Jump to content

Ìwúlò Ẹ̀ka Èdè Yorùbá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Àwọn ọ̀nà tí èdè àjùmọ̀lò (language/standard variety) gbà wúlò ní ẹ̀ka-èdè fúnra rẹ̀ náà gbà wúlò. Ní àkọkọ́, bí èdè fúnra rẹ̀ ṣe jẹ́ ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ ní ẹ̀ka-èdè náà jẹ́ ọ̀nà ìbánisọ̀rọ̀ kan tí ó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Ṣáájú, bí a ṣe ń fi èdè gbé èrò ọkàn wa jáde, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni a ń fi ẹ̀ka-èdè gbé èrò ọkàn wa jáde (medium of expression). Ohunkóhun tí a bá lè rò l’ọ́kàn ni a lè fi ẹ̀ka-èdè gbé jáde lọ́nà tí ó yéni yéké.

Ìpolówó ọjà jẹ́ ọ̀kan gbòógì lára ìwúlò èdè, bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀ka-èdè ṣe wúlò fún ìpolówó ọjà. Eléyìí wọ́pọ̀ púpọ̀ lórí èrọ rédíò àti móhùn-máwòrán (television). Gẹ́gẹ́ bí a ti mọ̀ wí pé ìpolówó ọjà ni àgúnmu òwò, ẹ̀ka-èdè agbègbè kọ̀ọ̀kan wúlò fún ìpolówó ọjà ní ẹkùn kọ̀ọ̀kan tí a ti ń sọ ọ́. (Advertisement).

A má a ń lo ẹ̀ka-èdè fún sísọ ọ̀rọ̀ àṣírí (secret conversation) tí a bá wà ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n ń sọ oríṣìíríṣìí ẹ̀ka-èdè tí ó pọ̀. Eléyìí wúlò ní àwùjọ tí a bá fura (suspect) pé ọ̀tẹ̀, rìkíṣí àti tẹ̀m̀bẹ̀lẹ̀kun wọ́pọ̀ sí. Tí a bá fẹ́ láti sọ ọ́ lọ́nà tí gbogbo ènìyàn yóò gbọ́, a lè sọ èdè àjùmọ̀lò.

Ẹ̀ka-èdè wúlò púpọ̀ fún ìpanilẹ́rìn-ín (comedy). Eléyìí wúlò púpọ̀ nínú eré orí ìtàgé Yorùbá àti àwọn èdè mìiràn. Àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá kan wà tí wọ́n pani lẹ́rìn-ín púpọ̀. Fún àpẹẹrẹ, Ìjẹ̀bú, Ìjẹ̀ṣà, Èkìtì àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Èyí tí ó fara pẹ́ eléyìí ni lílo ẹ̀ka-èdè fún eré orí ìtàgé. Eléyìí jẹyọ nínú iṣẹ́ Bàbá Sàlá ní ayé ìgbà kan. Láyé òde òní, tí a bá wo àwọn eré orí ìtàgé tí Ọ̀gbẹ́ni Ọdúnladé Adékọ́lá àti Arákùnrin tí a ń pè ní Ìjẹ̀bú ti kópa, a ó rí i wí pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n má a ń lo ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀bú. Fún àpẹẹrẹ, ‘Sàámú Alájo.’

Ẹ̀ka-èdè tún wúlò púpọ̀ fún ìròyìn ẹsẹ̀ kùkú. Fún àpẹẹrẹ, lórí ẹ̀rọ móhùn-máwòrán ti ìpínlẹ̀ Ògùn, wọ́n má a ń sọ ẹ̀dà ìròyìn ní ẹ̀ka-èdè Ègùn. Eléyìí má a ń ṣẹlẹ̀ náà ní àwọn ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun (Ìjẹ̀ṣà) àti Ìpínlẹ̀ Èkìtì níbi tí wọ́n ti má a ń sọ ẹ̀dà ìròyìn ní ẹ̀ka-èdè Ìjẹ̀ṣà àti ẹ̀ka-èdè Èkìtì.

Ẹ̀ka-èdè tún wúlò fún ìsọmọlórúkọ. Fún àpẹẹrẹ, tí a bá gbọ́ àwọn orúkọ bí i Elúfisan, Elújọba abbl, a ó mọ̀ wí pé àwọn tí ó ń jẹ́ orúkọ bẹ́ẹ̀ ti Ilé-Ifẹ̀ wá. Àwọn Ìjẹ̀bú a má a sọ ọmọ ní Ṣóyínká, Ṣówándé, Ṣówọlé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

Bákan náà, ẹ̀ka-èdè wúlò fún iṣẹ́ ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí èdè. Fún àpèjúwe iṣẹ́ lórí i Àńkòò fáwẹ́lì (vowel harmony), wọ́pọ̀ nínú àwọn ẹ̀ka-èdè Yorùbá ààrin gbùngbùn. A tún rí àwọn òǹkọ̀wé tí wọ̣́n má a ń kọ iṣẹ́ wọn ní ẹ̀ka-èdè. Fún àpẹẹrẹ, òǹkọ̀wé tí ó pe ara rẹ̀ ní Ṣóbò Aróbíodù. Bákan náà ni òǹkọ̀wé tí ó lo Kúnlé Ológundúdú.

Lákòótán, ẹ̀ka-èdè wúlò fún ìdánimọ̀ (identity). Ìdí ni èyí, tí ó fi jẹ́ pé tí a bá ti gbọ́ àwọn orúkọ kan, a lè sọ agbègbè tí ẹni tí ó ń jẹ́ orúkọ náà ti wá. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbà a má a wí pé: A má a ń fún ọmọ ní orúkọ torí ọjọ́ tí yóò bá dáràn.