Ìtàn àkọọ́lẹ̀ Yorùbá
Ìtàn bi ede Yorùbá ṣe di kíko sí lè (Yorùbá Orthography) Láti ayébáyé, èdè Yorùbá wa lábé ìpínsí sòrí tí ọ̀gbẹ́nì thamstrong (1964) se fún àwọn èdè gbogbo èdè Yorùbá bọ́ sí abẹ́ ìpín èdè “KWA”. Èyí sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ nítorí pé èdè olóhùn (tonalanguage) ni Yorùbá jẹ́. Gẹ́gẹ́ bí a se mọ̀ pé tẹ́lẹ̀-tẹ́lẹ̀ rí, a kì í kọ èdè Yorùbá sí lẹ̀, sí sọ nìkan ni a ń sọ ọ́ lẹ́nu. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn òyìnbó aláwọ̀ funfun dé tí òwò ẹrú si bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹ wọ́n bèrè sí ní í kó àwọn ọmọ bíbí ilẹ́ Yorùbá lẹ́rú lọ sí òkè-òkun. Èyí tẹ̀síwájú fún ìgbà pípẹ́ kán-fin-kése títí di àsìkò tí ìjọba àpapọ̀ àgbáyé gbìmọ̀ pọ̀ ti òpin sí òwò ẹrú yìí. Fún ìdí eléyìí, ó di òranyàn kí á dá àwọn ẹrú wònyí padà sí ibi tí wọ́n ti sẹ̀ wá. Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹní tí wọ́n jẹ́ ọmọ bíbí ilẹ̀ Yorùbá padà sí ilẹ̀ wọn. ṣùgbọ́n ní ọwọ́ àsìkò ti wọ́n fi wà ní oko ẹrú yíì ni wọ́n ti ń se ẹ̀sìn jíjẹ́-ọmọ-lẹ́yìn-kírísítì (chiristanity) Àwọn òyìnbó amúnsìn yìí sí rí i ní ọ̀ranyàn pẹ̀lú láti se agbára lórí i bí ẹ̀sìn yí yóò se máa tẹ̀síwájú láàrin wọn. Ẹ̀yí gan-an ló mú kí wọn se akitiyan lórí bí wọn yóò se se àyípaà ìwé-mímọ́ nì –Bíbélì sí èdè Yorùbá. Nínú sí se eléyìí ó se pàtàkì láti rí i dájú pé ọmọ bíbí ilẹ̀ Yorùbá tó sì jẹ́ gbédè-gbijọ̀ èdè náà wà ní bẹ̀ àti kí ó sì kó ipa takuntakun nínú sí se àyẹ̀wò, àfikún, àyokúrò àti afótónu tó yaarantí ló rí iṣẹ́ náà. Àwọn ènìyàn bíi Humnah Kilham (1891) John Rahar, Gollmer and Bowdich (1817) àti Àjàyí Growther (1815) ló bẹ̀rẹ̀ isẹ́ lórí kí kó lẹ́tà àti àwọn òǹkà jọ. Okùnrin kan tí ń jẹ́ Bowdich ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kọ́kọ́ si ṣẹ́ lórí i àwọn òǹkà Yorùbá bí i, óókan, ééjì, ẹ́ẹ́ta títío do ri i ẹ́ẹ́wà-á ó sì se àwọn isẹ́ yìí í ní odún (1817). Hamah Kilhar ní (1828) náà sísẹ́ lórí kíkọ sí lẹ̀ èdè tí à ń mẹ́nu bà yìí. Ó fún wa ní ìlànà méjì tí ó se pàtàkì jù nínú isẹ́ rẹ̀.
Lẹ́yìn Crowther, a ò gbọdọ̀ gbàgbé àwọn yeekan-yeekan bi, Henny Venn (ijo CMS), Àlùfáà Charle Andrew Gollmer (German), Alufa Heny. Townsend, Samuel Johnson abbl. Tí wọ́n se akanse iṣẹ takun-takun lórí bí èdè Yorùbá se di kí ko sèle. Akiyesi pàtàkì kan ti a lee se nínú gbogbo atotonu lórí bi èdè Yorùbá se di kiko silẹ yin i pe nínú gbogbo àwọn to siṣe yi ti wọn jẹ àwọn oyinbo atohun rinwa alawọ dúdú kan ni a timenu ba, ṣùgbọ́n èyí ko fi bẹ́ẹ ri bẹ. Àwọn dúdú ti wọn ko pa nínú iṣe yìí naa po jojo ṣùgbọ́n fún ìdí kan tàbí òmíràn ti a ko ni lee sòro nípa wọn. Ìwọ̀nba kéréje tí a leè mẹ́nu bà nínú ìtàn bí èdè Yorùbá ṣe di kíko sílẹ̀ nì yí.