Ìwúre Níbi Ilé Ṣíṣí
Ìrísí
ÌWÚRE NÍBI ILÉ ṢÍṢÍ
llé yìí yóò tú ọ́ lára,
Ire ni yóò máa bá ọ gbé inú ilé náà.
Kí ikú rí ilé yií sá,
Kí àrùn rí ilé yií sá
Kí òfò rí ilé yií sá,
Ki ẹ̀gbà gbe ìgbẹ́ wo àwọn tí ń gbé inú ilé yìí.
Ẹni lóyún sínú, á bí tibi tire,
Àgàn á tọwọ́ àlà bosùn;
Ire owó, ire ọmọ, ire àlàáfíà,
Ni yóó máa ba yín gbé ilé yìí.
Àgbàrá kì í fo kòtò,
Ire tí àwọn tí yóo máa gbé inú ilé yií ń fẹ́, kò ní fò wọ́n
Ẹ ò ní rùkú wọlé yìí,
Ẹ ò ní rùkú jáde;
Ẹ ò ní róhun gbé sọnù bí kò ṣe ibi ọmọ.
Ẹnìkan kì í dálé kọ́,
Ọlọ́run náà ní í kọ́ ọ fún ni;
Ọlọ́run tí ó kọ ilé náà fún ọ,
Kò ní ṣẹ̀rù bà ọ́ níbẹ̀.
Àṣẹ.