Dapo Abiodun

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Jump to navigation Jump to search
Dapo Abiodun
Dapo Abiodun.jpg
Gomina Ipinle Ogun
Lọ́wọ́lọ́wọ́
Ó gun orí àga
29 May 2019
Asíwájú Ibikunle Amosun
Personal details
Ọjọ́ìbí 29 Oṣù Kàrún 1960 (1960-05-29) (ọmọ ọdún 59)
Iperu Remo, Ogun State, Nigeria
Ẹgbẹ́ olóṣèlu All Progressives Congress (APC)

Dapo Abiodun (Ojo ibi, 29 May 1960) je onisowo ati oloselu omo ile Naijiria, eni ti o je Gomina Ipinle Ogun nigbati O bori idibo ti Gomina ni odun 2019 labe asiya egbe-oselu (All progressive Congress). Dapo Abiodun ni olori igbimo ti Corporate Affairs Commission. O tun je alakooso ati oludari ti Heyden Petroleum ati oludasile First Power Limited. Ni ojo kewa Osu keta odun 2019 (10 March 2019), igbinmo ti o n dari idibo ni ile Naijiria Independent National Electoral Commission kede Dapo Abiodun gege bi Gomina ti a dibo yan ni Ipinle Ogun. Won se ibura fun un gege bi Gomina Ipinle Ogun in ojo konkandinlogbon, osu karun, odun 2019 (29 may 2019)

Igba Ewe[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Dapo Abiodun wa lati Iperu Remo ni Ipinle Ogun. O wa lati idile Oba. A bi sinu ebi dokita Emmanuel ati Arabinrin Victoria Abiodun ti won wa lati Iperu Remo ni ila-orun Ipinle ogun ni ojo kokandinlogbon osu karun odun 1960 (29 May 1960).

eko[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Dapo Abiodun ko eko nipa imo ero ni ile eko giga yunifasiti Obafemi Awolowo ti o wa ni ile ife ni Ipinle Osun. O tun keko nipa isiro ni ile eko giga yunifasiti Ipinle ti Kennesaw ni ilu America. O tun gba oye iyi ninu isuna lati ile eko giga yunifasiti Ipinle ti Ekiti eyi ti o wa ni Ado-Ekiti. O si tun gba oye miran ninu isakoso owo lati ile eko giga yunifasiti Adeleke ti o wa ni Ede ni Ipinle Osun. O lowo ninu oro iwe eri ti ko peregede nigba igbara di fun idibo ti odun 2019, nigba ti o je wipe o ti koko so nigba idibo ti alagba fun apa ila-orun Ogun ti o waye ni odun 2015 pe o un keko jade ni ile eko giga yunifasiti Obafemi Awolowo sugbon ninu foomu fun idibo gomina ti odun 2019, O so wipe iwe eri oniwe mewa ni o un ni.Itokasi[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]