Jump to content

Adegboyega Dosunmu Amororo II

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Adegboyega Dosunmu II
(CON)
Reign July 2005 – December 2021
Predecessor Oba Adisa Odeleye
Spouse Mrs. Adetoun Dosunmu (nee Sanni) widowed

Mrs. Olatunbosun Dosunmu, (nee Oyetayo)

House Palace of the Olowu of Owu Kingdom
Father Benjamin Okelana Dosunmu
Born Owu kingdom, Ogun State South-Western Nigeria
Died December 2021
Abeokuta, Ogun state

Adégbóyèga Dòsùnmú Amórorò II (CON) jẹ́ ọba ilẹ̀ Òwuìpínlẹ̀ ògùn, ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. À-pè-jálẹ̀ oyè rẹ̀ ni Olówùú ti ilẹ̀ Owú[1]. Ó gun orí oyè yìí nígbà tí Ọba Oláwálé Àdìsá Ọdẹ́lẹ́yẹ, Lágbedu wàjà ní oṣù kẹfà ọdún 2003 ní ẹni ọdún márùn-dín-láàádọ́rin[2].

Ọba Adégbóyèga Dòsùnmú jẹ́ ọmọ bíbí inú ọmọ ọba Benjamin Òkélànà Dòsùnmú (ọ̀kan lára àwọn ọmọ oyè ní ìran olóògbé Ọba Adésùńmbọ̀ Dòsùnmú, Amórorò Kínní) ẹni tí ó jọba láàárín ọdún 1918 àti 1924) ní ilẹ̀ Owú. Benjamin Òkélànà Dòsùnmú yìí ni ọmọ kẹta tí Ọba Adésùńmbọ̀ Dòsùnmú, Amórorò bí.

Ó bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ ìwé rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ti Ìjọ Onítẹ̀bọmi ní Òwu (Owu Baptist Day School), Abẹ́òkúta ní ọdún 1941. Lẹ́yìn èyí, ó lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ girama ti àwọn Baptist Boys’ High School, níbẹ̀ ni ó sì ti gba ìwé ẹ̀rí oníwèé mẹ́wàá ní ọdún 1950. Ó tẹ̀síwájú nínú ìwé kíkà rẹ̀ nígbà tí ó lọ sí ìlú òyìnbó láti lọ gba ìmọ̀ lórí eré orí-ìtàgé àti bí a tí ń ṣe ètò orí ẹ̀rọ-amóhùn-máwòrán Drama and Television Production ní ilé ẹ̀kọ́ ìmọ̀ ẹ̀rọ (Hendon College of Technology) ní ìlú Ọba (London) ní ọdún 1963. Lẹ́yìn èyí, ó tún tẹ̀síwájú láti lọ sí ìlú Amẹ́ríkà láti lọ kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀sìn ìgbàlódé ní ilé-ẹ̀kọ́ Ìjọ Onítẹ̀bọmi tí ó wà ní ìlú Tennessee (Landmark Baptist College Tennessee, USA) níbẹ̀ ni ó ti gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sáyẹ́ńsì ní ọdún 1987.

Àwọn ìtọ́kasí

[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
  1. https://www.vanguardngr.com/2012/10/odun-omo-olowu-yam-festival-in-another-style/
  2. https://www.vanguardngr.com/2013/10/odun-omo-olowu-celebrating-culture-best/