Ìjọba Ìbílẹ̀
Ìrísí
(Àtúnjúwe láti Ìjọba Ìpínlẹ̀)
Ìjọba Ìbílẹ̀ jẹ́ ìpele ìjọba ẹlẹ́kẹta àti irúfẹ́ ìjọba tí ó jẹ́ ti àwa-ara-wa lẹ́sẹ̀ kùkú ti ó wà ní abẹ́ ìjọba Ìpínlẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan lábẹ́ ìlànà ìṣèlú àwa-ara-wa.[1] Ìjọba ìbílẹ̀ ma ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ òfin àti àlàkalẹ̀ òfin orílẹ̀-èdè bí àwọn aṣòfin (legistlatives) àti àwọn amòfin (Judiciary) ṣe gbe kalẹ̀ ní orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan. Nínú ìlànà étò Ìjọba Àpapọ̀ (Federal State), ìjọba ìbílẹ̀ ló sába ma ń wà ní ipò kẹta nínú étò ìṣèlú. [2]
Ẹ̀wẹ̀ àgbékalẹ̀ étò Ìjọba ìbílẹ̀ yàtọ̀ síra wọn ní orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè ní agbáyé. [3]
Àwọn Ìpínsísọ̀rí ìjọba
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìpínsísọ̀rí ìjọba lábẹ́ ìjọba apapọ̀ (Federal Government) lábẹ́ ìjọba àwa-ara-wa (Democrcy), ṣe pàtàkì. Ìlànà ìṣèlú lábẹ́ ìjọba Àpapọ̀ pín sí ọ̀nà Mèta.
- Ìjọba Àpapọ̀. Èyí ló ń ṣàkóso ìjọba méjèjì ìsàlẹ̀
- Ìjọba Ìpínlẹ̀, ẹ̀yí jẹ́ ìjọba àárín tó tún lágbara ju ìjọba ìbílẹ̀ lọ
- Ìjọba Ìbílẹ̀ tabí ìjọba ẹsẹ̀ kùkú ti ó kángun sí àwọn ará-ìlú. [4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "Definition, Examples, & Responsibilities". Encyclopedia Britannica. Retrieved 2020-06-09.
- ↑ "Definition of LOCAL GOVERNMENT". Definition of Local Government by Merriam-Webster. 2020-05-22. Retrieved 2020-06-09.
- ↑ Level, Education (2014-06-04). "What Is Local Government? - Definition, Responsibilities & Challenges - Video & Lesson Transcript". Study.com. Retrieved 2020-06-09.
- ↑ "Local Government". Encyclopedia.com. 2020-05-23. Retrieved 2020-06-09.