Ìjọba Mbata
Ìrísí
Ìjọba Mbata jẹ́ orúkọ tí wọ́n ń pe ìjọba Bantu kan ní àríwá Mpemba Kasi, kí wọ́n tó dà wọ́n pọ̀ mọ́ Ìjọba Kongo ní ọdún 1375 CE.[1][2]
Gégé bí arobá, wọ́n dá ìjọba Kongo kalẹ̀ nígbà tí Nima a Nzima fẹ́ Luqueni Luansanze, ọmọ Nsa-cu-Clau, olóyè àwọn ènìyàn Mbata. Ìgbéyàwó wọn sọ ìbásepọ̀ àárín Mpemba Kasi àti àwọn ènìyàn Mbata, ìbásepọ̀ yìí ni ó jẹ́ Ìpìlẹ̀ dídá ìjọba Kongo. Nima a Nzima àti Luqueni Luansanze, wọ́n ní ọmọ tí ó ń jẹ́ Lukeni lua Nimi, òun ni ó padà di ẹni àkọ́kọ́ láti di Mutinù (ọba) [3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ "A Short History of the Kingdom of Kongo". Archived from the original on 2018-10-03. Retrieved 2023-05-04.
- ↑ History Files: Kongo Kingdom
- ↑ "Kingdom of Kongo 1390 – 1914 | South African History Online". www.sahistory.org.za. Retrieved 2022-09-12.