AJA ỌDẸ
Ààló Ajá Ọdẹ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ààlọ oooooo
Ààlọ
Ààlọ mi dá lórí ọdẹ àti ajá rẹ.[1]
Ẹ fi ààló àpagbè yìí ṣe ara rindin Ajá Ọdẹ Ní ayé àtijó, ọkùnrin kan wà, iṣẹ́ ọdẹ ni ó yàn láàyò. Ọkùnrin yìí gbóná nínú iṣẹ́ ọdẹ ṣíṣe. Ohun tí ó fún ní òkìkí nínú iṣẹ́ ọdẹ yìí ni ajá. Ọkùnrin ọdẹ yìí sí féràn ajá rẹ̀ púpò wọn kì í sì ya ara wọn nígbà kan. Àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara ọdẹ yìí àti ajá rẹ. Nígbà tí ó di ọjọ kan, ọdẹ yìí kò rí ajá rẹ̀ mọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí wá ajá rẹ kiri. Nígbà tí ó pẹ́ tí ó ti ń wá ajá rẹ̀ kiri, ó sii gbúròó wípé àwọn kan ni wọn gbé ajá òun pamọ́. Ọkùnrin yìí gba ọ̀dọ̀ ọba ìlú lọ láti lọ f'ẹjọ́ sùn. Ọba gbọ́, ó si pe gbogbo ìlú jọ ó pe ọdẹ àti àwọn tí wọ́n gbé ajá ọdẹ yìí. Ọba sọ pé kí wọn ó wá pe ajá náà bí wọn ṣe máa ń pe tí ó fi máa ń dá wọn lóhùn. Àwọn tí ó jí ajá ni wọn kọ́ jáde, wọn bẹ̀rẹ̀ sí pe ajá yìí. Wọn pèé títí ajá na kò ṣe bí ẹni gbọ́ nǹkankan. Nígbà tí ó ṣe, ọba pe ọdẹ kí ó wa pe ajá rẹ̀.[2]
ORIN ÀÀLÓ
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ọdẹ: Ajáà mi da
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọde
Ọdẹ: Ajáà mi dà
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Òsọ sàkà gbe mì
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ : ajá mi dà
Ò gbálẹ̀ gbáràwé
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọdẹ
Ọdẹ: Ajáà mi da
Àwọn ará ìlú: Ajá Ọde
Bí Ọdẹ yìí ti ń kọrin bẹẹ ni ajá bẹ̀rẹ̀ sí gbó tí ó ń ké tí ó sì ń gbìyànjú àti tú ara rẹ̀ sílẹ̀. Bí Ọdẹ tún ti ń kọ orin yìí lẹ́ẹ̀kan sí ni ajá já'kùn, tí ó sì ń sá tọ olówó rẹ̀ ọdẹ lọ. Àwọn ènìyàn hó gèè, ọba sì pàṣẹ pé kí ọdẹ máa mú ajá rẹ lọ, kí wọn ó sì lọ ti ojú àwọn olè tí wọn jí ajá yọdà, kí wọn ó sì ti ẹ̀yìn wọn tibọ àkọ̀ rẹ̀. Eléyìí jásí pé wọn pa wọn.
Ẹ̀KỌ́ INÚ ÀÀLỌ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ààlo yìí kọ́ wa pé kí á mọ́ máa jalè.