Ìrànwọ́:Báwo lẹṣe le ṣe àtúnṣe ojúewé
Ìwé Ìmọ́-Ọ̀fẹ jẹ́ iwé, tí ó túmọ̀ sí ìwé tí ẹnikẹ́ni lè ṣàtúnṣe sí èyíkéyí ojú-ewé tí wọn kò dáàbòbò, tí yóò sì fi àtúnṣe rẹ̀ pamọ́ láti lè fi àtúnṣe rẹ̀ hàn sí gbogbo ènìyàn. Kódà, o kò ní láti dá àkọpamọ́ oníṣẹ́ kí o tó ṣàtúnṣe tó jọjú sí èyíkéyí àyọkà tí ó bá nílò àtúnṣe. Àmọ́ ṣá, bí o bá forúkọ sílẹ̀ tàbí dá àkọpamọ́ orúkọ oníṣẹ́ (Username) rẹ, yóò fún ọ láànfàní láti lè mọ iye àkòrí àyọkà tí o bá dá sílẹ̀ tàbí ṣàtúnṣe sí. Wikipedia editor!
Ṣíṣàtúnṣe àyọkà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ṣíṣàtúnṣe púpọ̀ ojú-ewé kò nira rárá, kàn tẹ "Àtúnṣe" tàbí "Àtúnṣe àmì-ọ̀rọ̀" ní orí ìlà ṣíṣàtúnṣe ní òkè ojú-ewé Wikipẹ́día lábẹ́ àwòrán agogo àti orúkọ oníṣẹ́.section-edit link). Bí ó bá ti tẹ̀ẹ́, yóò gbé ọ wá sí ojú ewé tí wà á ti lánfàní láti ṣàtúnṣe tó bá wù ọ́ sí àyọkà tí o fẹ́ túnṣe gan an.
Bí o bá ní ohunkóhun tí o fẹ́ fi kún ojú-ewé,
jọ̀wọ́ fi ìtọ́ka si, gẹ́gẹ́ bí àwọn àyọka tí kò ní ìtọ́ka sí yóò di píparẹ́. Bí o bá ti parí pẹ̀lú àtúnṣe, ṣàlàyé níí ṣókí sínú àkámọ́ kékeré ìsàlẹ̀ tí ó wà lókè "Ṣàtẹ̀jáde". O sì lè lo ìlànà ìkékúrú bíi legend. Bí o bá sì fẹ́ wo bí àtúnṣe rẹ ṣe rí, tẹ bọ́tìnì "Àyẹ̀wò". Tí ohun tí o bá ṣe bá ti tẹ́ ọ lọ́rùn tẹ "Ṣàtẹ́jáde" aláwọ̀ búlúù tí ó wà lápá òsì lẹ́gbẹ̀ẹ́ (Ṣàtẹ̀jáde). Àtúnṣe rẹ̀ yóò hàn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí o bá ti ṣe èyí fún gbogbo ayé rí. Wo èyí fún àpẹẹrẹ