Jump to content

Ọdún Batakari

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́


Ọdún Batakari jẹ́ ayẹyẹ ìbílẹ̀ tí ọba King Ayisoba ṣètò láti ṣe àfihàn Batakari, àwọ̀tẹ́lẹ̀ ìbílẹ̀ tí a fi ọwọ́ ṣe Ghanaian smock láti agbègbè Upper East Region ti Ghana.[1][2] Ayẹyẹ náà di ṣíṣe ní ọdún 2013 láti ìgbà náà sì ní ọdún náà ti di èyí tí wọ́n ń ṣe ní ọdọọdún ní Ghana.[1][2]

Ìpìlẹ̀ àti Ètò

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọba King Ayisoba se àgbékalẹ̀ èrò yìí látàrí ìfẹ́ rẹ̀ fún isẹ́ ọ̀nà àwọn ènìyàn Àríwá Ghanaian. Ó sọ pé àwọn ènìyàn àtijọ́ máa ń lo aṣọ húnhun, Batakari pẹ̀lú juju àti agbára òkùnkùn àti kọ́ńsáàtì náà jẹ́ ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti yí èrò àwọn ènìyàn padà àti láti yanjú àsìgbà èrò nípa wíwọ Fugu tàbí Batakari padà.[3] Ó gbàgbọ́ pé ìjíhìn rere nípa wíwọ aṣọ náà nípa àwọn ètò bíi èrò rẹ̀ padà ń sẹ̀dá iṣẹ́ fún àwọn ènìyàn ní èyí tí ó sì ń dín ìwọ̀n àìsísẹ́ kù àti láti dúró gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìpawówọlé fún àwọn ọ̀dọ́ ní Àríwá Ghana.[3]

Ọdún náà máa ń di ṣíṣe ní ọdọọdún ní àwọn ìlú kan pàtó ní Ghana ní àwọn ọjọ́ kan pàtó. Ní Accra, orísìírísìí ààyè ní ó ti di lílò fún ayẹyẹ náà, díẹ̀ lára wọn ni; National Theater àti Alliance Française. Àwọn àlejò òsèré máa ń di pípè láti ṣeré àti láti ṣe àfihàn àwọn aṣọ Batakari wọn, sibẹ̀, àwọn olùṣeré gangan ni ọba King Ayisoba àti àwọn ẹgbẹ́ òsèré Kologo rẹ̀. Àwọn àlejò òsèré kan tí wọ́n ti di pípè láti bu iyì kún ayẹyẹ náà ni; Wiyaala, Wanlov the Kubolor, Kwaw Kese, Yaa Pono, Atongo Zimba àti Zea láti Netherlands.[4]

Àwọn Ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. 1.0 1.1 "Government has not supported my Batakari Festival – King Ayisoba". www.ghanaweb.com. Retrieved 6 May 2020. 
  2. 2.0 2.1 "Government has not supported my Batakari Festival – King Ayisoba". www.etvghana.com. Archived from the original on 8 February 2023. Retrieved 6 May 2020. 
  3. 3.0 3.1 "Alliance Francaise launches 2017 Batakari Festival". www.ghanabusinessnews.com. Retrieved 6 May 2020. 
  4. "Batakari festival at Alliance Française". www.graphic.com. Retrieved 6 May 2020.