Ìpínlẹ̀ Ògùn
Ìpínlẹ̀ Ògùn | |||
---|---|---|---|
Àwòrán agbègbè mọ́ṣáláṣí kan ní Gbagura ní ìlú Abẹ́òkuta, ní ìpínlè Ògùn | |||
| |||
Nickname(s): | |||
Location of Ogun State in Nigeria | |||
Coordinates: 7°00′N 3°35′E / 7.000°N 3.583°ECoordinates: 7°00′N 3°35′E / 7.000°N 3.583°E | |||
Country | Nigeria | ||
Date created | 3 February 1976 | ||
Capital | Abeokuta | ||
Government | |||
• Body | Government of Ogun State | ||
• Governor | Dapo Abiodun (APC) | ||
• Deputy Governor | Noimot Salako-Oyedele (APC) | ||
• Legislature | Ogun State House of Assembly | ||
• Senators | C: Ibikunle Amosun (APC) E: Ramoni Olalekan Mustapha (APC) W: Tolu Odebiyi (APC) | ||
• Representatives | List | ||
Area | |||
• Total | 16,980.55 km2 (6,556.23 sq mi) | ||
Area rank | 24th of 36 | ||
Population (2006 census) | |||
• Total | 3,751,140 | ||
• Rank | 16 of 36 | ||
• Density | 220/km2 (570/sq mi) | ||
Demonym(s) | Ogun | ||
GDP | |||
• Year | 2007 | ||
• Total | $10.47 billion[1] | ||
• Per capita | $2,740[1] | ||
Time zone | UTC+01 (WAT) | ||
postal code | 110001 | ||
ISO 3166 code | NG-OG | ||
HDI (2018) | 0.662[2] medium · 2nd of 37 |
Ìpínlẹ̀ Ògùn jẹ ọ̀kan lára àwọn Ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tí ó wà ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Wọ́n da Ìpínlẹ̀ Ògùn sílẹ̀ ní ọjọ́ kẹtàlá oṣù kejì, ọdún 1976. Ìpínlẹ̀ Ògùn fi ẹ̀gbẹ́ kan ẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú Ìpínlẹ̀ Èkó lápá Gúúsù, Ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àti Ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun lápá Àríwá, Ìpínlẹ̀ Òndó àti Orílẹ̀-èdè Olómìnira ilẹ̀ Benin lápá Ìwọ̀-Oòrùn. Gómìnà ìpínlẹ̀ náà lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ni Ọmọọba Dapo Abiodun tí wọ́n dìbò yàn-án wọlé lọ́dún 2019. Abẹ́òkúta ni olú-ìlú Ìpínlẹ̀ Ògùn àti ìlú tí ó ní ọ̀pọ̀ olùgbé jùlọ ni ìpínlẹ̀ náà. Méjì lára àwọn ìlú mìíràn tí ó ṣe pàtàkì ni Ìpínlẹ̀ Ògùn ni Ìjẹ̀bú-Òde, olú-ìlú ọba aládé tí Ìjẹ̀bú Kingdom fún ìgbà kàn rí àti Sagamu, ìlú tí ń ṣe aṣáájú níbi ká gbin obì lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ado-Odo/Ota jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn tó ń ṣe agbátẹrù ètò ọrọ̀ ajé tó múnádóko.
Àwọn ìjọba ìbílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ògùn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìjọba ìbílẹ̀ ogún ló wà ní ìpínlẹ̀ Ògùn, àwọn sì ni:
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá Abẹ́òkúta/Akọmọjẹ
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Gúúsù Abẹ́òkúta/Ake
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ado-Odo/Ota
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ewekoro Itori
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ifo
- Ijebu East Ọ̀gbẹ̀rẹ̀
- Ijebu North/Ijebu-Igbo
- Ijebu North East Atan
- Ijebu-Ode
- Ikenne
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Imeko-Afon
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ipokia
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Obafemi-Owode/Owódé Ẹ̀gbá
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Odogbolu
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Odeda
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Ogun Waterside
- Remo North
- Sagamu
- Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Àríwá Yewa
- Agbegbe Ijoba Ibile Guusu Yewa/Ilaro
Àwọn ohun àmúyẹ ní ìpínlẹ̀ náà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ilé-ẹ̀kọ́
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ilé-ìwé ìjọba àpapọ̀ mẹ́ta, àwọn ni; Federal Government Girls' College, Sagamu [3] àti Federal Government College, Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Odogbolu[4] àti Federal Science and Technical College, Ijebu-Imushin.[5]
Ìpínlẹ̀ náà ní Yunifásitì ìjọba àpapọ̀ kan, tí ń ṣe; Federal University of Agriculture, Abeokuta (FUNAAB[6]) àti college of education tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀ kan, tí ń ṣe FCE Osiele (méjèèjì wà ní Agbègbè Ìjọba Ìbílẹ̀ Odeda), college of education kan, tó jẹ́ ti ìjọba ìpínlẹ̀ náà, tí wọ́n fi sọrí ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ti ṣaláìsì báyìí, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Augustus Taiwo Solarin tí wọ́n dá kalè ní ọdún 1994, tí wọ́n pè ní Tai Solarin University of Education#(TASCE[7]. Ó tún ní Polytechnic kan ní Ilaro, tó jẹ́ ti ìjọba àpapọ̀, tí wọ́n fi sọrí oníṣòwò ilẹ̀ Nàìjíríà àti olúborí ìdíje òṣèlú ti June 12, 1993, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Basorun Moshood Kasimawo Olawale Abiola, tí wọ́n pè ní Moshood Abiola Polytechnic (MAPOLY[8]), tí ó fìgbà kan jẹ́ Ogun State Polytechnic, Ojere, Abeokuta. Àwọn mìíràn ni Another Gateway Polytechnic Saapade,[9] Remo (GAPOSA), Abraham Adesanya Polytechnic[9] Ijebu-Igbo (Aapoly) (tí ó fìgbà kan jẹ́ 'The Polytechnic Ijebu-Igbo) tí wọ́n fi sọrí Chief Abraham Aderibigbe Adesanya, tó jẹ́ olóṣèlú ilẹ̀ Nàìjíríà, agbẹjọ́rò àti ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn. Yunifásitì ti ìjọba méjì tó ń ṣe: Olabisi Onabanjo University, Ago Iwoye (tí ó fígbà kan jẹ́ Ogun State University), àti Tai Solarin University of Education (TASUED[10]) Ijebu Ode.
Ìpínlẹ̀ Ògùn ní Yunifásitì mẹ́sàn-án lápaapọ̀ tó ti wà ní ìforúkọsílẹ̀, tó sì pọ̀ jù lọ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà. Lára wọn ni Yunifásitì aládàáni márùn-ún:[11] Chrisland University, Abeokuta Bells University of Technology ní Ota, Covenant University àti Babcock University ní Ilisan-Remo, tó jẹ́ Yunifásitì aládàáni àkọ́kọ́ ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Àtòjọ àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga ní ìpínlẹ̀ náà
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Babcock University, Ilisan Remo
- Bells University of Technology, Ota
- Chrisland University, Abeokuta [12]
- Christopher University, Lagos Ibadan ExpresWay Makun, Sagamu
- Covenant University, Ota [13]
- Crawford University, Igbesa
- Crescent University, Abeokuta
- Federal Polytechnic, Ilaro
- Federal University of Agriculture, Abeokuta
- Hallmark University, Ijebu Itele
- McPherson University, Seriki-Sotayo [14]
- Moshood Abiola Polytechnic, Ojere
- Mountain Top University, Lagos-Ibadan Expressway
- National Open University of Nigeria, Kobape, Abeokuta
- Ogun State College of Health Technology, Ilese, Ijebu Ode
- Olabisi Onabanjo University, Ago Iwoye
- Tai Solarin University of Education, Ijagun, Ijebu-Ode
Ilé-ìwòsàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìpínlẹ̀ náà ní ilé-ìwòsàn tó jẹ́ ti ìjọba méjì, tí ń ṣe: Federal Medical Center ní ìlú Abeokuta, àti Olabisi Onabanjo University Teaching Hospital ní Sagamu.
Àwọn ilé-ìjọsìn tó gbajúmọ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Bilikisu Sungbo Shrine, ní Oke-Eiri, lágbègbè Ijebu-Ode. Ibí yìí ní àwọn Ijebu gbàgbọ́ pé wọ́n sin [15] Queen of Sheba tí wọ́n tún máa ń pè ní Bilikisu alága Wúrà. Ó jẹ́ ibi ọ̀wọ̀ àti ààyè tí àwọn oníṣẹ̀ṣe yà sọ́tọ̀. Àwọn Mùsùlùmí àti Kìrìsìtẹ́ẹ́nì ló máa ń lọ ibẹ̀.
- Church of the Lord (Aladura), Ogere Remo
- Redemption Camp (Lagos Ibadan Express Road)
- Living Faith Church Worldwide, (Canaanland, Km. 10, Idiroko Road, Ota, Ogun State, Nigeria)
Gbàgede NYSC
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Gbàdede National Youth Service Corps (NYSC) wà ní agbègbè ìjọba ìbílẹ̀ Sagamu, ní ìpínlẹ̀ náà.
Àwọn ènìyàn tó ti jáde ní ìpínlẹ̀ Ògùn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Ìpínlẹ̀ Ògún jẹ́ dídílẹ̀ láti ọwọ́ ìjọba Murtala/Ọbásanjọ́ ní ọjọ́ kẹ́ta oṣù kejì, ọdún 1976 látara níhàa Ìwọ̀-Oòrùn àtijọ́. Wọ́n sọ ìpínlẹ̀ náà lẹ́yìn odò Ògùn, tí odò náà ṣàn káàkiri ìpínlẹ̀ náà láti Àríwá lọ sí Gúúsù. Ìpínlẹ̀ náà ní àyíká ìgbìmọ̀ ìjọba agbègbè ogún lọ́wọ́lọ́wọ́. Ìpínlẹ̀ Ògùn ní ọwọ́ ajẹmọ́-ìran mẹ́fà tó tóbi, àwọn náà ni: Ẹ̀gbá, Ìjẹ̀bú, Rẹ́mo, Ẹgbádọ̀, Àwọrí àti Ègùn. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn kékeré mìíràn wà bí Ìkálẹ̀, Kẹ́tu, Ohori àti Anago.[16] Ìwé- ìpamọ́ jẹ́ẹ̀rí pé ìpínlẹ̀ yìí ló ní Fáṣítì Àdáni àti ilé-ìwé gíga ní Nàìjíríà àti ìpínlẹ̀ tó ní Fáṣítì ìpínlẹ̀ ara rẹ̀ méjì ni Nàìjíríà. Ìpínlẹ̀ Ògùn tún jẹ́ ilé fún Fáṣítì fún Ẹ̀kọ́ àkọ́kọ́ àti ìgbẹ̀yìn.[17] [18]
Ìpínlẹ̀ Ògùn tí pèsè ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn olórí ìjọba ní Gúúsù-Ìwọ̀ Oòrùn. Gbogbo àwọn ara Gúúsù Ìwọ̀-Oòrùn tó ti jẹ Ààrẹ tàbí olórí ìpínlẹ̀ fún ìlú wá láti ìpínlẹ̀ Ògùn (Ọbásanjọ́, Shónẹ́kàn) wọ́n gba oríyìn láti ìpínlẹ̀ Ògùn. Olóyè Jeremiah Ọbáfẹ́mi Àwọ́lọ́wọ̀, Olórí àkọ́kọ́ fún Agbègbè Ìwọ̀-oòrùn, ó dẹ̀ jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ Ògùn. Àwọn ará Ìjẹ̀bú ní ìpínlè yìí ni àwọn Yóò á àkọ́kọ́ tó nínú ìbásepọ̀ pẹ̀lú àwọn ará Europe ní ṣẹ́ńtíúrì kẹrìnlá. Àwọn ènìyàn náà tún gbà wí pé àwọn ni ẹ̀yà Yoòbá tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí ní ma lọ owó tí a mọ̀ sí owó-Ẹyọ, tí ó jẹ́ àtawọ́gbà ní gbogbo ilẹ̀ Yorùbá kí wọ́n tí rọ́pò rẹ̀ pẹ̀lú kọ́ìsì nígbà tí àwọn Europe dẹ́.[19]
Àtòjọ àwọn ènìyàn tó lààmìlaaka tó jẹ́ ọmọ ìpínlẹ̀ yìí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- Abraham Adesanya (1922–2008), olóṣèlú
- Adebayo Adedeji (1930–2018), onímọ̀ nípa ọ̀rọ̀-ajé
- Adebayo Ogunlesi (b. 1953), agbẹjọ́rò, òṣìṣẹ́ ilé-ìfowópamọ́
- Adegboyega Dosunmu Amororo II, aṣagbátẹrù fíìmù, Olowu ti Owu
- Adewale Oke Adekola
- Afolabi Olabimtan
- Anthony Joshua
- Babafemi Ogundipe
- Babatunde Osotimehin
- Bisi Onasanya
- Bola Ajibola
- Bola Kuforiji Olubi
- Bosun Tijani (b. 1977), oníṣòwò
- Olu Oyesanya
- Cornelius Taiwo
- Dapo Abiodun
- David Alaba, ọmọ George Alaba, ọmọọba Ogere Remo
- Dimeji Bankole
- Ebenezer Obey, olórin juju
- Ernest Shonekan
- Fela Kuti (1938–1997), olórin, Pan-Africanist
- Fireboy DML, olórin
- Femi Okurounmu, olóṣèlú
- Fola Adeola, oníṣòwò, olóṣèlú
- Funmilayo Ransome-Kuti (1900–1978), onímọ̀, ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmmọbìnrin
- Funke Akindele (b. 1977), òṣerébìnrin
- Gbenga Daniel (b. 1956), olóṣèlú
- Hannah Idowu Dideolu Awolowo (1915–2015), oníṣòwò àti olóṣèlú
- Hubert Ogunde (1916–1990), òṣerékùnrin, adarí eré-ìtàgé àti olórin
- Ibikunle Amosun (b. 1958), olóṣèlú, sẹ́nátọ̀, gómínà ìpínlẹ̀ Ògùn láti ọdún 2011–2019
- Idowu Sofola (1934–1982)
- Joseph Adenuga (b. 1982),
- Jubril Martins-Kuye (b. 1942), olóṣèlú
- K1 De Ultimate (b. 1957), olórin fújì
- Kehinde Sofola (1924–2007), amọ̀fin
- Kemi Adeosun (b. 1967),
- Laycon (b. 1993), olórin
- Mike Adenuga
- Moshood Abiola
- Oba Otudeko (b. 1943), oníṣòwò
- Obafemi Awolowo (1909–1987)
- Ola Rotimi
- Olabisi Onabanjo
- Oladipo Diya
- Olamide
- Olawunmi Banjo
- Olusegun Obasanjo
- Olusegun Osoba
- Paul Adefarasin
- Peter Akinola
- Salawa Abeni
- Sara Forbes Bonetta
- Tai Solarin (1922–1994), onímọ̀, ajàfẹ́tọ̀ọ́-ọmọnìyàn
- Thomas Adeoye Lambo (1923–2004), ọ̀jọ̀gbọ́n
- Tunde Bakare (b. 1954), Pásítọ̀ àti olóṣèlú
- Tunji Olurin (b. 1944)
- Wole Soyinka (b. 1934), 1986 Òǹkọ̀wé
- Yemi Osinbajo (b. 1957), olóṣèlú, agbẹjọ́rọ̀
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ 1.0 1.1 "C-GIDD (Canback Global Income Distribution Database)". Canback Dangel. Retrieved 2008-08-20.
- ↑ "Sub-national HDI - Area Database - Global Data Lab". hdi.globaldatalab.org (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Retrieved 2018-09-13.
- ↑ "Federal Government Girls College, Sagamu | School Website". www.fggcsagamu.org.ng. Archived from the original on 2020-08-05. Retrieved 2020-05-24.
- ↑ "Federal Government College, Odogbolu | School Website". fgcodogbolu.com.ng. Archived from the original on 2020-06-30. Retrieved 2020-05-24.
- ↑ "Federal Science And Technical College, Ijebu Imushin | School Website". fstcijebuimusin.com. Archived from the original on 2020-08-05. Retrieved 2020-05-24.
- ↑ "Federal University of Agriculture, Abeokuta, teaching, learning, research". Archived from the original on August 5, 2020. Retrieved Aug 6, 2020.
- ↑ ":::TASCE". tasce.edu.ng. Retrieved Aug 6, 2020.
- ↑ "Moshood Abiola Polytechnic". Archived from the original on August 6, 2020. Retrieved Aug 6, 2020.
- ↑ 9.0 9.1 "List of NBTE approved State government owned Polytechnics in Nigeria". NBTE portal. Archived from the original on 2023-03-20. Retrieved 2023-03-20.
- ↑ "Tai Solarin University of Education | The Premier University of Education". tasued.edu.ng. Retrieved Aug 6, 2020.
- ↑ "Ogun State". Ogun Smart City (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). Archived from the original on 2022-01-19. Retrieved 2022-02-25.
- ↑ "Home - Chrisland University". www.chrislandtuniversity.edu.ng. Archived from the original on 2022-08-02. Retrieved 2023-03-20.
- ↑ "Home - Covenant University". www.covenantuniversity.edu.ng.
- ↑ "McPherson University". Jul 15, 2014. Archived from the original on 2014-07-15. Retrieved Aug 6, 2020.
- ↑ Sungbo Eredo and Its Ecotourism Values: Sonubi O K (2009)
- ↑ "6 Important Facts about Ogun State You Probably Didn't Know". Vanguard News (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2017-07-27. Retrieved 2021-12-06.
- ↑ "List of Tribes & Local Government in Ogun State Nigeria.". School Drillers. 2021-02-22. Retrieved 2022-04-20.
- ↑ "Brief History of Ogun State:: Nigeria Information & Guide". Nigeriagalleria. 1976-02-03. Retrieved 2022-04-20.
- ↑ "6 Important Facts about Ogun State You Probably Didn’t Know". Vanguard News. 2017-07-27. Retrieved 2022-04-20.
Coordinates: 7°00′N 3°35′E / 7.000°N 3.583°E{{#coordinates:}}: cannot have more than one primary tag per page