Jump to content

Ìwé Ìròyìn

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Photograph of a bespectacled man sitting on a stool with his legs crossed reading a newspaper in the morning
Man reading a newspaper

Ìwé Ìròyìn gẹ́gẹ́ bí orúkọ rè ni Ìwé àtẹ̀jáde olójoojúmọ́ tí wọ́n fi ma ń kọ tàbí sọ nípa ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́ lọ́wọ́ tàbí ohun tí ó ń lọ nínú àwùjọ kan.[1] Ìwé Ìròyìn ma ń sábà sọ̀rọ̀ nípa oríṣiríṣi bí ọ̀rọ̀ Ìṣèlú, Okòwò, eré Ìdárayá, iṣẹ́ Ọnà, ìmọ̀ Sạ́yẹ́nsì, ọ̀rọ̀ nípa ojú ọjọ́, ìkéde ayẹyẹ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ó sì ma n ní àlàfo tí àwọn ènìyàn lè fi sọ nípa bí ọ̀rọ̀ kan ṣe rí ní pàtó. Púpọ̀ nínú àwọn ìwé ìròyìn ni wọ́n sábà ma ń jẹ́ iṣé ìṣe tàbí okòwò fún àwọn tí wọ́n bá dá irụ́fẹ́ ìwé ìròyìn bẹ́ẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sábà ma ń fi Ìwé ìròyìn pawó nígbà tí àwọn ènìyàn bá polówó okòwò, ọjà, tàbí ayẹyẹ èyíkéyí tí wọ́n bá fẹ̣́ ṣe lórí ìwé ìròyìn kan. Ẹ̀wẹ̀, ìwé ìròyìn kìí ṣe ọ̀fẹ́, bí kò ṣe títà fún enikẹ́ni tí ó bá fẹ́ jànfàní ìròyìn nínú ìwé náà. Àwọn tí wọ̣́n gbé ìwé ìròyìn olójoojúmọ́ jáde ni a pè ní Oníṣẹ́ Ìròyìn tàbí oníròyìn ní ṣókí. Nígbà tí ìwé ìròyìn kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ń jáde láyé àtijọ́, orí ìwé fífẹ̀ fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ ni wọ́n ma ń kọ àwọn àkòrí ọlọ́kan-ò-jọ̀kan tí ó gbọ́mọ pọ̀n lóríṣríṣi tí ó ń tọ́ka sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ onírúurú tí ó ń lọ láwùjọ sí. Púpọ̀ àwọn ìwé ìròyìn ni wọ́n ma ń kọ pẹ̀lú òǹtẹ̀ aláwọ̀ dúdú àti funfun gbé jáde. Àmọ́ láyé òde òní, àwọn ìròyìn tàbí ìwé ìròyìn ni wọ́n ti ń gbé jáde lórí ẹ̀rọ ayélujára fún ìrọ̀rùn àti rí ìròyìn ka níbikíbi àti ní àyèkáàyè lágbàáyé nípa lílo ìkànì tí yóò tọ́ka sí ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn kan tàbí òmíràn, fúndí èyí, púpọ̀ nínú àwọn ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn ni wọ́n ti pa kí wọ́n ma kọ ìròyìn sí orí ìwé fífẹ̀ fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ tì látàrí ìrọ̀rùn tí ìtàkùn ayélujára ti mú wá bá wọn. Ìwé ìròyìn ni wọ́n ṣàgbékalẹ̀ rẹ̀ nị ǹkan bị́ ọ̀rùndún mẹ́tàdínlógụ́n sẹ́yin láti lè mạ́a fi ṣàgbéjáde ìròyìn nípa okòwò, àmọ́ nígbà tí yóò fi di ǹkan bí 19th century, àwọn orílẹ̀-èdè bí Europe, North àti South Amẹ́ríkà bẹ̀rẹ̀ sí ní fi gbé àwọn ìròyìn jáde lórí oríṣiríṣi ohun tí ó ń lọ ní àwùjọ wọn gbogbo.

Ìwòye lórí Ìwé Ìròyìn

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
Front page of The New York Times on Armistice Day, 11 November 1918.

Wọ́n ma ń gbé Ìwé Ìròyìn jáde ní ojoojúmọ́, tàbí ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Àwọn ìwé ìròyìn alákànṣe tí a mọ sí "Magazine" náà ma ń jẹ́ ọlọ̣́sọ̀ọ̀sẹ̀ bákan náà, àmọ́ ìrísí àkọsílẹ̀ wọn ma ń yàtọ̀ sí ti Ìwé Ìròyìn pọ́nbélé. Lápapọ̀, gbogbo ohun tí ó bá ń lọ ní àwùjọ ni ó ma ń jẹyọ nínú àwọn ìwé ìròyìn olójoojúmó àti ọlọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tí wọ́n sì má ń ṣe àgbékalẹ̀ ìròyìn náà gẹ́gẹ́ bí àyọkà sí ojú-ewé ìwé ìròyìn, àwọn ìròyìn bí ìròyìn tí ó ṣe pàtàkì, ìròyìn àgbáyé, tàbí ìròyìn nípa orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti n ́tẹ ìwé ìròyìn náà ni wọ́n ma ń gbé sí àwọn ojú ìwé ìròyìn. Lára àwọn ìròyìn tí ó ma ń fara hàn nínú ojú ìwé ìròyìn ni: ìròyìn nípa Ètò Ìṣèlú àti àwọn lààmì-laaka olóṣèlú, ìròyìn nípa Ìṣúná àti Okòwò ìròyìn nípa Ètò Ìlera, ètò Ẹ̀kọ́ , Sáyẹ́nsì, Ìmọ̀ Ẹ̀rọ, Ìwà jàndùkú, Ìròyìn Ojú-Ọjọ́, Ìròyìn Afẹ́, ìròyìn Àwùjọ, Ìròyìn nípa Àsè, Oge, Ilé gbígbé, Iṣẹ́ Ọnà àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n sábà ma n ́pín Ìwẹ́ Ìròyìn sí ìsọ̀rí ìsọ̀rí, tí wọ́n sì ma ń ṣe àkójọ àwọn ìròyìn tí ó bá jọ mọ́ ara wọn sí abẹ́ ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n yóò sì fún àwọn ìsọ̀rí yí ní àmì ìdánimọ̀ wọn bí: (A, B, C, ati A1-A20, B1-B20, C1-C20), àti bẹ́ẹ̀ bẹ̣́ẹ̀ lọ́. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìwé ìròyìn ni àwọn Olóòtú náà ma fi gègé dárà ọ̀rọ̀ sí nípa ìwòye wọn lórí àkòrí ọ̀rọ̀ kan tí ó bá ń jà rànìn rànìn ní àwùjọ wọn.

Oríṣiríṣi àwọn àpilẹ̀kọ ní ó tún ma ń jẹyọ nínụ́ àwọn ìwé ìròyìn tí a kò tíì mẹ́nu bà, lára àwọn ohun tí ó tún ma ń jẹyọ ni: Ìròyìn iṣẹ́ àkànṣe Lítíréṣọ̀, Ọ̀nà Ìkọ́lé, Eré Orí-Ìtàgé, Sinimá, àti àwọn ìkéde pàtàkì lórí Ilé oúnjẹ, Ilé Ìtura , Ayẹyẹ Ìsìnkú , Ayẹyẹ Ọjọ́ Ìbí àti bẹ́ẹ̀ bẹ́é̀ lọ. Bákan náà ni wọ́n tún ma ń fi ìwé ìròyìn ṣe eré ìdárayá ọpọlọ oríṣiríṣi. Púpọ̀ nínú àwọn oníwé ìròyìn ni wọ́n ma ń gba àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ bíi tiwọn síṣẹ́ tí wọ́n sì ma ń sanwó fún wọn, àwọn oníwé ìròyìn náà tún má ń pawó wọlé sílé iṣẹ́ wọn pẹ̀lú kí wọ́n ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn iléṣẹ́ ìwé ìròyìn kéréje kéréje nípa fífún wọn ní ànfàní láti lo ojú òpó wọn láti fi tẹ ìwé ìròyìn tàbí gbé ìròyìn tiwọn náà jáde. Ọ̀pọ̀ nínú wọn náà sì tún má ń gba àwọn oníròyìn bíi tiwọn láti kọ, to ìròyìn tàbí, jábọ̀ rẹ̀, tị́ wọn yóò sì ta ìròyìn náà fún àwọn ilé-iṣẹ́ ìwé ìròyìn míràn láti gbe jáde. [2] Nígbà tí yóò fi di ìparí ọdún 2000 sí ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2010, wọ́n ti ń lo ojú-òpó ayélujára látarí ìgbèrú àti ìdàgbàsókè ẹ̀rọ ayélukára pàá pàá jùlọ ní àsìkò tí okòwò dẹnukọlẹ̀ ní agbáyé, púpọ̀ àwọn oníléeṣẹ́ ìròyìn ni wọ́n ṣamúlò ẹ̀rọ ayélujára láti fi iṣẹ́ wọn dúró ṣinṣin.[3]

  1. "Definition of NEWSPAPER". Merriam-Webster. 2024-08-05. Retrieved 2024-08-24. 
  2. "A Daily Miracle: A student guide to journalism and the newspaper business (2007)" (PDF). Archived from the original (PDF) on 15 May 2011. Retrieved 21 May 2012. 
  3. Plambeck, Joseph (26 April 2010). "Newspaper Circulation Falls Nearly 9%". The New York Times. https://www.nytimes.com/2010/04/27/business/media/27audit.html?scp=3&sq=newspapers&st=Search.