Ọjọ́ Ìbí

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti Ọjọ́ọ̀bí)
Àwọn abela ti won fi ko ikini ni Èdè Gẹ̀ẹ́sì

Ọjọ́ ìbí rẹ ni ìṣè-rántí ọjọ́ tí a bí ọ sáye. [1] Ọjọ́ ìbí ni ajodun ojo pato ti a bi enikan.

Gẹ́gẹ́ bí arákùnrin Simon Jacobson ti ṣé lálàyé, [2] ó dára kí a máa dunnú fún àwọn ohun ti a jẹ́ láyé àti ohun tí ati gbé ilé ayé ṣe. Sùgbón kí awá tó leè máa ṣe eléyìí, a ní lati kọ́ mó rírì ìbí wa gan an.

Ìbí ni ìbẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé ẹ̀da. òhun ni fèrèsè si ìgbé ayé ẹ̀dá, lati le ní àbáyọrí ipa rẹ. Nítorínà ọjọ́ ìbí jẹ́ àkókò kan pàtàkì, tó yẹ kí a yà sọ́tọ̀ fún ra ẹni, bí ẹní ya ọjọ́ ìdásílẹ̀ orílẹ̀-èdè tàbí ọjọ́ tí a ṣẹ̀da ilé-iṣẹ́ kan. Síbẹ̀, ó kọ ja pé kí a kan gba ẹ̀bùn lásán lọ. ó tún jẹ́ àkókò láti rántí awọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó ti ṣelẹ̀. lati ṣe àjọyọ̀, ìdúpẹ́ ati àtún gbéyẹ̀wò bí a ti ṣe nlo ayé wa dáradára si.

Nítorí àkókò àti ìgbà a maá yí, áwọn nkan pàtàkì a máa wáyé ní àkókò ọjọ́ ìbí rẹ lọ́dọdún. irúfẹ́ okun kan naa tí Adẹ́da fi kun ọ yóò tún ru ọ́ sóke ní àkókò yi. ojúṣe wa sì ni lati túraká pẹ̀lu. A le ṣe èyí nípa jíjọ̀wọ́ ara wa fún Adẹ́da wa àti láti lo àwọn ẹ̀bùn ati ohun tí o wà ní ìkáwọ́ wa láti ṣe ara wa ati alabágbé àyíka wa ati gbogbo or=lẹ̀ àgbáye loore bí Adẹ́da ti n fẹ́.

Ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ni a fi n ṣe àjọyọ̀ ìbí fún ra rẹ̀, àti ayọ̀ ìwàláàyè. ó sì tún jẹ́ àkókò láti tún inú wa rò lo rii, ki ni ìpààlà larin àwọn àṣeyọrí tí atiṣe ati àwọn tí a tún leèṣe? ṣé mo n lo àkókò mi dáradára tabi mi ò sí ni ojú ọ̀na gaan tí o yẹ kí o wa? Bawo ni mo ṣe lee mú èrò àti ìse mi dógba?

Ọjọ́ ìbí tun le mú wa ní àròjinlẹ̀ nípa ohun tí ìbí ènìyàn jẹ́.Láti rántí ọjo ìbi jẹ́ ànfàní láti pinnu ìbẹ̀ẹ̣̀rẹ̀ ìgbé-ayé tuntun. kò ní fiṣe bí ohun kan ti rí lánànan, tàbí ní àkòkò díẹ̀ sẹ́hìn, gbogbo ìgbà ni a maa ní ore-ọ̀fẹ́ áti tún ìtàn ayé wa kọ. Ọjọ ìbí a máa tunilára, a máa fún ni ni ore-ọ̀fẹ́ láti ṣe àgbékalẹ̀ ayé ara ẹni. kii ṣe ní ti àwọn nkan àfọwọ́bà nìkan, sùgbọ́n pẹ̀lú àwọn ohun tí nṣe tẹ̀mí.

O lèè kó mọ̀lẹ́bí àti àwọn ojúlùmọ̀ rẹ jọ ní ọjọ́ ìbí rẹ kí ẹ́ jùmò ṣe ìgbéléwò àwọn ohun tí o ṣe ànfàní tí ó sì ṣe pàtàkì.

Kò wá sí ohun tí ó dára tó kí a ṣe ọjọ́ ìbí pẹ̀lú ọkàn ìṣòore. Tí a bá fẹ́ fi ọkàn ọpẹ́ wa han iba dára kí a ṣe pẹ̀lú ohun àrítọkasí rere kan, Ni gbatí a kò tilẹ̀ ṣee lana tàbí pe ṣe ni a fi ipá mu wa, tàbí pé ẹnìkan ni ó tọ́ka rè síwa. Sùgbọ́n ti ó jẹ́ ohun tí o wá láti inú ọkan ẹni láti dúpẹ́ ìbí áti ìdásí wa.

irúfẹ́ nkan bayìi a maa mú inú Ẹlẹ́da ẹni dùn. Èyí gan ni ìríri ótítọ́ pé abíniwáyé.

Àwọn ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "Birthday definition and meaning". Collins English Dictionary. 2017-12-20. Retrieved 2023-04-11. 
  2. Jacobson, Simon (2002-07-31). "How Should We Celebrate our Birthday?". Chabad.org. Retrieved 2023-04-11.