Adámáwá-Ubangi I

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search

Èdè tí ó gbòòrò ni èdè Adamawa-Ubangi. Ipẹ̀ka rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti apá Gúsù-Ìwọ̀ oòrùn Nàìjíríà títí dé Àríwá-Ìwọ̀ oòrùn Sudan. Àpapọ̀ iye àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa tó mílíọ̀nù kan àti ààbọ̀-Crozier àti Blench (1992); Grimes (1996). Mílíọ̀nù méjì lé lẹ́gbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún ni Barreteau àti monino (1978) tọ́ka sí gẹ́gẹ́ bí àwọn tó ń sọ èdè Ubangi. Èyí túmọ̀ sí pé àpapọ̀ àwọn tí ó ń sọ èdè Adamawa-Ubangi ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ jẹ́ mílíọ̀nù mẹ́rindín ní ẹgbàá lọ́nà ọgọ́rùn-ún láì ka àwọ̣n tí ó ń sọ èdè Sango mọ́ ọ.

Nínú àtẹ yìí a rí ‘Proto-Adamawa-Ubangi’ tí ó pín sí ọ̀nà méjì ní ìbẹ̀rẹ̀ àpẹẹrẹ̀.

(a) Adamawa

(b) Ubangi

Adamawa - eléyìí tún pín sí àwọn àwọn ìsọ̀rí mìíràn bíi: Leko, Duru, Mumuye/Yendang ati Nimbari; Ubum, Bua, Kim, Day; Waja, Longuda, Jen, Bikwin, Yungur. Bákan náà ni a rí: Ba (Kwa), Kam, Fali.

Ubangi - Gbaya; Banda, Ngbandi, Sere, Ngbaka àti Mba; Zande.