Abẹ́lé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Abẹ́lé jẹ́ ìlànà mímú àwọn ẹranko àti ewéko látinu igbó wásílé lati múwọndára tàbí yíwọnpadà fún lílò àwa èníyàn bóyá fún ónjẹ,iṣẹ́,aṣọ,oògùn,bàtà àtibẹ́ẹ̀lọ.

Ohun ọ̀gbìn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Láti nkan bii ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́wàá sẹ́yìn (10,000 years) làwọn ènìyàn ti n ṣàwárí àwọn ohun ọ̀gbìn onírúunrú láàárín àwọn àgbègbè bíi Tígírísì,Efurete ní Mẹsopotámíà towadi Iran,Iraq,Turkey ati Siria loni,wọ́n farabalẹ ṣayẹwo ohun ọgbin kọọkan àti eweko biwọn ṣele gbìín tómáafidáa láti mú ónjẹ jáde. Lára àwọn ohun ọ̀gbìn tiwọn kọkọ lo ilana abẹlé fun lawọn orilẹede bíi Mesopotamia,Asia,Áfíríkà,apa iwọ ati ila oorun Amerika ni alikama,ọka bali,ẹwa lẹntili,ẹwa olyin, irẹsi,ọdunkun (potato) bakan naa paki,agbado,ọgẹdẹ ati bẹẹbẹlọ. Ónjẹ nìkan kọ́ ni irúgbìn ilé àwọn mii tún wà bíi òwú,àwọn òdòdó ati bẹẹbẹlọ tó wúlò fún aṣọ,ọ̀ṣọ́ ilé,oògùn àtàwọn nkan mii.

Ẹranko Ilé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Àárín àkókò kan naa tiwọn ṣawari ohun ọgbin naa niwọn ṣawri awọn ẹranko tole ba eniyan gbélé ní guusu ila oorun Asia ó sì ṣeeṣe kójẹ́ ewúrẹ́ niwnọ́n kọ́kọ́ sọ di ẹran ilé tí àgùtàn,Ologbo ati ajá sì tẹ̀le .Awọn ohun abìyẹ́ naa fara han.edìyẹ,pẹ́pẹ̀yẹ,awó,ẹyẹlé,tòlótòló atibẹbẹlọ. Nígbà tóyá wón fún àwọn ẹranko nlanla naa láfiyèsí lati sọwọn di ẹran ile irúu bíi Maalu,Ẹṣin,Ràkúnmi,ati Ẹlẹdẹ.Biwon ti n sin awọn ẹranko yi ni ile bẹẹ ni iṣesi ati iwa wọn túbọ̀ n yàtọ̀ sí ti awọn babanla wọn ninu igbo,fun apẹẹrẹ latinu ẹ̀yà ìkokò(wolf grey)ni aja ti wa amọ iwa rẹ̀ ti yàtọ̀ siti ojulowo ìkokò,bakan naa edìyẹ igbo kii wuwo ju poun meji lọ,amọ ediyẹ ile ma n wiwo to pọun mẹ́tàdínlógún bẹẹ naa niwọn tún máa n ye ẹyin ju ediyẹ́ igbo lọ gboogbo aṣeyọri yìí ṣeéṣe lateri ilana abẹ́lé[1] [2]

Ìwúlò Abẹ́lé[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Lakọkọ nan onjẹ pọ sii oriṣiriṣi onjẹ lowa fun jijẹ nigbakigba ẹran ọsin ilé muki iṣẹ́ àgbẹ̀ rọrùn apẹẹrẹ tiwọn ba so àjàgà mọ́ akọ maluu meji lọrun wọnle fiwọn roko kọja ibi teeyan le ṣee de,wọntunle fi aja ṣọdẹ,bakan na irin ajo rọrun wọnle gun ẹṣin lọsibi to jinna fun ọrọ̀ ajé ati fun awọn nkan mii.ọ̀pọ̀ anfaani lowa ta o le sọ tan nínú ìlànà abẹ́lé.

Àwọn Ìtọ́ka si[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. http://news.nationalgeographic.com/news/2004/04/0408_040408_oldestpetcat.html
  2. http://dienekes.blogspot.com/2008/10/dog-domestication-in-aurignacian-c.html