Jump to content

Íónì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Àwòrán Kationt

Íónì je atomu tabi horo kan ni inu ibi ti iye apapo awon elektronu ko dogba mo iye apapo awon protonu, bi be ti atomu na yio ni agberu itanna to seku to je didaju tabi lilodi. Ioni wa lati oro ede Griiki ἰόν (to tumosi "o rinso"), o si koko je lilo latowo asefisiksi Michael Faraday fun awon ohun ti won unlo labe iwo itanna larin awon elektrodu ninu iyosomi kan, nigbati ayika itanna kan ba je mimulo mo.

Ti atomu adogba kan ba pofo elektronu kan tabi jubelo, yio ni agberu siseku didaju, eyi ni a unpe ni kationi. Ti atomu kan ba jere elektronu, yio ni agberu siseku lilodi, a si unpe ni anioni. Ioni kan to ni atomu kan soso ni a unpe ni ioni atomu tabi oniatomukan; to ba ni atomu meji tabi jubelo, a unpe ni ioni onihoro tabi oniatomupupo.

Ninu apere isodiioni efuufu kan, awon ohun kan ti a unpe ni "ibeji ioni" je dida ti won ni elektronu adawa kan ati ioni didaju kan.

Àwọn íónì àti kátíónì

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]