tí kò ní odo sílébù nínú ìhun rẹ̀. Nítorí náà bí sílébù bá ní ègé ìró kan soso, ègé ìró náà ni yóó dúró gẹ́gẹ́ bí odo sílébù.

Sílébù lè ní apààlà sílébù nínú ìhun rẹ̀ tàbí kí ó máà ní. Àmọ́ sá, bí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìhun sílébù èdè Yorùbá, ìró kọ́nsónáǹtì ni ó máa dúró gẹ́gẹ́ bí apààlà sílébù nígbà tí ìró fáwẹ́lì àti ìró kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù sì máa ń dúró gẹ́gẹ́ bí odo sílébù. Wà á ṣàkíyèsí pé ìró fawẹ́lì ni ó máa ń gba ohùn, ìró kọ́nsónáǹtì kìí gba ohùn  àyàfi ìró kọ́nsónáǹtì aránmú asesílébù. Nítorí ìdí yìí ni ìró kọ́nsónáǹtì àti fáwẹ́lì fi gba oríkì Fonọ́lọ́jì gẹ́gẹ́ bí a ti fi hàn saájú ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ Móòdù ìkínní, ìkejì àti ìkẹta tí a ó tún ṣe ìtẹnumọ́ rẹ̀ níbí kí ó lè rọrùn láti rántí.

Ìró kọ́nsónáǹtì ni ó máa ń siṣẹ́ apààlà sílébù

Ìró fáwẹ́lì ni ó máa ń síṣẹ́ odo sílébù

Nǹkan pàtàkì tí oríkì òkè yìí fi yé wa ni pé, kò fàyè gba ìró kọ́nsónáǹtì aránmú asesílébù gẹ́gẹ́ bí i ìró kọ́nsónáǹtì nítorí pé kò lè síṣẹ́ apààlà sílébù bí i àwọn kọ́nsónáǹtì yòókù. Ìdí gan-an tí ó fi yàtọ̀ sí àwọn kọ́nsónáǹtì tókù nìyẹn. bí ó tilẹ̀ jẹ́ kọ́nsónáǹtì, òun nìkan ni kọ́nsónáǹtì tí àyè gbà láti síṣe odo sílébù.

Ẹ̀ya Ìhun Sílébù

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ̀yà ìhun sílébù mẹ́ta ni ó wà ní èdè Yorùbá, àwọn náà ni:

Fáwẹ́lì

Kọ́nsónáǹtì àti Fáwẹ́lì

Kọ́nsónáǹtì Arámú Asesílébù

A lè fi lẹ́tà rọ́pò gẹ́gẹ́ bí àrokò tí yóó máa dúró fún wọn báyìí

F= Fáwẹ́lì

KF = Kọ́nsónáǹtì àti Fáwẹ́lì

N = Kọ́nsónáǹtì Arámú Asesílébù

Àpẹẹrẹ tí a ó lò láti fi ẹ̀yà ìhun sílébù hàn nínú èdè Yorùbá ni

A  dé  wá    lé

F   KF  KF  KF

A  lá     ǹ  gbá

F   KF  N  KF

A  bí   m  bọ́  lá

F  KF N  KF KF

Àwọn ìwọ̀nyí dájú nipa ẹ̀yà ìhun sílèbù tí a ṣàlàyé yìí:

Sílébù lè ní ègé ìró kan soso nínú ìhun rẹ̀, bí èyí bá rí bẹ́ẹ̀, ègé ìró yóó jẹ́ ìró fáwẹ́lì tàbí kí ó jẹ́ kọ́nsónáǹtì aránmú aṣesílébù. Àmọ́ sá, bí sílébù bá ní ju ègé ìró kan soso lọ, a jẹ́ pé ègé ìró náà yóó jẹ́ ìró kọ́nsónáǹtì àti fáwẹ́lì ní tẹ́léǹtẹ̀lé.

Kọ́nsónáǹtì kìí parí sílébù èdè Yorùbá,

Èdè Yorùbá kò fàyè gba ìsùpọ̀ kọ́nsónáǹtì (ìyẹn ni kí kọ́nsónáǹtì méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tẹ̀lé ara wọn ní tẹ̀léǹtẹ̀lé).

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]