Aaron Eckhart

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Aaron Eckhart
Eckhart ní ọdún 2016
Ọjọ́ìbíAaron Edward Eckhart
Oṣù Kẹta 12, 1968 (1968-03-12) (ọmọ ọdún 56)
Cupertino, California, U.S.
Ẹ̀kọ́Brigham Young University (BFA)
Iṣẹ́Actor
Ìgbà iṣẹ́1992–present

Aaron Edward Eckhart (tí a bí ní ọjọ́ kejìlá oṣù kẹta ọdún 1968) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n bi ní Cupertino, California, Eckhart lọ sí orílẹ̀ èdè United Kingdom nígbà tí ó wà ní èwe. Ó bẹ̀rẹ̀ sí ń ṣeré nígbà tí ó sì wà ní ilé ìwé kí ó tó lọ sí Australia. Ó fi Ilé-ìwé High School kalẹ̀ láì gba ìwé ẹrí ṣùgbọ́n ó padà gba àmì-ẹ̀yẹ diploma, ó sì kàwé gboyẹ̀ ní Yunifásitì Brigham Young (BYU) ní Utah, U.S., ní ọdún 1994 pẹ̀lú àmì-ẹ̀yẹ Bachelor of Fine Arts nínú eré ṣíṣe.

Nígbà tí ó sì jẹ́ ọmọ ilé ìwé ní BYU, Eckhart pàdé adarí eré Neil LaBute. Ọdún márùn-ún lẹ́yìn ìgbà náà, Eckhart nínú eré LaBute tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ black comedyIn the Company of Men (1997), ó sì padà farahàn nínú eré mẹta míràn tí Neil dárí.

Eckhart gbajúmọ̀ sí nígbà tí ó kó ipa George nínú eré Erin Brockovich (2000), àti ní 2006, wọ́n yán mọ́ ara àwọn tí ó tó sí àmì ẹyẹ Golden Globe fún ipa rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Nick Naylor nínú Thank You for Smoking. Ní ọdún 2008, ó ṣeré nínú eré Christopher Nolan tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Batman The Dark Knight gẹ́gẹ́ bi Harvey Dent / Two-Face.

Ní ọdún 2019, ó ṣeré nínú eré Roland Emmerich tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ Midway.