Jump to content

Adaba

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

ÀDÀBÀ

Àdàbà yí yọ lókè 80

Àdàbà yí yọ lókè

Àdàbà yí yọ lókè

Àdàbà yí yọ o

Sọ̀kalẹ̀ wá ò adaba


Bàbá lọ ò sókè 85

Edumarè wọlé ẹ ò

Bàbá mi délé ògo

Ojú ti júdasì dandan

Sìkàsìkà má sìkà mọ́


Ojú baba níkàn ẹ ló yẹ́ 90

Eléte lète ń yé

Ẹní deérú leérú ma tọ̀ dandan

Ará mi mo tọrọ gáfárà ná

Mo fẹ́ ki bàbá mì dada

Aṣiwájú Onígbàgbọ́ 95

Ìlá nilé babáà rẹ

Ọmọ ọ̀ràngún ọmọ ògóyè mi o

Déyẹmí

‘Caretaker’ tó pawó


Afínjú caretaker’ ni 100

Èrò tí ń lọ sílàá òràngún

Bẹ́ẹ dókè ìlá, ẹ bá mi yà kí baba

Bàbá Adéfolúṣọ́, ọkọ Àdùkẹ́ mi daada

Ọ̣̀kọ Táyélolú mì


Òkè ìlá nilé bàbáà rẹ 105

Ọmọ Oyètáyọ̀ Bámigbádé

‘Reverened’ tó pawó gidi ni

Adéyẹmí, ọmọ afínjú ọlọ́jà o

Wọn a rìn gbẹndẹ́kẹ


Wọ́n a rìn gbẹndẹ́kẹ 110

Ọmọ ọ̀bùn wọn a rìn ràdàràdà wọja

Ọ̀bùn ràdàràdà ní ó rẹrù afínjú wọlé

Adéyẹmi bàbá mi daada

Bá mi kí bàbá rẹ daada,


Nínú Olúwa 115

Bàbá mi John Àjàyí atọ́nà,

Afínjú onígbàgbọ́ ni

Àrànse olúwa pàtàkì,

Kó máa bá bàbá mi dada

Ìgò ńlá lorókè 120

Edumaré wọlé ò

Júdásì ojú tí ẹ o,

Olùgbàlà ti jíǹde

Ẹ bá mi kí bàbá mi William Adétọ̀nà

Àwọ̀n kan mí bẹ lókè 125

Wọ́n ń kọrin àléluyà

Lílé: E ké Hosánà

Ègbè: Lelú, lèlu

Lílé: Hosánà


Ègbè: Lelú, lèlu 130

Lílé: Lelú

Ègbè: Lelú, lèlu

Lílé: Lelúyà

Ègbè: Lelú, lèlu


Lílé: Sákà sakà mi 135

Lelúyà

Ègbè: Lelú, lèlu

Lílé: Lelúyà

Ègbè: Lelú, lèlu