Ọrọ orúkọ

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ọ̀rọ̀-orúkọ ní èdè Yorùbá

Ọ̀rọ̀-orúkọ ní ọ̀rọ̀kọrọ̀ tí a lè lò gẹ́gẹ́ bí i olùwà fún ọ̀rọ̀ ìṣe, àbọ̀ fún ọ̀rọ̀ ìṣe àti àbọ̀ fún ọ̀rọ̀ atọ́kùn.

Ọ̀rọ̀-orúkọ ni ọ̀rọ̀kọrọ̀ tí ó lè dúró gẹ́gẹ́ bí i ìdánimọ̀ fún enìyàn, ẹranko, ibìkan, tàbí nǹkan.

Bí àpẹẹrẹ:

Ènìyàn: Àánú, Ọmọladé, Pẹ̀lúmi, Ṣeun, abbl.

Ẹranko: ajá, olońgbò, ẹkùn, àmọ̀tẹ́kùn, ejò, abbl.

Ibìkan: Ìbàdàn, Ejìgbò, Oshòdì,Ìkòròdú, Ìdúmọ̀tà, abbl.

Nǹkan: abọ́, ilẹ̀kẹ̀, ẹní, àwo, bàtà, aṣọ, ìgò, abbl.


A tún le dá ọ̀rọ̀-orúkọ mọ̀ nípa ipò wọn nínú gbólóhùn, nínú àwọn gbólóhùn alábọ́dé Yorùbá, ọ̀rọ̀-orúkọsáàbà máa ń jẹ́ olùwà àti àbọ̀.

Bi àpẹẹrẹ:

  1. Ṣọlá jẹ ẹran.
  2. Ọpẹ lọ ọjà.
  3. Tolú fọ aṣọ.
  4. Adé fọ bàtà.

P.s: Nígbà míìràn, a máa ń bá àwọn ìsọ̀rí ọ̀rọ̀ mìíràn pàdé ní ipò olùwà àti àbọ̀ nínú àwọn gbólóhùn alábọ́dé, tí wọn kì í bá ṣe àwọn ọ̀rọ̀ arópò-orúkọ (bí i mi, a, o, ẹ, ó, wọ́n abbl.) wọn ma jẹ́ àwọn ọ̀rọ̀ afarajorúkọ ( bí i èmi, àwa, ìwọ, ẹ̀yin, òun,àwọn abbl.).


Tí a bá ronú sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ọ̀rọ̀ arọ́pò-orúkọ àti ọ̀rọ̀ afarajorúkọ máa tóka sí a ma ri pé ọ̀rọ̀-orúkọ ni wọ́n.



Àwọn Ìtọkasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]