Abẹli Ìdòwú Ọlayinka
Abẹli Idowu Ọlayinka FAS (ti a bi ní ọjọ́ kẹrìndínlógún, Oṣù Èrèlé 1958) jẹ́ ọmọ orílẹ̀èdè Nàìjíríà. Ọ̀jọ̀gbọ́n applied geophysics. Ó ti fi ìgbà kan jẹ́ igbákejì Gíwá àti Gíwá Yunifásítì Ìbàdàn. Bákan náà ni ó jẹ́ Ààrẹ Ẹgbẹ́ Ìṣàkóso Ìwádìí àti ọ̀tun-ìmọ apá, Ìwọ̀ - Oòrùn Áfíríkà.
Ní 2012, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹgbẹ́ Nigerian Academy of Science, ajọ́ alákadá tí ó ga jù lọ ní Nàìjíríà. Òun àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Isaac Folorunso Adewole tí ó jẹ́ Gíwá kọkànlá tí Yunifásítì Ìbàdàn, ni wọ́n fi mọlé sínú àjọ náà. Ọ̀jọ̀gbọ́n Mojeed Olayide Abass, Ọ̀jọ̀gbọ́n Ìmọ̀ Sáyẹ̀nsì Ẹ̀rọ Ayára-bí-àṣá tí Yunifásítì Àpapọ̀ tí ìlú Èkó àti Ọ̀jọ̀gbọ́n Akinyinka Omigbodun, Ààrẹ Kọ́lẹ́jì àwọn oníṣẹ́-abẹ́ Apá Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà àti Olùdarí Kọ́lẹ́jì Ìṣègùn òyìnbó, Yunifásítì ti Ìbàdàn.
Ní oṣù Òwàrà ọdún 2015, wọ́n yàn án gẹ́gẹ́ bí Gíwá Iléẹ̀kọ́ Yunifásítì Ìbàdàn nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Isaac Folorunso parí sáà tirẹ ní Oṣù Bélú, 2015. Ọ̀jọ̀gbọ́n Olayinka parí sáà tirẹ̀ ní ọgbọ̀n ọjọ́, Oṣù Bélú, Ọdún 2020 tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Adébọ́lá Babátúndé Ẹ̀kànọlá sí gba ọ̀pá àṣẹ ìṣàkóso.
Ẹ̀kọ́
Wọn bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Olayinka ni ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Ẹ̀rẹnà, Oṣù 1958 ní Odò-Ìjẹ̀sà, ìlú kan ní Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun. Ó bẹ̀rẹ̀ Iléẹ̀kọ́ rẹ̀ ní Iléẹ̀kọ́ Alákọ̀bẹ́ẹ̀rẹ̀ Bartholomeow ní Odò-Ìjẹ̀sà, ó lọ sí Iléẹ̀kọ́ Gírámà Iléṣà níbi tí ó ti ṣe WASC ní ọdún 1975. Ó gba oyè BA nínú imọ̀ Ẹ̀kọ́ nípa ilẹ̀(Geology) ní Yunifásítì ti Ìbàdàn. Nígbà tí ó ṣe tán bíi àgùnbánirọ̀ ní ẹ̀ka Hydrogeology àti Hydrology tí Ẹ̀ká... ní ọdún 1982, ó ṣiṣẹ́ ráńpẹ́ ní Deptol Consultants gẹ́gẹ́ bí onimọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ilẹ̀ kí ó tó lọ sí Yunifásítì London. Ó gba oyè Master's ní Geophysics ní 1984, ọdún yìí náà ni ó gba Dípúlómà tí Kọ́lẹ́jì Imperial ní oṣù Agẹmọ ọdún 1984 kí ó tó di pé ó gba àmì-ẹ̀yẹ ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí ó sọ di Ọ̀mọwé nínú imọ̀ Geophysics ní Yunifásítì Birn. Ní oṣù Igbe 1997, ó lọ ṣe iṣẹ́ ìwádìí ní Yunifásítì Technical, Braunschweig. Láti ìgbà tí ó ti gba oyè Ọ̀jọ̀gbọ́n, ó ti mójútó ọ̀gọ̀rọ̀ akẹ́kọ̀ọ́, akẹ́kọ̀ọ́ Master's mẹ́rìndínlààdọ́rin àti akẹ́kọ̀ọ́ fún Oyè Ọ̀mọwé mẹ́sàn-àn. Ó ti gbé iṣẹ́ àpilẹ̀kọ ó lé àádọ́ta jáde ní àwọn jọ́nà akadá tó lókìkí.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ^ "Fellows of the academy". www.nas.org.ng. Archived from the original on November 9, 2015. Retrieved September 15, 2015.