Ọba Ìkòyí
ORÍKÌ OBA ÌKÒYÍ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]LÁTI ENU ALÀGBÀ OYEKALE ALADE
OMO ISÉ FÓYÁNMU)
Ùn n lo ilé wa lóhun ò ò ò ò
Nílé ìkòyí omo erù ofà
Olóòótó omo gbáà, omo gbèdu
Yánbínlólú omo Arágáláká kee fikú pogun
1 Àrònì gbonra jìgì dagi erù oògùn nù
Omo gbélé
Omo gbégbèé
Omo gbé ijù, gbébi
Ò-gbódi-gbé-yàrá
O gbebadan ò kè pé, o gbákínmòórìn, o gbáawé
Ò-gbé-fìdítì-gbewàré
O gbákínelé, o gbéléefón run
O gbélé kúata, òtè ò tán e e bibì làá dé si
Kú fúnwon rérìn-ín Olóyè n ni baba mi
Ó níbi táa bá gbé, ibe nilé eni
Jagunjagun lèrò ìkòyí jé, omo oba a jò lápó wòròwòrò
Ogun ló bámi ni gbo
Mo dolú igbó
N lé mi lóhùnún ma dòsó esin
Bí bá n rogun
Èrò òdàn bamii lódan mo dèrò òdàn
Ogun ló bámi pàlàpálá mee dòpá à bon
Àsé Olú nìkòyi jé omo eèru Ofa
Témi bá n lo sónà ihè mo mo on lé wa
Olúkòyí àfeji, àfeji n lo bí onikoye àfòjò àfòjò
Olúkòyí àfòjò àfòjò, un lo wa bí Olúkòyí èèrùn gan gan gan
2 Olúkòyí èèrun gang an gan
N ló bí Olúkòyí ìrìwòwò
Olúkòyí ìrì wòwò, un ló bi Oníkòyí òdá gbágbá
Olúkòyí òdá gbá gba, un ló bi Oníkòyí ò koko
Un ba won tó pón kángun síkoto níjóhun
Témi bá n sónà bè mo monú ilé wa,
Eléyun nì taa lóbí, taa lóbí ?
Un ló bí òkéré lèrù gan gang an
Òkéré-lèrù gan gan gan gàgbon n baba won àgbà took tó kori òde ìsálayé
N lé ìkòòòyí omo eerù ofà
Olóòtó omo gbáà omo gbèdu
Yánbíniólú omo arágálá efikú pogun
Témi bá n lo sónà be mo molé wa
Omo Oba ìjí peké-peké
N lé ìkòòyí omo erù ofà
Àwon ni, àwon lomo Oba ìjí pokùn-pokùn
Ìjí mó pokùn mó
Igi àtòrì ni ko yá mó on pa
Ìji mó pagi àtòrì mó
Igi àtòrì òun nigi àse
3 Igi àtòrì òun nigi òrìsà òwójì
Láwòójì n be nlé owínsí dara
Omírìn dara lóri ofa òòò
Ota rìn dara lóri omi ò ò ò
Làwa n pèkòyì omo eerú ofà
Olóòtó ègi yánbinlolu omo arágálá e fikú pogun.
Àrònì gbonra jìgì dagun erùù oògùn nù
N lé ìkòòyí omo eerù ofà
Àlà e wà bí, inú ilé gbogbo kààà sí nkan kan nítiwa
Omo sírò n togun
Omo gbàro n togun
Omo jìgan n tode
Omo jìgan-jìgan láà rùkú alaigbodoràn mote serù bòtè
Mo letí mo fi n gbóràn láyé òòò
Enikéni kó mó rúmí gbajú òde baba mi lo olórí ogun
Àwa lomo òsèsè ‘kòyí
Tí mo réèrín gán án ni kú
Tú kí n dérin, elégbà ni mo di pèle níjó tí mo fi lo gán án ni ogun ìlànlá omo èrù oofà
Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa
Ìkòyí omo eerù ooofà
4 Olóòtó omo gbáà, omo gbèdu
Èyin obìnrin ìkòyí e mó pagbòn lágbòn mó
Gbogbo obìnrin ìkòyí tí bá n pagbòn lágbòn wón n rán oko won léti ogun ni
Lóòotó ni béè ni òdòdò on yùn
Àkà kè wà bí, inú ilé gbogbo káà sí n kan ní tiwa ìlànlá omo gbáà erù ooofà
Olóòtó omo gbáà omo gbèdu yánbínlólú omo arágálá omo e fi kú pogun
Orin: Eruwa nil é omo agbòn, ta n níkòyí ò nílé Omo agbon ?
Ègbè: Eruwa ni lé omo a
Lílé: Ta n ni kòyí ò ni lé omo agbòn
Ègbè: Èrùwà nilé omo agbòn
Lílé: Ta n níkòyí ò nílé omo agbon?
Ègbè: Èrùwà nilé omo agbòn on on.
Ìrìn mi gbèrè ó dilé wa lóhùn ún òòò
Àdesítèé oníkòyí òòò
Ìkòyí omo eerù oofà
Adésítèé loba tí nbe lé kòyí omo agbàawà
5 Olóòtó omo gbáà, omo gbèdu, yánbímilólú omo arágálá e fikú pogun,
Àrònì gbonra jìgì dabo erù oògùn nù
Okùnrin gbon gbon gbon bí ojó kanrí
Adésítèé,
Okùnrin gbòn gbòn gbòn bí eni fìbon tì
Ìsépo méjì omokùnrin
Adésítèé mo o bá tòde baba a re lo
Ìkòyí omo gbáà, omo gbedu yánínlólú omo arágálá e fi kú pogun
Témi bá n lo sónà bè mo monlé wa
Orin: Tapó tapó ;à á bómo ogun
Tapó tapó là á bomo ogun
Ìgbà ìkòyì ò tó déedé
Ègbè: Tapó là á bómo ogun
Lílé: Èsò kòyí ò rìkú sá
Ègbè: Tapó tapó làá bómo ogun
Lílé: Àgbà à kòyì ò ríkú sá
Ègbè: Tapó tapó làá bómo ogun
Lílé: Àgbà kòyí ò ríkú sá
Ègbè: Tapó tapó làá bómo ogun
Lílé: Àgbàà kòyì ò ríkú sá
Ègbè: Taapó taapó làá bómo ogun un.
ÀWON ÌTUMÒ ÒRÒ TÍ Ó TA KÓKÓ NÍNÚ OBA ÌKÒYÍ
1 Olúkòyi je jagunngagun tí kì í gbélé kò se inú ìgbé. Ìdì nìyi to wón fi máa n so pé èrùwà nilé omo agbòn.