Ìjẹ̀bú-Òde

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Ìjẹ̀bú-Òde
Ìjẹ̀bú-Òde is located in Nigeria
Ìjẹ̀bú-Òde
Ibudo ni Naijiria
Àwọn ajọfọ̀nàkò: 6°49′0″N 3°56′-1″E / 6.816667°N 3.93306°E / 6.816667; 3.93306 longs<0 (dms format) in {{Coord}}
Country Flag of Nigeria.svg Nigeria
Ipinle Ipinle Ogun
Olùgbé
 - Iye àpapọ̀ 222,653

Ijebu-Ode je ilu ni Naijiria ni Ipinle Ogun.

ITAN IJEBU-ODE[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orísìírísìí ni ìtàn tí à ń gbó nípa ìsèdá ìjèbú Òde. Sùgbón èyí tí ó wó pò jù nínú àwon ìtàn náà ni mo ménu bà yìí;

Aládùígbò ni Odùduwà àti Alárè jé ni apá ilè Lárúbáwá. Odùduwà ni a gbó pé ó kókó sí kúrò ní agbègbè náà wá sí Ilé-Ifẹ̀. Léhìn rè ni Alárè kúrò ní ilè Wàdáì; tí ó gba asálè Núbíà dé Ilé-Ifè, tí ó sì se “e-nlé-ń bèun o” fún Odùdùwà. Alárè fi omobìnrin rè kan Gbórowó, fún Odùduwà láti fi se aya. Léhìn èyí, ó gba ònà Ìseri dé Ìbesè, títí ó fi dúró ní Ìjèbú-Òde. Ajèbú àti Olóde jé lára àwon àtèlé Alárè. Fún isé ribiribi won fún ìlú ni a se so Ibùdó náà lórúko won - Ajèbú-Olóde. Àpèjá orúko yìí ni ó di Ìjèbú-Òde lónìí yìí.

Léhìn Alárè ni Lúwà (OLÙ-ÌWÀ) náà dé láti asálè Núbíà. Òun náà gba ònà Ilé-Ifè, ó sì yà kí Odùduwà. Lúwà àti Àlárè bí omokùnrin kòòkan. Osi ni omo Lúwà; Eginrin sì ni omo Alárè. Ní àsìkò yìí. Osìn tàbí Olójà ni à ń pe Olórí Ìjèbú-Òde.

Èdè àìyédè bé sílè láàárín Alárè àti Lúwà lórí, i eni tí yóò je olójà. Nígbà tí wón to Ìfá lo lórí òrò yìí, ó fí yé won pé eni tí yóò je olórí kòì tíì dè!.

Kò pé kò jìnnà, léhìn ikú Alárè àti Lúwà, ni àjèjì kan tí o múrá pàpà-rere wòlú. Ònà Ondó ni àjèji yíí gbà wo ìlú. Kò pé, ìròhìn ti tàn ká pé àjìji kán fé gbógun wòlú. Èyí ni ó mú Apèbí (Olóyè pàtàkì kan ní ibùdó yìí) lo báa bóyá ijà ni ó bá wá ní tòótó. Àjèjì yìí kò fèsì lo báa bóyá ijà ni ó bá wá ní tòótó. Àjèjì yìí kò fèsì ju pé “Ìjà dà?. láti fi hàn pé òun kò bá ogun wá. Àjèjì náà fi yé wón pé Ògbòrògánńdá-Ajogun ni orúko òun. Ó jé omo Gbórówó tí í se omobìnrin Alárè tí ó fún Odùduwà fé ní Ilé-Ifè, Ipasè àwon ebí ìyáa rè ni Ògbòrògánńdà tò wá, léhìn ikú bàbá rè. Títí di òní, àdúgbò tí Apèbí tí pàdé Ògbòrògánńdà ni à ń pè ní ÌJÀDÀ.

Àpàbí lo fi tó olóyè àgbà Jaginrìn tí ó rán an nísé pé owó èrò ni àjèjì náà mú wá. Nígbà tí Jaginrìn bi Apèbí ibi tí àjèjì náà wà, Apèbí dáhùn pé “Oba-ńníta” (Oba wà ní ìta) nítorí ipò Óba ni ó rí i pé ó ye eni pàtàkì bí i tí Ògbòrògbánnńdà-Ajogun. Láti ìgbà yìí ni a tí mo Ògbòrògánńdà ní Obańníta, tí àjápè rè di Obańta di òní. Agbègbè tí Oníseémù ti lé òsà lo tí a fún Ògbòrògánńdà láti máa gbé ni ó júwe pé” ó tóó ró”- (Ibí yìí) tó láti dúró sí) ni à ń pè ní Ìtóòró di òní. Àdúgbò yìí ni a se òwón kan sí ní ìrántí Obańta, nítorí a kò mo bí ó se kú. Inú igbó kan ni tòsí Orù-Àwà ni a gbó pé ó rá sí.

Ògbórògbánńdá Ajogun (Obańta) gbé Winniadé, omo Osi níyàwó. Ósi yìí, bí a ti mò sáájú jé omo Lúwà. Obáńta sì jé omo-omo Alárè. Wón bí omokùnrin kan tí ó ń je Monigbùwà. Síbè aáwó tí ó wà láàárín Lúwà àti Alárè nípa óyè jíje kò í tán láàárín àwón ebí méjèèjì.

Láti fi òpin sí aáwò yìí, àwon ará ìlú ní kí Monigbùwà, omo Obańta, jáde rè ti se ní ojó kìíní. ‘Monigbùwà gbà láti se béè. Ó lo sí ìletò kan tí a mò sí Òdo, láti ibè ní ó sì ti padà wo ìlú pèlú ìfon àti orin. Ojó yìí ni a gbé adé fún Monígbùwà. Oùn ni ó jé eni àkókó ti ó je oyè Awùjalè - ‘A-mu-ìjà-ilè’-èyí ni eni tí ó parí ìjá tí ó bá nílè. Àpápè oyè yìí ni ó di Awùjalè dòní yìí. Títí di òní yìí ni enikéni tí a bá yàn gégé bí oba tuntun gbódò jáde ní ìlú lo sí Òdo, kí ó sì wo ìlú padà gégé bí i Monigbùwà àti Obańta kí ó tó ó gbadé.

Lára àwon olóyè pàtàkì-pàtàkì ní Ìjèbú-Òde ni Olísà Egbò, Àgbòn, Kakanfò, Jaginrìn àti Lápòekùn, tí wón jé óyè ìdílé. Àwon oyè bí i Ògbéni Ojà kìí se oyè ìdílé. Àwùjalè kokànléláàádóta ni a gbó pé ó wà lórí oyè báyìí.

Àwon Ìjèbú féràn láti máa je kókò àti òjòjò. Wón tún féràn lati máa fi ògìrì sí obè àti oúnje won mìíràn bíi ikókoré láti fún un ní adùn àjepónmulá.

ÈSIN[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Elésìn ìbílè ni àwon ènìyàn Ijèbú Òde ní ìgbà láíláí. Wón máa ń bo orísìírisìí òrìsà tí a ń bo ní gbogbo ilè Yorùbá bí i Ògún, Ifá, Èsù àti béè béè lo. Àwon òrìsà ìbílè bíi Agemo, Òrò, àti Obìnrin-Òjòwú wà pèlú. Lóde oní àwon èsìn ìbílè wònyí kò ranlè bíi ti àtijó, síbè a sì ń bo wón lójú méjèèjì. Èsìn Mùsùlùnì ni òpò àwon ará Ìjèbú-Òde ń se báyìí. Mosálásí kan wà ní àdúgbò Òyìngbò tí ó jé òkan nínú mósálásí tí ó tóbi jù ni apá ìwó oòrùn Afríka.

Àwon elésìn àtèlé Krístì Lórísìírísìí kò gbéhìn. Àwon náà pò ní iba tiwon. Àwon ìjo Àgùdà tilè fi Ìjèbú Òde se ibùjúkóó fún dáyósíìsì ti ekùn Ìjèbú.

ADUGBO[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

1. Àdúgbò: Itaolówájodá Ìtùmò: Àdúgbò yìí ni àwon ìjòyè Oba ìlú yìí tí a ń pè ni olówá tè dí, ti won si ń se ìjoba lórí àwon ènìyàn tó wà ládùgbó yìí

2. Àdúgbò: Olíwòro Ìtùmò: Àdúgbò yìí ni ojúbo òrìsà alá wà tétètélè, Àwon àwòrò òrìsà yìí ni ó te àdúgbò yìí dó.

3. Àdúgbò: Ìdóbì Ìtùmò: Igi obì púpò ni àwon tó te àdúgbò yìí bá nígbà ti wón fé te ìbè dó.

4. Àdúgbò: Ìtaòsù Ìtùmò: Àdúgbò yìí ni ojúbo òrìsà òsù wa. ni tori pe ibí yìí ni wón ti ń bo òrìsà yìí ni wón se ń pe e ni ìta òsù.

5. Àdúgbò: Imèpè Ìtùmò: Igi òpe púpò ni àwon tó te àdúgbò yìí ban i ibi yìí nígbà tí wón fé te ibè dó

6. Àdúgbò: Ayegun Ìtùmò: Àdúgbò yìí ni òkan lára àwon akoni ode to máa ń ye ojó ogun ti awon olóde yòókù bá ti dá síwájú tè dó ìdí niyìí tí won fi ń pe àdúgbò yìí ni Ayegun.

7. Àdúgbò: Ìtalápò Ìtùmò: Awon ounje orisirisi tí a dì sínú àpò bii àgbàdo, ìyo, ni àwon ara àgbègbè máà ń gbé wá si àdúgbò yìí wá lati tà kí ó tó di àdúgbò. Wón si máà ń na ojà ni àdúgbò yìí títí di òní yìí .

8. Àdúgbò: Ìsasà Ìtùmò: Isé ìkokò mímo ni isé àwon to té àdúgbò yìí dó. Díè lára àwon omo omo won si ń se ìsé yìí

9. Àdúgbò: Ìta Òsùgbó Ìtùmò: Àdúgbò yìí ni àwon Olósùgbó ti máà ń se ìpàdé. Níbè ni ilé ìpàdé wón wa, kí ó tó di pé won te ibè dó.

10. Àdúgbò: Ìsesí Ìtùmò: Ibí yìí ni ójúbo osi esi wà télètélè kí o to di pé won te ibè do tí o si dí àdúgbò ojúbo osi yìí si wa níbè títí dònìí.

11. Àdúgbò: Ìta Opó Ìtùmò: Àwon Opó ni won máà ń na ojà yìí ni alaalé. Òríta ti wón ń náà yìí ni o di adúgbò, ti wón si ń pe ni ìtà opó. Wón si máà ń ná ojà alé ni àdúgbò yìí títí dònìí

12. Àdúgbò: Molípáà Ìtùmò: Okunrin kan tó mú opà dání ló te apá ibí yìí dó. Ìtàn so fún wa pé àpá ase Oba ìlú ibòmíìràn ló mu dàni nígbà tí o ń bo, àwon kan tilè so pé Àremo oba ìlú náà ni. Nígbà tí o, fé te àdúgbò náà do ó mú òpá yìí dá ni, Ìdí niyìí tó fi je pé won ń je oba ni àdúgbò náà títí di òní yìí

13. Àdúgbò: Ìtóòrò Ìtùmò: Ìtàn so fún wa pé omi nigbogbo àdúgbò yìí teletélè kí ó to dí pe wón te ibè do. Okunrin akoni ti a ń pè ni òró ni o pé ofò tí ó sì le omi náà lo. Ìdí nìyìí ti a fi ń pé àdúgbò náà ni Ìtóòró.

14. Àdúgbò: Olóde Ìtùmò: Ibí yìí ni òkan lára àwon akoni tó te ìlú yii dó kokó dúró si kó tó dip é ó wo àárin ìlú lo. Nígbà ti ijà dé láàrin òun àti àwon tí wón fo wo ìlú yìí, o bínú pàdà si ibi yìí o si wolè. Ìdí niyìí tí wón fi ń pe àdúgbò naa ni Olóde. Oórì okùnrin yìí si wà níbè títí dòníì.

15. Àdúgbò: Odò Èsà Ìtùmò: Eégún kan ti won ń pè ni obrinrin ojòwú ní o te ibí yìí dó. Èégún Odoodún ni eégún máà ń jáde ni àdúgbò yìí títí donii. Ìdí igi ìrókò ni won fi se ojúbo eégún yìí Igi ìrókò yii wà níbè títí dónì yìí.

16. Àdúgbò: Ìdépo Ìtùmò: Isé epo ni àwon to te àdúgbò yìí yàn láàyò léyìn tí wón ti dó síbè. Bí o tilè jé pé won kò se ise epó níbè mó, won si ń ná ojà epo níbè titi dò níí.

17. Àdúgbò: Fìdípòtè Ìtùmò: Lára àwon ìjòyè oba Gbélébùwà àkókó tí won kò fara mo on pé kí wón pa Oba náà ni won wa te àdúgbò yìí dó léyìn ti wón kúrò ni ààfún.

18. Àdúgbò: Apèbi Ìtùmò: Oríta yìí ni àwon ìjoyè Oba Gbétebùwá àkókó péjo sí láti bi ara won ohun ti o ye kí àwon se fún oba náà.

19. Àdúgbò: Ìdéwòn Ìtùmò: Ìtàn so gún wa pé nígbà tí wín fe te ibí yìí dó, wón bá òrìsà kan níbè tó dé adé sórí tó sì fi èwòn onírin se ileke owó àti tí esè. Ìdí ni yìí ti à fi máà ń yan Oba láti ìdílé enití ó te àdúgbò náà dó. Ìdílè yìí náà tílè ni ààfún tí a ń pè ni ààfin Òba ìdéwon.

20. Àdúgbò: Ìta Àfín Ìtùmò: Ìtàn so fún wa pé bí ó tilè jé pé èrúktí o té àdúgbò yìí do kii se àfín, sùgbón gbogbo àwon omo tí won bi láti ìdílè enití o te àdúgbò náà do je àfín. Nígbà ti won lo bi ifá wo, Ifá ni ki won máà bo Obàtálá ni ìdílé náà, láti ìgbà náà lo ni won ti ń bo Obàtálá ni ìdílè yìí. Ti o bad i àsìkò odún òrìsà yìí, àríyá ni fún gbogbo àwon omo àdúgbò yìí àti fún ìlú pàápàá.

Itoka[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • C.O. Onanuga (1981), ‘Ìlú Ìjèbú-Òde’, láti inú ‘Odún Òrìsà Agemo ní Agbègbè Ìjèbú-Òde.’, Àpilèko fún Oyè Bíeè, DALL. OAU, Ifè, Nigeria, ojú-ìwé 3-6