Adébáyọ̀ Tìjání

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Adébáyọ̀ Tìjání (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹta ọdún 1975) jẹ́ gbajúgbajà olóòtú, olùdarí àti òṣèré sinimá àgbéléwò ọmọ bíbí agbolé alubàtá ní ìlú Ọ̀yọ́ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Ọdún 2002 Adébáyọ̀ Tìjání ti kọ, tí ó sìn ṣe olóòtú sinimá àgbéléwò rẹ̀ tí ó pe àkọ́lé rẹ̀ ní "Dúrósinmí".[1] Lẹ́yìn èyí, onírúurú sinimá àgbéléwò ló tún ti ṣe olóòtú rẹ̀, tí òun náà sìn kópa pàtàkì nínú wọn. Adébáyọ̀ Tìjání ni owó rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùdarí sinimá-àgbéléwò wọ́n jù láàárín àwọn sàwáwù rẹ̀.[2] [3]

Àtòjọ díẹ̀ nínú àwọn sinimá-àgbéléwò rẹ̀[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • Dúrósinmí - 2002
  • Kájọlá - 2003
  • Tí Ìgbín Bá Fà - 2004
  • Àpésìn - 2006
  • Àkàndù - 2007
  • Ipá - 2007
  • Ìránṣẹ́ Ajé - 2008
  • Tibi tire láyé - 2009
  • Àbẹ̀gbé - 2009
  • Ìgbẹ̀hìn Ewúro - 2009
  • Ògùn Àìkú - 2010

Àwọn Ìtọ́kasí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  1. "I can't marry an actress". Nigeria Films. 2016-03-24. Retrieved 2019-12-12. 
  2. "Adebayo Tijani Biography, Age, Movies & More". 360dopes. 2018-07-30. Retrieved 2019-12-12. 
  3. "Renowned Yoruba movie director, Adebayo Tijani is a year older today - Nigerian Entertainment Today". Nigerian Entertainment Today. 2016-03-24. Retrieved 2019-12-12. 

https://nigerianfinder.com/adebayo-tijani-biography-career-movies-more/