Jump to content

2001 United Nations Climate Change Conference

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
United Nations Climate Change Conference

COP7
Fáìlì:COP7 Logo.jpg
Date(s) 29 October 2001 (2001-10-29)

10 November 2001 (2001-11-10)
Location(s) Marrakech, Morocco
Previous event ← The Hague / Bonn 2000/01
Next event New Delhi 2002 →
Participants UNFCCC member countries
Website Report of the conference of the parties

Àpéjọ Ìyípadà Ojú-ọjọ́ ti United Nations ti ọdún 2001 wáyé láti ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n (29) oṣù kẹwàá, sí ọjọ́ kẹwàá oṣù kọkànlá, ọdún 2001, ní Marrakech, ìlú Morocco. Àpérò náà pẹ̀lú àpéjọ ẹlẹ́ẹ̀keje ti àwọn ẹgbẹ́ (COP7) sí United Nations Framework Convention on Climate Change (UNFCCC). Àwọn olùdúnàdúra náà parí iṣẹ́ náà lórí ètò iṣẹ́ ti Buenos Aires, tí wọ́n sì parí púpọ̀ nínú àwọn àlàyé ìṣiṣẹ́ àti ṣètò ìpele fún àwọn orílẹ̀-èdè láti fọwọ́ sí ìlànà Kyoto. Ìpinu àpapọ̀ tí wọ́n ṣe ni a mọ̀ sí Marrakech Accords. Aṣojú àjọ ti United States ń wòye ọ̀rọ̀ náà, ó sì kọ̀ láti kópa tààrà nínú ìdùnàdúra náà. Àwọn ẹgbé mìíràn tẹ̀ siwájú nípa níní ìrètí pé United States máa dá sí ètò náà bó bá yá, àti pé wọ́n máa gbé ìgbésẹ̀ láti fọwọ́ sí ìlànà Kyoto nípasẹ̀ nọ́ḿbà àwọn orílẹ̀-èdè tó nílò láti mú un wá sínú agbára. Déètì àpéjọ àgbáyé lórí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ láti mú ìdàgbàsókè wá tó jẹ́ oṣù kẹjọ sí oṣù kẹsàn-án, ọdún 2022 ni wọ́n sún síwájú láti ri dájú wípé èrò láti mú ìlànà Kyoto wá sí ìmúṣẹ. Àpéjọ àgbáyé lórí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ yẹ kó wáyé ní Johannesburg, ní South Africa.