Abúlé
Ìrísí
Abúlé jẹ́ ìlú kékeré tí àwọn ènìyàn ń gbé, ó tóbi ju àbà lọ ṣùgbọ́n kò tóbi tó ìgboro. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà ni àwọn ènìyàn máa ń pe àbà náà lábúlé, òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, àbà kéré ju abúlé lọ.[1] Abúlé sáàbà máa ń wà ní ìgbèríko, tí wọ́n máa ń wà lábẹ́ ìgboro, tí ó sìn ní ọ̀wọ́ àwọn olùgbé rẹ̀. Àwọn ilé abúlé sáàbà máa ń wà káàkiri, ìyẹn ni pé, ní ọ̀pọ̀ abúlé, ilé kéréje kéréje ló sáàbà máa ń wà níbẹ̀ káàkiri.
Nígbà láéláé, abúlé jẹ́ àwọn ìlú kéréje kéréje tí wọ́n tí máa ń ṣe iṣẹ́ àgbẹ̀ adákojẹun fún ara wọn tàbí adákotà fún àwọn ìlú ńlá tàbí ìgboro. Lórílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì, àbà tí ó bá ti ní ilé ìjọsìn ẹsìn ọmọlẹ́yìn Jésù ti tó pè ní Abúlé. [2]
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Society, National Geographic (2013-08-22). "village". National Geographic Society. Archived from the original on 2021-04-21. Retrieved 2021-04-19.
- ↑ Dr Greg Stevenson, "What is a Village?" Archived 23 August 2006 at the Wayback Machine., Exploring British Villages, BBC, 2006, accessed 20 October 2009