Jump to content

Ọ̀rọ̀:Iléṣà

Page contents not supported in other languages.
Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ojúlówó àwọn ọmọ Yorùbá ni ilẹ̀ Yorùbá òde-òní ìjẹ̀sa jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára ojúlówó ọmọ Yorùbá tí kò se fí ọwọ́ rọ́ sẹ́yìn nínú ìtàn àwọn Yorùbá. Oríìsíìsí ìtàn ni a sì gbọ́ nípa orírun Ìjẹ̀sà gẹ́gẹ́ bí ojúlówó Yorùbá kó dà a ti lè gbọ́ wí pé olórí àwọn Ìjẹ̀sà jẹ òkan lára àwọn ọmọ méjèje tí Odùduwà bí. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàn ni a gbọ́ nípa ìsẹ̀dálẹ̀ Ìjẹ̀sà. Ó sì dàbí ẹni pé o sòro díẹ̀ láti sọ pe ọ̀kan ni fìdí múlẹ̀ jùlọ.

Lára ìtàn tí a gbọ́ ni wí pé ó jẹ́ àsà fún àwọn ènìyàn jàkànjàkàn láti wá bá Ajíbógun ní ibùdó rẹ̀, àwọn ènìyàn wònyí ni à ń pè ní “Ìjọ tí a sà”. Ní ìtẹ̀síwájú, ìtàn sọ fún wa wí pé òjígírí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tí ò bá Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀. Òjígírí yìí kan náà ló jẹ́ ọwá sí ìlú Ìpólé. Bákanna ni ìtàn sọ pé òjígírí ló jẹ Ògbóni sí ìlú ti Ìjẹ̀bú-jẹ̀sà. A sì tún gbọ́ wí pé nígbà tí Ajíbógun kúrò ni ilé-ifẹ̀, ilé-Ìdó ni o kọ́kọ́ dúró sí láti ilè Ìdó yi ló ti lọ sin òkú ọlọ́fin (Odùduwà) ní ilé-ifẹ̀, lẹ́yìn èyí ni a gbọ́ wí pé ìgbàdayé ni Ajíbógun padà sí, tí ó sì kú síbẹ̀. Ọ̀kà-òkìlè tí ó jẹ́ daodu fún Ajíbógun ni ó jẹ Ọwá sí ìlú- Ìlówá ti oun naa si sun ibẹ̀, bakanna ni Ọbarabara tí a mọ̀ sí Olokun. Esin ló je Ọwá sí Ìpólé. Ọwalusẹ ní ẹnití ó jẹ Ọwá àkọ́kọ́ sí ìlú Ilesà ti o nì. Bakanna ni a tún rí ìtàn míràn tó sọ fún wa nípa Ọwá Obòkun ti ilẹ̀-Ìjẹ̀sà wí pé nígbà tí Odùduwà tó n se bàbá fún (Ajíbógun) dàgbà ti ojú rẹ fọ̀ ni ifá Àgbọ̀níregùn ní kí wọn lo bu omi òkun wá kí ojú Odùduwà bàbá wọn lè là. Báyìí ní ó wá pe àwọn ọmọ rẹ̀ ni ọ̀kọ̀ọkan èjèejì wí pé ki wọn lọ bu omi lókun wá fún ìtọ́jú ojú òhun, sùgbọ́n èyí Ọwá re ló gbà láti lọ bu omi òkun naa wá. Nígbà tí ó ń lọ bàbá rẹ fun ní idà tí á mọ̀ sí idà ìsẹ́gun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ agbára, a gbọ́ wí pé nígbà tí o n lọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsòro àti ìdàmú ló bá pàdé ni ojú ọ̀nà rẹ sùgbọ́n o sẹ́gun wọn pẹ̀lú idà ìsẹ́gun ọwọ́ rẹ, sùgbọ́n kí ó tó dé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ló ti sọ ìrètí nù èrò yìí ló mú kí bàbá rẹ gan-an pàápàá sọ ìrètí nù, èrò yìí ló mú kí bàbá pín gbogbo ogún àti àwọn ohun ìní rẹ̀ fún àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ (Owá)

Sùgbọ́n ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn ènìyàn àti bàbá wí pé ó lè padà dé mọ́. nígbà tí o dé wọn fi omi òkun fọ ojú bàbá wọn ó sì là padà, lẹ́yìn èyí ló wá bi bàbá lérè wí pé àwọn ẹ̀gbọ́n oun ń kọ́ bàbá sì sàlàyé fún pe ò ń rò pé kò lè padà wá sí ilé mọ́ àti wí pé ò ń

Start a discussion about Iléṣà

Start a discussion