Ìlú Igbó-Ọrà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Olúgbóyèga Àlàbá

Onírúurú Àròfọ̀

Gboyega

Alaba

Ilu Igboora

Igboora

Ìlú Igbó-Ọrà Ojú-ìwé 13.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìdèrè jẹ́ ìlú pàtàkì,

Tó ṣe kókó gan-an ní Bàràpá;

Tó jẹ́ ẹ̀yà Oòduà kan.

Ẹ̀gàn àtàwàdà ni wọ́n ń sọ̀rọ̀ “ọ̀bọ Ìdèrè”.

Kò mà mà sọ́bọ ní Dèrè ní pàtó,

Ilu Idere

Idere

Ìlú Ìdèrè Ojú-ìwé 14-16.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ayétẹ̀ jẹ́ ìlú pàtàkì,

Tó dúró gedegbe ni Bàràpá;

Tó jẹ́ ìlú olóríire.

Ayé, ìyá Onídèrè àkọ́kọ́,

Ṣóun ló tẹ̀ lú yìí dó;

Ilu Ayete

Ayete

Ìlú Ayétẹ̀ Ojú-ìwé 17.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kò sẹ́ni tí ò níí kú,

Kò sẹ́ni tí ò níí rọ̀run.

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ má fi kú yọ̀ wá;

Gbogbo wa la sá jọ ń lọ.

Ẹní bá wáá fẹ́ kó yá,

Ilu Tapa ni Ibarapa

Tapa

Ibarapa

Ìlú Tápà ní Ìbàràpá Ojú-ìwé 18.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́n ná, jànmán-àn mi,

Ìrọra àtòkèwá lèmí fẹ́;

N ò fówó lásán;

Ìrọra lèmí fẹ́, n ò foníjàngbàn àlejò.

Nítorí bí “Agbọ́nmi ti í wó lé ẹja”,

Ojaa warawara

Oja

Warawara


Ọjàa Wàràwàrà Ojú-ìwé 19-20.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kò sẹ́ni tí ò níí kù,

Kò sẹ́ni tí ò níí rọ̀run.

Ẹ jọ̀wọ́ ẹ má fi kú yọ̀ wá;

Gbogbo wa la sá jọ ń lọ.

Ẹní bá wáá fẹ́ kó yá,

Irora atokewa

Iro ara

Ara


Ìrọra Àtòkèwá Ojú-ìwé 21.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ tẹ́tí ẹ gbọ́ ná, jànmán-àn mi,

Ìrọra àtòkèwá lèmí fẹ́;

N ò fówó lásán;

Ìrọra lèmí fẹ́, n ò foníjàngbàn àlejò.

Nítorí bí “Agbọ́nmi ti í wó lé ẹja”,

Tí “Apàjùbà í bal é àpáròó jẹ́”;

Tí “Olùgbóńgbó tìǹlà í ṣẹ́gun ògúlúǹtu”;

Bi ala

Ala

Bí Àlá Ojú-ìwé 22.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bí àlá ni gbogbo ayé rí,

Bí òjìjìji ni gbogbo afẹ́ ayée wa.

Ṣùgbọ́n kì í ṣòfifo.

Bẹ́ẹ ni kì í ṣòfìfo.

Wíwá-ọlà-nínúu-làálàá,

Ogede aye

Aye


Ọ̀gẹ̀dẹ̀ Ayé Ojú-ìwé 23.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bọ́gẹ̀dẹ̀ ayé ti ń bàjẹ́ bẹ́ẹ̀ ló ń pọ́n,

Báṣọ ayé ṣe ń gbó bẹ́ẹ̀ ló ń tàn.

Bá a bá rántíi kú,

La máa ń sinmi aré-sísá,

Àsìkò tá a bá rọ̀nà ọ̀run wò,

Gba tire

Tire

Ire

Gba Tìrẹ Ojú-ìwé 24.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kó sẹ́ni tí ó fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́,

Tó o bá gba ohun tÓlú pè ní tìrẹ.

Taa ha lẹni tí ó fi ọ́ ṣẹ̀fẹ̀?

Bó o bá gba hun tÓrí pè lẹ́rùu rẹ?

Kò sẹ́ni tó jẹ́ fi ọ́ pòṣé,

Tó o bá gba hun tó dé bá ọ.

Ogun nla

Ogun ńlá Ojú-ìwé 25.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ogun ńlá kan ń ṣẹlẹ̀ látàrí,

Tó jé isó gidi.

Àní isó inú ẹ̀kú,

Tó jẹ́ àramọ́ra gidi.

Èyí-ó-wù-mí-ò-wù-ọ́,

Èyí-ó-wù-ọ́-ò-wú-mí,

O ti loju ogun

Ogun


Ọtí lójú ogun Ojú-ìwé 26.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ifá kan wáa jẹ dé,

Odù kan wáá gàtẹ:

Ẹ bi mí:

Ẹ ní “Fáa kí ni?”

Ifá “Ọtí nílé ayé”

Tibitire

Ibi

Ire

Tibi Tire Ojú-ìwé 27-28.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àìlera ni bàbá ìlera,

Àìsàn sì lokùnfà ìwòsàn.

Ẹní paraa rẹ̀ ní líle ṣánṣán,

Ó lè jọ́gàá aláìlera.

Ẹní lóun ò nílòò ìwòsàn

Ó le máa fakùn àìsàn mọ́dò

Ipade ore merin

Ore

Ìpàdé Ọ̀rẹ́ Mẹ́rin Ojú-ìwé 29.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lágbájá ń wá owó kágbó,

Tẹ̀mẹ̀dù sì ń wá ọlà kájù


Gbogbo wọn ń sá kíjokíjo.

Lágbájá pàdé Owó-tàbíyì,

Tẹ̀mẹ̀dù pàdé Ọlà-tàbí-ẹ̀yẹ;

Owo airi


Ọwọ́ Àìrí Ojú-ìwé 30.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kò sẹ́ni tó mọ lé ayé tán,

Kò sẹ́ni ó mọ bi à ń rè gan-an.

Ṣùgbọ́n ṣáá, ọwọ́ kan ń bẹ tó ń ṣiṣẹ́,

Iṣẹ́ tó ń ṣe ò lóùnkà;

Ọwọ́ àìrí mà lọwọ́ yẹn o.

Nínú-un ká ṣiṣẹ́ láyé,

Ori to sunwon

Orí tó sunwọ̀n Ojú-ìwé 30-31.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orí tí ò sunwọ̀n a bà lú jẹ́,

Orík tó bá sunwọ̀n a tún un ṣe.

Orí tí ò sunwọ̀n ní í tú lùú,

Orí tó pé a bá ní kó o jọ.

ẹní rórí tó sunwọ̀n tí kò yìn ín,

Ẹ jẹ́ ó re lé Olórí-wíwú-tutu.

Odikeji arokan

Òdìkejì Àròkàn Ojú-ìwé 32.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

“Àròkàn, Àròkàn, Àròkàn,

“Àwọn ló ń bÁsúu-ùndákẹ́ sáyé.

“Àwọn ni baba ńláa rẹ,

“Àwọn ni babaláwo tó mọ̀ ọ́n kì.

“Ìyá ńláa rẹ̀ ló ń jÁròójù,

“Òun gan-an lAmúlẹ́nubíabẹ”

O kari aye

Aye

Ó kárí Ayé Ojú-ìwé 33-34.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹni ó lówó tí ò ní Àmúmọ́ra

Ẹni tí ò lówó tó mà ní Àmúṣayé,

Olúkálukú a mọ hunt i ń bá un fínra.

Kò wọ́n òpìjẹ̀;

Kò wọ́n Ayáwo,

Kò sì wọ́n Awínni.

Iduro o si

Ìdúró ò sí Ojú-ìwé 35.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

“Ìdúró ò sí, ìbẹ̀rẹ̀ ò sí,

Ọmọ ayé kúkú ti gbódó mì.”

Un ni Lákáṣegbé wí tó fi ṣojú yáwú,


Ó ṣojú yáwú, ó bá gbéra sọ.

Ó lóun ò níí rojú mọ́ láéláé,

Ó lérè ojú-ríro-kókó ò sí ní bì kankan.

Adura fun irin gbere

Irin gbere

Irin

Àdúrà fún Ìrìn Gbẹ̀rẹ̀ Ojú-ìwé 35-36.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

“Arìnrìngbẹ̀rẹ̀ ni yóò móyè délé,

Asíretete ò kúkú ní í róyè kankan jẹ.”

Ìrókò ga gíga ńlá,

Ó ga jAgbọ́teku-rò-fẹ́yẹ.

Àyànmọ́ wọn ò tó wà.

Ṣe un wọ́n bá ṣe ni jíjẹ.

Ayanmo o to iwa

Ayanmo

Iwa

Àyànmọ́ ò tó ìwà Ojú-ìwé 37.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bó o lórí lọ́wọ́,

Bó ò níwà pẹ̀lú ẹ̀;

Apẹ lórí tó o ń gbé kiri.

Ìwà níí mú ni í là,


Ìwà níí sọ ni í datọrọjẹ.

Oro idaraya

Idaraya

Ọ̀rọ̀ Ìdárayá Ojú-ìwé 38-39.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àpárá dùn lẹ́gbẹ́,

Àwàdà wuyì lọ́gbà.


Eré sunwọ̀n láwùjọ ẹgbẹ́ ẹni.

Wọ́n ní “Bá a bá rọ́lọ́rọ̀ ẹni tán,

Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ là á dà kalẹ”.

Igbagbe Oloosa

Oloosa

Ìgbàgbé Olóòṣà Ojú-ìwé 40-41.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ní “Bí kúu lé ò pa ni,

“Tòde ò rí ni gbé mì.”

Un ló mú mi rántí Olóòṣà kan Òòṣà kàn,

Tó ń ṣè gbàgbé pọ̀ mọ́ gbàgbọ́.

Tó ń fouńjẹ ajá féhoro jẹ.

Ìyàwó Olóòṣà sì rèé;

Oju ti ra

Ojú ti rà Ojú-ìwé 42.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kàkà kó ní “Ojú ti là”,

“Ojú ti rà” ló wá sẹ́ẹ̀kẹ́ẹ̀ Gbìrà.

Àṣìṣee rẹ̀ sì wáá wúlò gidi!

Nígbà ojú ṣì wà lórúnkún,

Nígbà ojú ṣì wà lórúnkún,

Nígbà ojú ṣẹ̀ṣẹ̀ gbó tí kò tíì rà,

Aajo ara

Aajo

Aájò Ara Ojú-ìwé 43-44.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Aájò ara bẹ̀rẹ̀ lórí ìmọ́tótó,

Ìmọ́totó tó borí àrùn mọ́lẹ̀;

Bọ́yẹ́ ti í borí ooru.

Aájò ara dórí oúnjẹ àtàtà,

Oúnjẹ àtàtà ti í ṣare lóore.

Oúnjẹ tíí mú orí pé,

Aye yi

Ayé yí Ojú-ìwé 45.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Òbìrí, ayé yi dà sí tàtijọ́,

Òbìrì, ayé yí dà sí tìgbà kan. Ọmọ ò sin baba bíi tìjọ́sí mọ́,

Baba ló wá ń sin ọmọ bíí rẹ́rẹ.

Ọmọbìnrin ò sìn yá rẹ̀ mọ́.

Ìyá ọmọ ló wá ń sin ọmọ dé bi tó ga.

Owó ti kúrò ní Àpèṣẹnukótó,

Ojulari

Ojúlarí Ojú-ìwé 46-47.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bábá kan bàbà kàn,

Ó wà lẹ̀gàn níjọ́sí,

Ó lórí lọ́wọ́, ó láya tó dáa.

Aya ọ̀hún sunwọ̀n, ó yẹ̀nìyàn.

Ṣùgbọ̀n ó pẹ́ korí tóó dá a.

Ó tojú sú gbobgo àdúgbò.

Ilu Odaju

Ìlú Ọ̀dájú Ojú-ìwé 48.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹ̀kọ́, ìlú ọ̀dájú.

Èkó, ìlú ìmọtara.

Yorùbá bọ̀ wọ́n ní ‘Òjú níí rójú ṣàánú’

Èkó ní ‘Alátiṣe níí màtiṣe’

Yorùbá ní ‘ Ká fọ̀tún wẹ̀sì,

Ká fòsì wẹ̀tún;

Eda naa n da nnkan

Ẹ̀dá náà ń dá nǹkan Ojú-ìwé 49.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Kí lènìyàn wà láyé fún?

TẸ́lẹ́dàá, fi ṣẹ̀dá ènìyàn?

TẸ́lẹ́dàá, ṣẹ̀dá ènìyàn?

Tó sì fún wọn lágbára?

Ó ní ki wọn ó má dá hun ti wọ́n fẹ́,

Yàtọ̀ sénìyàn tó já raa wọn,

Alaininnkan-anse

Aláìníkan-án-ṣe Ojú-ìwé 50-51.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ifá ní Ṣòtítọ́ọ́ọ́,

Má mà ṣè kà ènìyàn o o.

Ṣòtítọ́ o o ò,

Má mà ṣè kà ènìyàn o o.

Ẹní bá ṣòtítọ́ọ́ọ́

Ni ó tẹlẹ̀ yí pẹ́ o o.’

Oga nla

Ọ̀gá ńlá Ojú-ìwé 52-53.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ẹyẹ kan,

Ẹ̀yẹ̀ kàn,

A máa jẹ́ Ọ̀gá-ńlá.

Inúu pápá ló ń gbé kiri.

Ìdí tó fi ń jẹ́ Ọ̀gá-ńlá-wòr`o ní kíkún,

Kò sẹ́ni tó le fìdí ẹ̀ hanni?

Ebe

Ẹ̀bẹ̀ Ojú-ìwé 54.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Òkun layé o, ọ̀rẹ́ẹ̀ mi.

Òkun layé o; ènìyàn ibẹ̀, un lọ̀sà.

Odò tún layé pẹ̀lú;

Bí olórúkọọ́ jórúkọ.

Orí, wáá dá wa pé, jọ̀wọ́:

Káyé má mu wá lómi.

Afefe laye

Afẹ́fẹ́ Layé Ojú-ìwé 55.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bí ò sí afẹ́fẹ́

Ẹnì kan ò pẹ́ láyé.

Bí ò sì sí òòrùn

Ilè kàn ò gbẹ bòrọ̀bọ̀rọ̀.

Afẹ́fẹ́ tó fẹ́.

Tá a rí fùrọ̀ adìyẹ;

Ebo adarudurudu

Adarudurudu

Rudurudu

Ẹbọ Adárúdurùdu Ojú-ìwé 56.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọ̀rọ̀ dọ̀rọ̀ àwa araa wa –

Gbogbo àgbààgbà tó wà nílẹ̀ yí

Ẹ dákun, ẹ bá mi gbérò yìí yẹ̀ wò.

Èrò ọ̀hùn ò déédéé tu yọ látàríi kékeré Ọ̀jẹ̀-

Kékeré Ọ̀jẹ̀ tí ń kẹ́ṣà-pípè.

Àgbà Ọ̀jẹ̀ ló ti kéwì ṣáájú,

Oju o tori

Ojú ò tórí Ojú-ìwé 57.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ojú ẹ̀dá ò tórí –

Ó ṣe,

Ó pọ̀;

Ó mà ṣe o!

Ṣé bẹ́dàá bá dẹjú rẹ̀

Yóò rímú.

Akanti

Àkàntì Ojú-ìwé 58.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àkàntì tí ẹ rí yìí

Ogun tó nípọn ni.

Mo fẹ́rẹ́ pa á

Ǹjó ṣeé sè mọ́bẹ̀?

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ gbó

Njó ṣeé ká jẹ?

Ka sora

Ká Ṣọ́ra Ojú-ìwé 59.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Igba ẹká níí fọwọ́ọ́ tilé;

Igba aláàmù níí fọwọọ́ tògiri;

Un nilé fi í fúró sán-ún.

Ùn lògiri fi í ní bàlẹ̀-ọkàn.

Omi ní ń bẹ lẹ́yìn ẹja

Un lẹja fi joyè abìwẹ̀gbàdà.

Owere eniyan meji pere

Òwèrè Ènìyàn méjì péré Ojú-ìwé 60-61.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Alàgbà kan ń bẹ nífẹ̀ Oòyè

Amọ́bíọjọ́ ní í jẹ́;

Ó mọ́ níkùn tán, ó tún mọ́ lóde ara.

Òun ló kọ́ wa lọ́rọ̀ kan, àjímáarán;

Ó kọ́ wa lọ́rọ̀ kan, àjígbéyẹ̀wò -.

Ó lénìyàn méjì péré

Igbaradi ebo ayipada

Ìgbaradì: Ẹbọ Àyípadà Ojú-ìwé 62.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Omí parade

Omí dọtí.

Àgbàdó paradà

Ó dògì.

Èbù ìjọ̀sí paradà

Adura fun won

Àdúrà fún wọn Ojú-ìwé 1[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ní “Ta ló wà nínú ọgbà náà?

Bí mo ti tajú kán-án,

Ni mo bá rọ́mọ kékeré kan.

Ó ní “Ẹ̀yin babaláwo ayé, ẹ mà kúù dúró,

“Ẹ̀ kúù dúró tÌbádùnmọ́pẹ́,

“Ẹ kú àìgbò lẹ́yìn ọmọ je-n-jele.

“Bó bá jẹ́ mo dáyé wá ṣé ǹ bá ti tán,

“Bó sì jẹ́ mo nìkan rìn, mà ti rìn jùnù.

Mo kíi yín fún iṣẹ́ẹ yín,


Ìwúlò Ewì Ojú-ìwé 2.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Béwì kéré tá `o rí rú ẹ̀ rí,

Ká má fojúdewì ló tọ̀nà,

Ká kúkú rò ó wò ló tọ́,

Ká tú ọgbọ́n tó fi pamọ́ yọ.

Torí béwì kéré bá ò rí rú ẹ̀ rí,

Aboyún ọ̀rọ̀ ní ń bẹ ní kùn-un rẹ̀.

Ewì le wèrò òmùgọ̀ tí à ń rò lọ́wọ́,

Kó bá ni sọ ọ́ dọgbọ́n tó jinná gidi.


Èrò Ọkàn Ojú-ìwé 3[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Mélòómélòó òjò ló ti rọ̀ látàrí;

Tó rọ̀ níbẹ̀, tílẹ̀ sì ti fi mu?

Mélòómélòó lèrò tó ti sọ sí ni lọ́kàn;

Tó sọ sí ni lọ́kàn ṣùgbọ́n tí ò dúró rárá?

Mélòómélòó lèrò tó ti sọ lódòo kùn,

Tó sọ níbẹ̀, tó sì tún mòòkùn lọ bí ẹja?

Ìwọ̀n ẹja tá a bá fiwò gbé ńkọ́,

Ṣéun náà la lè jẹ.

Ìwọ̀n ẹja tá a bá fàwọ̀n kó,

Ṣóun náà la lè tà.

Má ṣe bẹ́ẹ̀ Ojú-ìwé 4-5.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Wọ́n ní “Ṣe bó o ti mọ,

“Ṣenu ní wọ̀n-ọn tòkèlè;

“Ṣòkèlè ní wọ̀n-ọn tọ̀fun

“Dá ṣọ pé-ń-pé o mú bo ra rúgúdú,

“Rẹ̀wù òun ṣòkòtò ní wọ̀n o lè wọ̀.

“Kọ́lé apá-ọ̀bún-ká,

“Má ṣe yà ní sọ ajunilọ.

“Bágbọ̀n bá ga lágajù,

“Sá fẹ́kọ inú ẹ̀ wéréwéré.

“Nítorí pẹ́ni ó ju ni lọ tefétefé

Láaróyè Ojú-ìwé 6.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọlọ́run tó layé lọ̀run.

Ló fÈṣù sílé ayé;

Pé kó máa báráyé fínra.

Ẹ̀sù kò ní bìkan àgbámú,

Ibikíbi ló le fi gúnni.

Eji lÈṣù, kò bẹ́nìkan ṣọ̀rẹ́,

Ẹni Akọ́gọ fẹ́ ní í pa nígi.

Láaróyè kò bẹ́nìkan ṣọ̀tá,

Ọrọ̀ gidi Ojú-ìwé 7.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bó o lówó bó ò lọ́rọ̀ láyé,

Ṣe bówó báńsá lo kó jọ.

Ìgbà tó o kówó ka lẹ̀ẹ́-lẹ̀,

Bónílé wọlé dé ńkọ́?

Ti taa ni kóhun tó o ní ó jẹ́ gidi?

Bó o tún fowó ṣe hun iyì sílẹ̀,

Bónílé bà dé ńkọ́?

Ṣùgbọ́n bó o rí ná tó o sì rí lò láyé,

Tálàáfíà sùn ẹ́ bọ̀,

Ìlú Ìgàngàn Ojú-ìwé 8-10.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọmọ kékee ilé, ẹ sáré wá.

Àgbà tí ń bọ̀ lọ́nà, ẹ tẹsẹ̀ mọ́rìn

Ẹ yé, ẹ wá ná, ẹ wáà gbọ́rọ̀ ẹnu àwa.

Àwaa kékeré ìwòyí tó mú létè bí ìṣó;

Àwaa kékeré ìwòyì tó buyọ̀ setè.

Kí lohun tá a fẹ́ẹ́ wí fáyé?

À ní kí lohun tá a fẹ́ẹ́ sọ sóde?

Ìtàn ló sọ fún wa nílẹ̀ yi.


Ìlú Làǹlátẹ̀ Ojú-ìwé 11.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bá a bá fa gbùrù,

Gbùrù á mà fa nǹkan.

Bá a bá gbọ́ Làǹlátẹ̀ sétí,

Ó le dún létí bí “Ìlú Ọ̀tẹ̀”.

Làǹlá ò mà mà lọ́tẹ̀ ńnú rárá,

Làǹlá ló tẹ bi wọ́n ń gbé ni.

Làǹlá ò fẹ́gàn rárá,

Ṣe ni wọ́n ń bá raa wọn wá re.

Ìlú Èrúwà Ojú-ìwé 12.[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bá a bá kọ́ gbọ́ “Èrúwà”,

Ó jọ “Bí-èrú-wà” létí

Ṣùgbọ́n ní gàsíkíyá, èrú-ṣíṣe kọ́ nì pìlẹ̀ ìlú,

Èrú-ṣíṣe kò ráyè níbẹ̀;

À ní, èrú-ṣíṣe ò sí lọ́rọ̀ọ tiwọn.

Èrú iṣu ló pọ̀ níbẹ̀ rí,

Tí wọn ń tà férò ọ̀nà.

Wọ́n wá ń polówó iṣu tó tú dáadáa.

Iwe ti a yewo[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Olúgbóyèga Àlàbá (1993) Onírúurú Àròfọ̀ Onibonoje Press & Book Industries (NIG.) LTD. ISBN 978-145-497-0.