Jump to content

Ẹ̀sìn Krístì

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Ibojì mímó fún àpèjúwe ti Dome lórí àwon Katholikon, Jerusalemu.

Ẹ̀sìn Kristi tàbí Ìsìn Kristi tàbí Ẹ̀sìn onígbàgbọ́ (tí àwon míràn máa ń pè ni Ẹ̀sìn Kiriyò) jẹ́ ẹ̀sìn Ọlọ́runkan tọ́ dá l'órí ìgbésíayé àti àwọn ẹ̀kọ́ Jesu ti Nasareti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe kọsílẹ̀ nínú Májẹ̀mú Tuntun ti Bíbélì.[1][2]

Ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ ló fẹ́rẹ̀ tan kálẹ̀ jù ní gbogbo àgbáyé. Ní bíi nkàn an ọdún bíi mewa séyìn ìye àwon Tí ó n sẹ ẹ̀sìn ìgbàgbọ ní àgbáye fẹ́rẹ̀ tó bílìònù méjì ènìyàn Bíì àwọn ẹ̀sìn míràn èsìn ìgbàgbọ́ ní àwọn òpó igbagbọ àti àsà tì ó dìrò mó. Fún àwọn tó bá jẹ onígbàgbó nìkan ló lè ní òye ìtumọ̀ àwọn òpó igbagbo tí ẹ̀sìn yí dìró mọ́ dáradára. Sùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀ a sì lè sàlàyé fún aláìgbàgbọ́ nínú ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ ohun tí èsìn ìgbàgbọ́ jẹ.[3]

A le rí ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí àpéjọpọ̀ àwọn onìgbàgbọ́. A tun le ríi gẹ́gẹ̣́ bí ìgbésíayé ayé tí onígbàgbọ̀ ń gbé. A le rí èsìn ìgbàgbọ́ gẹ́gẹ́ bí iş̣ẹ́ ìsìn, a tún lé ríí gẹ́gẹ́ bií àşà, gbogbo itumọ̀ yìí tàbì jù bẹ́ẹ̀ lọ ni a le fún ẹ̀sìn ìgbàgbọ́. A le şe àfiwé ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀sìn míràn làtàrí pe ọ̀pọ̀lọpọ̀ èsìn ló ní àwon àbùdá tí èsìn ìgbàgbọ́ ní. Fún ìdí èyí yó şànfàní nígbà tí a bá n sọ nípa èsìn ìgbàgbọ́ lati máa mẹ́nu ba àwon èsìn míran. Ṣùgbọ́n ó ṣe pàtàki náà láti şàgbéyèwò àwon àbùdà tí ó jẹ́ ti èsìn ìgbàgbọ́ [4]

Ohun Pàtàkì tí ó jẹ́ ààrin gbungbun èsìn ìgbàgbó tí ó dàbí òpó tí ohun gbogbo dìrò mọ́ ni Jésù . Ìgbàgbọ́ nínú ohun tí Jésù jẹ́ tàbí tí ó ṣe nígbà ayé rè lọ́ bí ìlànà tàbí èkó tí ìjo kọ̀ọ̀kan ń té lè ninu ẹ̀sín ìgbàgbó. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọpọ́lọpọ́ onígbàgbọ́ ló gbàgbọ́ pe ènìyàn ìyanu ni Jésù, àti pé ìṣẹ̀dá rẹ̀ yàtọ sí ti ẹ̀dá alàyè yókù wọn a (àwọn onígbàgbọ) si tún máa kóni láti tẹ̀le àwọn ìkọ̣́ni Jésù, síbẹ̀síbẹ̀, imọ awọn onígbàgbọ́ nipa ohun tí Jésù jẹ́ nítòótọ́ kò jọra wọn. Nítorí ìdí èyí yó ṣe Pàtàkì fún wa láti lo bíbélì ìwé mímọ́ àwon onígbgàgbọ́ làti ṣe atọ̀nà wa nínú àlàyé yìí.

Bíbélì jé ọ̀rọ̀ olọ́run tí a ti ọwọ̣́ awọn ènìyàn mímọ́ kọ. Ìwé mẹ́rindínláàdọ́rin ni wọ́n kó jọ sínú Bíbéli. Apa kan jẹ màjẹ̀mu láíláí tí a ti ọwọ́ àwọn wòlíì kọ Nígbàtí májẹ̀mu títun jẹ ẹ̀yí tí a ti ọwọ́ àwọn àpósítélì kọ nípa Jésù láti fi tan ìwàásù Jesu kálè. Àwon elékọ̀ọ́ bíbélì tí à ń pè ni (Theologians) gbà pe Májẹ̀mú láíláí wà ní ìṣọ̀kan pẹ̀lu májèmú títun. Májẹ̀mú láíláí sọ nípa iṣẹ́ ìgbàlà ti Jésù wá ṣe nílé aye. Nígbàtí májẹ̀mú títun n ṣe àmúşę ohun tí màjèmú làìlàì sọ.

Bíbélì fìdí rẹ múlè pé gbogbo ènìyàn ní ó sá ti ṣè tí ó sì ti kùnà ògo Ọlọrun (Romu 3:23). Èyí ni láti sọ pe ẹlẹ́sẹ̀ ni gbogbo ọmọ adárí hurun. Iwe Romu orí kẹrin ẹsẹ ikẹtadínlíágun títí de ikọkànlélógún (Romu 4:17-21) pẹlu fìdí re múlẹ̀ pe láti inú ẹ̀sẹ̀ àìgbọràn ti Ádámú ati Eéfà Ọkùnrin àtì Obìnrin akọkọ ṣẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá ọ̣mọ̣ ènìyàn ti di ẹlẹ́sẹ́, torí láti ara àwon méjéèjì ni gbogbo ọmọ ẹ̀dá ti ṣẹ wa. Àlàyé ìbę̣rę ìran ọmọ ènìyàn wa nínù Jénésísì (Genesis). Fún ìdí èyí ọmọ ènìyàn nílò ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ́ Olódùmarè, torí rè ni Jésù ṣe wá sílé aye láti wàásù ìgbàlà àtì láti kú fún ọmọ aráyé fún ìwènùwọ́ àti ìràpadà ẹ̀sẹ̀ wọn (John 3:16, Matthew 1:21)

Jésù Kírísítì, ni bíbélì tún sọ fún wa pe o jẹ ọmọ ọlọ́run (John 3:16). Jésù fúnrarẹ̀ pe ara rè lọ́mo ọlọ́run nínú ọ̀pòlòpò ẹsẹ̣ bíbélì pàápàá jùlọ nínú àdúrà olúwa tí ó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa gbà (Matheu 6:9-13, Luke 11:2-4). Jésú sẹ ọ̀pòḷòp̣ọ̀ iṣẹ́ ìyanu láti fi ìfé olódùmarè hàn sí àwọn ọmọ ènìyàn. Ó lajù afọ́jú, Ó jí okù dìde, Ó mú arọ ní ara dá. Onírúurú ìjọ onìgbàgbọ́ ló ní orísìírísìí ìtumọ̀ fún bibeli torí ìdí eyi onírúrú ìlànà èsìn ni ìjọ kọ̀ọ̀kan ní. Àtí pé ìgbàgbọ wọn nípa ohun tí Jésù jẹ́ yàtọ̀ díèdíẹ̀ síbèsíbè gbogbo wọn gbà pé olùgbàlà ni Jésù. A le ṣe kònkárí àwọn òpó ìgbàgbọ́ tó wà nínú èsìn ìgbàgbọ́ ní ọ̀nà márùn-ún

  • Ìgbàgbọ́ nínú ìwáyé àti ikú Jésù fún ẹ̀sẹ̣̣̣̀ gbogbo ọmọ ènìyan (John 3:16)
  • Títèlé àwọn àṣẹ ti Jésù pa àti ṣ̣iṣe àwòkóṣe ìgbésí àyé re (John 15:14)
  • Jíje ónje ale olúwa ní írántí ikú Jésù (Luke 22)
  • Jíjósìn pèlú àwon onígbàgbó (John 13:34-35)
  • Síse ìtèbomi (Mathew 28:19)

Bí mo se so sáájú àwon onígbàgbó ní èró to yàtò nipa òpòlopò nnkan nínú bíbélì fún bí àpeere awon kan gbà pe Jésù dógba pèlú olódùmarè eléyìí ni wọ́n ń pè ni èkó métalọ́kan ninu eyi tí o so pe, olódùmarè, Jésù àti Èmí mímó bara won dógba àti pe nnkankan náà ní àwon métèèta. Àwon onígbàgbó míràn ko faramó èyí torí kò séé fòye gbé bí ènìyàn tàbí èdá méta ṣe le parapọ̀ di okan. Àmó sa òpòlopò ìjo àwon onígbàgbó ló gbàgbó nínú àwon òpó márààrun tí a là sílè.

ÌTÀNKÁLÉ ÈSÌN ÌGBÀGBÓ

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ní ìlú Jerúsálémù ni èsìn ìgbàgbó ti bèrè kò tó di pe àwón omo ogun Róòmù ba ìlú náà jè ní ogórin odún léyìn ikú Jésù. Díè nínú àwon Júù lo kókó di onígbàgbó torí wón gbà pé Jésù Kírísìtì ní àmúse àsótélè àwon wòlíì nínú májèmú láíláí sugbon láti ipasè isẹ́ ìwàásù ti Póòlù àpóísitèlì se ní óríléèdè àwon kènfèrí(àwon aláìgbàgbó), òpòlopò kènfèrí bèrè sí ní dide [5]

Inúnibíni jé bíi omo ìyá awúsá fún èsìn ni kò sí ẹ̀sìn kan tí kò ní alátakò. Bí ẹnìkan kò bá gba ohun tí mo gbàgbọ́ ó ṣeéṣe fun irú ẹni béè láti takò mí. Bẹẹ gẹ́gẹ́ lọ́ ṣe ri fún èsìn ìgbàgbó, onírúurú àtakò sùgbọ́n èyí tọ́ burú jù ní inúnibíni láti ọdọ Ọba Nẹ́rò tí í se olórí ìjoba Róòmù nigbana Ọba yìí ko le gbà ki enìkan máa pe Jésù ní Olúwa Nígbà tí òun sì jẹ́ Ọba, ìdí nìyí tí ó sẹ gbógun ti ìgbàgbó.

Sugbọ́n léyìn ọba yìí, ọba kan jẹ tí ó n jẹ Constantine. Ọba yìí di onigbàgbọ́. Èyí mú kí ẹ̀sìn igbàgbọ́ gbayì nígbà náà ó sì wá rọrùn fún ẹnikẹ́ni láti di onígbàgbọ. Bákannáà eléyìí mú kí ìgbàgbọ́ di yẹpẹrẹ, ko di gbẹ̀fẹ́, yàtọ̀ sí èyí ìjo páàdì(catholic) to wa ni Róòmú nkó àwọn èèyàn ni papá mọra wọ́n fi jújú bo àwọn ènìyàn lójú wón gbe ọ̀rọ̀ àṣà aye wọ inú ìjọ. Eléyìí sì mú kí èdè àìyedè àti ìṣọ̣̀tẹ̣̀ bẹ́rẹ́ nínú ìjọ̀. Ìgbà tó yá ìyapa bẹ̀rẹ̀ sí ní dé àwọn èèyàn tí ó sì sokùnfà ìyapa naa ni àwọn èèyàn bíi Martin Luther, John Calvin, Ernst Troeltsch àti àwon ènìyàn míràn tí a kòlè dárúkọ. Wọ́n tako àwọn àṣà bíi kí á máa ṣe ìtẹ̀bọmì fún ọmọdé, ẹ̀kọ́ lórí metalọkan àṣepọ ìjọ ati ìjọba, sísọ àwọn olórí èsìn bíi ti olórun. Gbogbo àwọn àṣà yìí ni àwon ènìyàn wònyí tako. Ìyapa tí ó sẹlè kúrò nínú ìjọ paadi (Catholic) ló bí àwọn ìjọ bíi onítèbọmi (Baptist), Àgùdà (Anglican), Methodist àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̣̀ lọ. Bí ó tìlẹ̀ jé pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ onírúurú àjọ ati ìpàdé ni wọ́n gbé kalẹ lati ṣe àtúnṣe àwọn aṣa ijo,̣ sìbẹ̀ òrò kò ní ojú itu. Yàtọ̀ si èyì ìtànkálè ẹ̀sìn ìmàle (Islam) tún ṣàkóbá fun ẹ̀sìn ìgbàgbọ́ lọpọlọpọ, ìdàgbà sókè èsìn ìmàle bèrẹ̀ ni ogoòrùn – un mèfa odún leyin iku Jesu.

Àmósá laye òde òní kí èsìn ìgbàgbó má baá so òtító rè nù onírúurú ìgbìmò àti àjo lati gbe kalè láti mú àjosepo àti àsoyepo wà láàrin awon ìjo. Pèlúpèlú onírúurú ìjo loti n gbìyànju láti se ìwádìí ìjìnlè sínú bíbélì láti lóye ohun tí bíbélì n so.

  • IDOWU OLUWASEUN ADESAYO.



  1. "What is a Christian?". Christianity. Retrieved 2023-06-12. 
  2. "Dogma, Definition & Beliefs". HISTORY. 2017-10-13. Retrieved 2023-06-12. 
  3. "Ibeere rẹ: Ipa wo ni Kristi ṣe ninu awọn iṣe wa?". Dios eterno. 2021-12-06. Retrieved 2023-06-12. [Ìjápọ̀ tí kò ṣiṣẹ́ mọ́]
  4. Kaweendwa, Kornelius (2021-02-14). "The Role of the Christian in Society". Grace to the Nation. Retrieved 2023-06-12. 
  5. Astor, Yaakov (2010-08-18). "The Spread of Christianity". Jewish History. Retrieved 2023-06-12.  Text " We Bring Jewish History To Life " ignored (help)