Aalo Ìjàpá àti elédè
Ààlọ́ ooooo
Ààlọ
Ààlọ́ mi dá firigbagbòó, ó dá lórí Ìjàpá àti ẹlẹ́dẹ̀.[1]
Ní ìgbà láíláí , Ìjàpá àti Ẹlẹ́dẹ̀ jọ ńṣe ọ̀rẹ́ . Ní ọjọ́ kan, Ìjàpá lọ yá Owó lọ́wọ́ Ẹlẹ́dẹ̀ pẹ̀lú ìlérí pé títí ọjọ́ mẹ́ta ohun yíò dá owó yìí padà. Ṣùgbọ́n lẹ́hìn ọjọ́ mẹ́ta, Ìjàpá kò rí Owó yìí dá padà fún Ẹlẹ́dẹ̀ . Elédè bèèrè si para ọdọ Ìjàpá láti gba owó rẹ padà ṣùgbọ́n pàbó ló jásí. Ní ọjọ́ kan bí Ìjàpá se gburo pé Ẹlẹ́dẹ̀ tún ń bọ̀ ní ilé òun láti wá sin gbèsè tí òhun jẹ , báyìí ni Ìjàpá wá da ọgbọ́n ewe. Ìjàpá sùn sílè , ó si àyà sókè , ló bá ní kí Yánníbo, Ìyàwó rẹ̀ kí o máa lọ ata ní àyà òhun. Ìgbà tí Ẹlẹ́dẹ̀ dé tí ó béèrè Ìjàpá láti gba owó rẹ , Yánníbo dá Ẹlẹ́dẹ̀ lóhùn pé Ìjàpá kò sí nílé . Inú bí Ẹlẹ́dẹ̀ ló bá fi ìbínú ju ohun tí Yánníbo fi ń lọ ata nù . Báyìí ni Ìjàpá sáré wọlé tí ó ń béèrè ohun tí Yánníbo fi ń lọ ata. Yánníbo bá se àlàyé fún Ìjàpá pé ọ̀rẹ́ rẹ Ẹlẹ́dẹ̀ ti fi ìbínú ju sí ìta ní ìgbà tí kò bá Ìjàpá nílé. Ìjàpá bá kọjú sí Ẹlẹ́dẹ̀ pé , Págà ! Owó tí Òhun jẹ Ẹlẹ́dẹ̀ tí òhun fẹ́ san padà wà nínú ohun tí Yánníbo fi ń lọ ata tí Ẹlẹ́dẹ̀ jù sí ìta. Ìjàpá sọ fún Ẹlẹ́dẹ̀ kí ó yára lọ gbé e wá padà bí bẹ́ẹ̀kọ Ẹlẹ́dẹ̀ kò níí rí Owó rẹ gbà. Ìgbátí Ẹlẹ́dẹ̀ dé ibi tí ó ju ohun tí Yánníbo fi ń lọ ata sí, kàyéfì ńlá ló jẹ́ fún torípé kò rí ohun kóhun níbè . Báyìí ni Ẹlẹ́dẹ̀ se bẹ̀rẹ̀ sí níí fi imú tú ilẹ̀ kiri títí di òní tí ó ń wá ọlọ ata Yánníbo kiri o.[2]
Ẹ̀KỌ́ INÚ ÀÀLỌ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìtàn yìí kó wa pé kí á máa ni sùúrù pẹ̀lú ohun gbogbo tí a bá ńṣe.