Action Against Trafficking in Persons And Smuggling of Migrants in Nigeria (a-tipsom)

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Action Against Trafficking in Persons And Smuggling of Migrants in Nigeria tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọdún 2018 látàri àjọmọ̀ tó wà láàárín àjọ European Union àti ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, jẹ́ àjọ tó ń rí sí ìdínkù gbígbé àwọn èèyàn láti oríẹ-ede Nàìjíríàlo si orílẹ̀-èdè mìíràn lọ́nà àìtọ́. International and Ibero-American Foundation for Administration and Public Policy (FIIAPP) ni àjọ tó rí sí ìmúṣe ètò yìí.[1][2][3] Àwọn obìnrin àti ọmọdé gan-an ni wọ́n tọ pinpin mọ́ nítori àwọn gan-an ni wọn máa ń faragbá a jù.

Àfojúsùn wọn ni; láti mú kí ìṣèjọba àjọ tó ń rí sí ìṣílọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríàtúnbọ̀ tẹ̀wọ̀n si, láti dènà gbígbé àwọn èèyàn kúrò lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà lọ́nà àìtọ́, dídàbòbò àwọn olùfaragbá láti ìlú Europe, láti mú kí ọwọ ba àwọn ọ̀daràn yìí kí wọ́n sì wá ìjìyà tó tọ́ fún wọn, àti làti mú kí ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó yanrantí wà láàárín àwọn àjọ tó ń dojúìjàkọ ẹ̀sùn búburú yìí.[4][5]

Rafael Monila sì ni olùdarí Action Against Trafficking in Person and Smuggling of Migrants (A-TIPSOM).[6][7]

Ìtàn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ọdún 2018 ni wọ́n dá àjọ yìí sílẹ̀, látàri àjọmọ̀ tó wà láàárín àjọ European Union àti ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, tí European Union sì jẹ́ onígbọ̀wọ́ wọn. A-TIPSOM gbé ìpàdé ọdọọdún kan kalẹ̀ tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ní ìlú Àbújá, lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ní ọdún 2019, tí eléèkejì irú rẹ̀ rẹ̀ sì wáyé lóṣù kejì àti kẹta ọdún 2022, ní ìlú Toronto, ní Canada.

Àfojúsùn àti iṣẹ́ wọn[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

A-TIPSOM ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àjọ mìíràn lóríṣiríṣi tí kìí ṣe àjọ ti ìjọba, tó ń rí sí gbígba àwọn olùfaragbá ìṣílọ lọ́nà àìtọ́ là,[8] ṣíṣe ìpolongo láti tako ìwà ṣíṣí àwọn èèyàn kúrò láti ibi kan sí ibòmìíràn,[9] kíkọ́ àwọn èèyàn, àti ṣíṣe ìgbékalẹ̀ àwọn ètò lọ́lọ́kan-ò-jọ̀kan nípa lílo áwọn òté márùn-ún kan tíí ṣe; àìfààyègbà, ìdáábòbò, ìfọwọ́sowọ́pọ̀, ìfìyàjẹ àti ìgbófin kalẹ̀.

[10]

Awon Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "About Us". A-TIPSOM Nigeria. 2019-09-10. Retrieved 2022-03-30. 
  2. George, Aderogba (2022-03-02). "NACTAL begins 3-day training on legislative framework in Keffi". News Agency of Nigeria. Archived from the original on 2022-03-08. Retrieved 2022-03-30. 
  3. "Trafficking: Arm NAPTIP, track illicit TIP funds, JIFORM tells FG". Tribune Online. 2021-12-12. Retrieved 2022-03-30. 
  4. "A-TIPSOM Nigeria". A-TIPSOM Nigeria. 2020-02-25. Retrieved 2022-03-29. 
  5. "A-TIPSOM Film Exhibition". FilmFreeway. Retrieved 2022-03-29. 
  6. "EU disburses €10m to combat human trafficking in Nigeria". Vanguard News. 2021-05-21. Retrieved 2022-03-30. 
  7. Asare, Asare (2021-11-10). "NAPTIP, Police, NIS personnel trained to curb migrant smuggling". Daily Post Nigeria. Retrieved 2022-03-30. 
  8. Report, Agency (2022-02-21). "NAPTIP, two others secure release of 15 Nigerian girls trafficked to Mali". Premium Times Nigeria. Retrieved 2022-03-30. 
  9. Online, Tribune (2019-07-31). "NACTAL calls for collaborative effort to tackle human trafficking". Tribune Online. Retrieved 2022-03-30. 
  10. Adetayo, Ayoola (2021-07-26). "Blue Bus Frontliners: NACTAL's pivotal partnership with government against human trafficking". Pulse Nigeria. Retrieved 2022-03-30.