Ọdún Adae
Ọdún Adae
Ọdún Adae (Twi: "ààyè ìsinmi") jẹ́ àjọ̀dún ní Ashanti. Tí wọ́n kà sí ọjọ́ ìsinmi, ó jẹ́ ìṣe àwọn babańlá àwọn èèyàn Ashanti people tí ó pàtàkì jù lọ.
Síse
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́fà yí po , Adae ní ọjọ́ àjọ̀dún méjì, ọ̀kan ní ọjọ́ Àìkú (Akwasidae)àti òmíràn ní ọjọ́ Ọjọ́rú(Awukudae). Ìyípo Adae máa ń di títúnse ní ẹ̀ẹ̀mẹ́sàn-án ní ọdún kan. Ní ṣíṣe Akan calendar, ọdún Adae kẹsàn-án, tí wọ́n ń pè ní Adae Kese Festival ("Adae ńlá"), máa ń papọ̀ pẹ̀lú àjọ̀dún Ọdún Tuntun. Fún ìdí èyí ó máa ń di ṣíṣe àjọyọ̀ láti dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ònilẹ̀ àti àwọn babańlá fún ìkórè tuntun.[1] Ọdún náà láàárín Adae kò ṣe é yí padà, ó ti wà bẹ́ẹ̀ láti ìgbà ìwáṣẹ̀.[2]
Ìse
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìgbáradì fún Adae máa ń fẹjú gidi gan-an. Ní ọjọ́ tí ìgbáradì máa ń di ṣíṣe ni wọ́n ń pè ní Dapaa,( Sábàá máa ń jẹ́ ọjọ́ Ìsẹ́gun àti Àìk) . Ní ọjọ́ yìí, àwọn ilé àti àwọn agbègbè tí ó yí wọn ká ni ó máa ń di títún se. Ní iwájú ilé olúwo, ìlù máa ń di lílù láti ọwọ́ "alùlù àtọ̀run" ( lẹ́yìn bíbọ̀wọ̀ fún olúwo), gbogbo ìrọ̀lẹ́ láti ìgbà tí oòrùn ti wọ̀ títí di alẹ́ pátápátá pẹ̀lú àwọn orin ayẹyẹ. Olúwo máa gbé oúnjẹ tí ó kún fún isu yam tàbí ọ̀gẹ̀dẹ̀ plantain. (láìsí iyọ̀ salt gẹ́gẹ́ bí ó ti di gbígbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí kò fẹ́ràn rẹ̀). Pẹ̀lú ayẹyẹ rẹ̀, ó máa wá tẹ̀síwájú lọ sí ìyẹ̀wù níbi tí àpótí (ìtẹ́) ayẹyẹ wà. Oúnjẹ tí ó di fífi sílẹ̀ lẹ́yìn tí olúwo ti jẹ máa di gbígbé wá sí àgbàlá yóò sì di fífọ́n kálẹ̀ fún àwọn ẹ̀mí òkú àwọn babańlá wọn láti jẹ ẹ́; agogo lílù yóò tẹ̀lé eléyìí láti ṣe àfihàn pé àwọn ẹ̀mí ti jẹ oúnjẹ náà. Ètùtù náà á tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìrúbọ àgùntàn láti ọwọ́ àwọn àlejò olúwo. Ẹ̀jẹ̀ ìrúbọ wọ̀nyí máa di fífi sàmì sí iwájú orí àti igbá àyà olúwo. Ìyá olórí máa wá ṣe ìrúbọ pẹ̀lú fufu (tí a fi ẹ̀gẹ́ cassava tàbí isu se). Lẹ́yìn náà rum yóò di dídà lórí àpótí náà, èyí tí ó bá sì kù yóò di jíjẹ fún àwọn tí ó péjú nínú ìyẹ̀wù náà. Gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ máa kí olúwo, ẹni tí ó jókòó ní gbangba ní àgbàlá pẹ̀lú ìkíni "Adae morn". Àwọn fọ́nrán ayẹyẹ yòókù ni kíka ewì láti ẹnu akéwì ààfin èyí tí ó máa ń fi ìṣe àwọn olúwo tí ó ti kọjá lọ hàn, ìlù yóò sì tẹ̀síwájú ní lílù pẹ̀lú ìwo fífọn. Àjọ̀dún náà máa ń wáyé títí di alẹ́ pátápátá. Àwọn oúnjẹ àti àwọn ohun mímu tí a fi ṣe ètùtù fún àpótí máa di yíyọ ní alẹ́ pátápátá, àyàfi fún awọ tí ó sì di gbígbà láàyè láti wà níbẹ̀ fún àkókò díẹ̀ si.[3]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Asante, Molefi Kete; Mazama, Ama (26 November 2008). Encyclopedia of African Religion. SAGE. pp. 36–. ISBN 978-1-4129-3636-1. https://books.google.com/books?id=B667ATiedQkC&pg=PT36. Retrieved 21 November 2012.
- ↑ Braffi 2002, p. 10.
- ↑ Roy 2005, p. 2.