Jump to content

Èdè Gẹ̀ẹ́sì Áfríkà Amẹ́ríkà

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
(Àtúnjúwe láti AAVE)

Àpèjá AAVE duro fun African-American Vernacular English, ìyẹn ni, ede Geesi tí àwọn ọmọ Afrika Amerika n so ni ile Amerika. Ọ̀kan nínú àwọn èdè àdúgbò ni. Àwọn orúkọ mìíràn tí wọ́n tún ń pe èdè yìí ni Black English Vernacular (BEV), Afro-American English àti Black English. Àwọn àmì ìdámò èdè yìí ni pé wọn kì í lo ‘s’ tí ó jẹ́ àtọ́ka ẹni kẹ́ta ẹyọ, bí àpẹẹrẹ, She walk , wọn kìí lo be, bí àpẹẹrẹ, They real fine. wọ́n sì máa ń lo be láti tọ́ka ibá atẹ́rẹrẹ bárakú, bí àpẹẹrẹ, Sometime they be walking round here. A kò le so pàtò ibi tí èdè yìí ti sẹ̀. Àwọn kan sọ pé láti ara kirio (Creole) ni ṣùgbọ́n àbùdá rẹ̀ kọ̀ọ̀kan tí a ń ṣe àkíyèsí rẹ̀ lára èdè Gẹ̀ẹ́si tí wọn ń sọ ní gusu Àmẹ́ríkà jẹ́ kí àwọn kan gbà pé láti ara èdè Gẹ̀ẹ́sì ni ó ti wáyé. Èdè yìí wá ní àbùdá tirẹ̀ nígbà tí àwọn dúdú kọjá sí àwọn ìlú ńláńlá. wọ́n wá ń lo èdè yìí gẹ́gẹ́ bí àmì àdámọ̀ fún ara wọn.


Ọmọ Afrika Amerika