Jump to content

Sikiru Kayode Adetona

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́

Ọba Sikiru Kayode Adetona (Tí a bí ní ọjọ́ kẹwa oṣù karun ọdún 1934) ni Awujale ti Ìjẹ̀bú. Wọ́n fi jẹ ọba ní ọdún 1960, èyí ló mú kí Adetona jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọba tí o tí pẹ́ lórí àléfà ní ilẹ̀ Naijiria. Baba rẹ ni ọmọ ọba Rufai Adetona tí Ìyá rẹ si jẹ Alaja Wolemotu Ajibabi Adetona (nee Onasile). Gẹ́gẹ́ bí ọba, Ó jẹ aṣojú fún ìdílé ọba Anikilaya.[1]Oba Sikiru Kayode Adetona ti lo ogota odun o le odun meji lori alefa awon baba nla won,

Sikiru Kayode Adetona

Ọ̀dọ́mọdé ọmọ ọba Adetona lọ sí oríṣiríṣi ilé ẹ̀kọ́ bi i ilé-ẹ̀kọ́ ti onítẹ̀bọmi (Baptist) tí ó wà ní Eroko ní Ìjẹ̀bú Òde; ilé-ẹ̀kọ́ alakọbẹrẹ Ogbere United tí ó wà ní Òkè-Àgbò ní Ìjẹ̀bú Igbó, àti ilé-ẹ̀kọ́ Ansar-Ud-Deen ni ́Ìjẹ̀bú Òdé laarin ọdún 1943 sí ọdún 1950. Ní ìtẹ̀síwájú lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ gíga ti koleeji, Ó lọ sí koleeji Olú-Ìwà (Èyí tí ó di Adeola Odutola bayi) tí ó wà ní Ìjẹ̀bú Òde láti ọdún 1951 sí ọdún 1956. Laarin ọdún 1957 sí ọdún 1958, ó ṣe iṣẹ́ pẹ̀lú ẹ̀ka tí ó nṣe àyẹ̀wò nípa owó ní Ibadan. Ní ọdún 1958, ọmọ ọba Adetona kọ̀wé fi iṣẹ́ sílẹ̀ láti tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ lórí olùṣírò owó (Accountancy) ní ìlú aláwọ̀ funfun (United Kingdom), ìlú tí nse àkoso orílẹ̀ èdè Naijiria nigba na.

Látipasẹ̀ lẹ́tà ti wọ́n kọ ni ọjọ́ kẹrin oṣù kini ọdún 1960, èyí ti akọ̀wé àgbà ti ìjọba ìbílẹ̀ fi ránṣẹ́ si olùdámọ̀ràn ìjọba ìbílẹ̀ ti Ìjẹ̀bú òde Pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà baalẹ ìgbìmọ̀ fún agbègbẹ̀ ìwọ̀ oorun fún yínyàn ọmọ ọba Síkírù Káyọ̀dé Adétọ̀nà gẹ́gẹ́ bi ọba àti fífi ẹsẹ̀ rẹ múlẹ̀ gẹ́gẹ́ bi Awujale ti ilè Ìjèbú láti ìgbà ti wọ́n ti kọ lẹ́tà yi ni ọjọ́ kẹrin oṣù kini ọdún 1960. Èyí lo mú ki àwọn olókìkí ọmọ ilẹ̀ Ìjẹ̀bú bi i olóògbé Ọ̀gbẹ́ni-Ọjà, Olóyè (dọ́kítà) Timothy Adéọlá Òdútọ́lá, Bòbasuwà 1 Olóyè Emmanuel Òkúsànyà Òkunọwọ àti Aṣíwájú, Olóyè Samuẹl Olátúbọ̀sún Shonibarẹ ṣe ètò ìpàdá bọ ọba ti wọ́n ṣẹṣẹ yàn wa sílè. Ní ọjọ kejìdínlógún oṣù kini ọdún 1960, olórí ìgbìmọ̀ afọbajẹ ti ilẹ̀ Ìjẹ́bú, Ọ̀gbẹ́ni-Ọjà, Olóyè Timothy Adéọlá Òdútọ́lá ṣe àfihàn ọba tuntun fún gbogbo àgbáyè. Àfihàn yi ni ó jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ayẹyẹ fifi ọba ti wọ́n ba ti yàn si orí ìtẹ́. Eleyi jẹ́ ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀tun fún àwọn ọmọ Ìjẹ̀bú. Lẹ́hín èyí ní ọba ti wọn yàn yi yio tẹ̀síwájú lọ si Ìpẹ̀bí ni "Odo" fún oṣù mẹ́ta.

Ọba Síkírù Káyòdé Adétọ́nà, ẹni ti "ODIS" tí kọ́koọ́ yàn pẹ̀lú àwọn marun miran ni àwọn afọbajẹ pawọ́pọ̀ mu ni ìbámu pẹ̀lú abala ìkọkànlá òfin òye jíjẹ ti ọdún 1957 ní agbègbè ìwọ òorùn ilẹ̀ Nàíjírià. Gómìnà nìgbà na fi ọwọ́ si yíyàn Síkírù Káyọ̀dé Adétọ̀nà gẹ́gẹ́ bi Awujalẹ ti ilẹ̀ Ìjẹ̀bú. Ayẹyẹ igbade waye ni ọjọ Abamẹta ti i ṣe ọjọ́ kejì, oṣù kẹrin ọdún 1960.

Ni ọjọ́ Ìṣẹ́gun ti i ṣe ọjọ́ karun oṣù kẹrin ọdún 1960, ọba tuntun, ọba Adétọ̀nà darapọ̀ mọ àwọn ọba ti agbègbè ìwọ òorùn lẹ́hìn ti wọ́n ti ṣe àfihàn rẹ. Ọba Síkírù Káyọ̀dé Adétọ̀nà jẹ aláànú ọba. Èyí lo mú ki àwọn ọba àti àwọn ìjòyè dárúkọ rẹ gẹ́gẹ́ bi àarẹ fún ìgbìmọ̀ lọ́ba lọ́ba. Sùgbọ́n ẹni tí o ti dàgbà ti o si tún jẹ àgbà ọba gẹ́gẹ́ bi ìṣẹ̀dálẹ̀, olóògbé sir Adésọjí Adérẹ̀mí, Òoni ti Ilé-Ifẹ̀ ni wọn padà wa yàn gẹ́gẹ́ bi i àarẹ. Èròngbà wọn ní pe gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́modẹ́ ọba, Àwújálẹ̀ ti O jẹ ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún yio ni akitiyan fún ipò gíga yi. La i se aniani, èròngbà yi lo mu ki wọn gbà Àwújálẹ̀ ti ilẹ̀ Ìjẹ̀bú gẹ́gẹ́ bi ẹni ọ̀tọ̀.

  1. "Seven interesting facts about Awujale of Ijebu at 85". Latest Nigeria News, Nigerian Newspapers, Politics (in Èdè Latini). 2019-05-10. Retrieved 2020-03-03.