Ìlú Òró

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Ilu Oro

 1. Lábáńbí la ti bí mi lórí omi òsà
 2. Ìlú se é wà lórí omi?
 3. Mo mò pébéèrè tí yóò kó so sí wa lókàn nù-un
 4. Bí n ó bá fún-un yín nídáhùn tó ye
 5. Ko ní yéé ko wá ní háà! 5
 6. Nítorí kí ni ń kó?
 7. Nítorí bírú èyí bá sè
 8. Tílùú forí omi selé
 9. Tómi ń be níwá, tí ń be léyìn
 10. Tí ń be lótùn-ún, tí ń be lósì 10
 11. Tó wa jé pé ìwònba ìyàngbe
 12. Ilè tí ń be láàárín
 13. Lá wá dó lé gégé bí ìlú
 14. Erékùsù nìlúù mi nù-un
 15. Erékùsù, ilè tómí yípo pátápátá poo 15
 16. Tí ò séni ó lè débè láìwokò ojú omi, okò olópón
 17. Ìyún-ùn ni pé
 18. Erékèsù Lábáǹbí ni mo forí solè sí
 19. Ibè la bí mi, tí mo forí rìn dé
 20. Ìrókò se wá se bí eré wá so osàn? 20
 21. Tí mo fi Lábáǹbì sílè dára Òró
 22. Ìyen ni pé
 23. Bawo ni mo se dará ìlú Òró?
 24. Èyí ò le
 25. Bí mo se dará ìlú Òró kò le páàpáà 25
 26. Ogun ló gbalé, totè gbòde kan
 27. Ìyen nígbà tá a bí mi
 28. Ń se ni rògbòdùyàn gba gbogbo sánmò lókè
 29. Ìlú wa ò kúkú tóbi, rébété báyìí ni
 30. Kò pé tí wón bí mi tógun kólùú wa terú tomo 30
 31. Eni tó bá mí pínkín
 32. Ń se ni wón ní kénu rè ya dépàkó
 33. Wón ní á panu mó, á yéé pera wa lára Lábáǹbí
 34. Wón ní látojó ùn gan-an la ti dará Òró
 35. Mo rò ó 35
 36. Mo rú u
 37. Mo là á
 38. N ò já a
 39. Emi la wá lè se? Emi la lè so?
 40. Olórun ló dá o léjó tó o fé pe kòtémilórùn un 40
 41. Ìyà tólúwa rè yóò je sí i, kò ní í mo ní wín-ńwín
 42. Àbí téni ó mádàá lówó bá ni á káwó sókè
 43. Òsé là á tún máaá pá?
 44. Àfeni tí ó se tán láti jÓlorun nípè
 45. Eni tó gbórí míìn pamó sílé 45
 46. Tí yóò fi pààrò èyí tó bá lo
 47. Báyìí ni mo se domo ìlú Òró
 48. Tí mo gbàgbé ìlú àbínibí mi
 49. Mo domo ìlú Òrò tán nù-un nì
 50. Isé ológun ni mo gbà 50
 51. Sóhun ló kúkú pé jù ní sáà yìí
 52. Mò ń gbàsé ológun tan
 53. Ń se nìgbéga ń tèlé ìgbéga fún mi
 54. Ó wá bùse gàda, ó bùse gèdé
 55. N làwon mèkúnnù panu pò 55
 56. Pé báwon olówó se ń sèjoba
 57. Ò táwon lórùn
 58. N ni won bá pòbìrìkòlò
 59. Tí wón gbára jo, tí wón láwon ó kòwòsí
 60. Sémi náà ti mobi tÓlórun ó ti bepo sí bòòlì fún mì 60
 61. Mo dara pò mó àwon púrúǹtù
 62. A réyùn àwon olówó ayé
 63. Àwon ajeniséni, àgbòn ìsàlè bí ìkéèmù
 64. Àwon wònyí wáà pàmò pò
 65. Wón ní ń wá solórí àwon 65
 66. Mo dolórí Òrò ìlú ròsòmù
 67. Sùgbón kò sí bá a ó ti sèfó òdú tí ò ní í rùngbé
 68. Isẹ́ ogun tí mo fi dolórí kò kúò lókàn-àn mi
 69. Àfì bí èyí kí ìlú Òró máà fè sí i lábé ìtójúù mi
 70. Nǹkan sì ń jé fún èmi náà 70
 71. Àfi bí èyí pé mo wègbo
 72. Àfi bí èyí pé mo fosé rarí
 73. Bí mo bá ìlú iwá jà, n ó ségun
 74. Bí mo bá tèyìn jà, n ó ségun
 75. Ìgbà ó wá se 75
 76. N ló wá dàbí èyí pé kí n dolórí gbogbo ilú
 77. Tí ń be ládùúgbòo tàwa
 78. Sùgbón àwon tí ń be ládùúgbòo mi ò ponú
 79. Béè ni, won ò pòdà
 80. Ń se láwon náà pèrò pò tí wón bá mi fìjà peétà 80
 81. Wón ségun, àwé, wón lémi lugbó
 82. Ìgbà mo dóhùn-ún
 83. Ìpò olá tí mo wà sì ń wù mí jojo
 84. Níbi táwon tó ségun mi ti ń sètò ìpíngún
 85. Ibé ni mo ti bé lù wón gìjà 85
 86. Pèlú àwon èrò wóńwé tí mo rí kó jo
 87. Ero won tí kò jo
 88. Die bín-ńtín báyìí ló kù n ségun won
 89. Sùgbón wón ní olópò èrò logun ń séé fún
 90. Eyi ni wón fi rí mi fi se ní nnkan 90
 91. Tí wón ráyè ségun
 92. Ìgbà yìí ni wón wá rù mí regbóńgbó
 93. Níbi ojú olómo ò to
 94. Ibè ni mo sá wà
 95. Tí mo ri i pé ìgbésí ayé mi féé
 96. Tí mo da gègé dé ìwé
 97. Pé kí n ko ìtàn ayé mi fáráyé kà.