Ìjẹ̀bú

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí

ÌTÀN ÌJÈBÚ ÀTI ÈKA ÈDÈ ÌJÈBÚ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ìjèbú jé òkan lára àwon èyà èdè Yorùbá. Ó sòro láti so pàtó ìgbà tí a dá ìlú Ìjèbú sílè nítorí pé àwon àgbà tí a fi òrò wá lénu wò won kò mò-ón-ko tàbí mò-ón-kà. Sùgbón wón so wí pé “Ajebú” ni orúko eni tí ó dá ìlú Ìjèbú sílè n jé.

Ajebú àti Olóde jé ode. Gégé bí wón ti so, níbi tí enìkòòkan won ti n de igbó kiri ni wón ti pàdé ara won nínú igbó. Báyìí ni wón se di òré tímótímó. Ní ojó kan, wón dá ìmòràn láàrin ara won pé ó ye kí wón dá ibìkan sílè tí àwon yóò fi se ìbùgbé léyìn tí wón bá se ode lo. Wón lo bi Ifá léèrè, Ifá si se atónà Ajebú wí pé kí ó lo tèdó sí ibi kan, èyí tí à n pè ní Imèpè. Olóde àti Àjànà darapò wón te ibi tí à n pè ní Ìta Ajànà dó, èyí sì wà ni ìlú Ìjèbú-Òde títí di òní yìí.

Ibojì Ajebú wà ní Imèpè lébàá ojà Òyìngbò lónà Èjirín tí Olóde sì wà ní ibi tí à n pè ní “Itún Olóde” ní Ìta Àjàná títí di òní yìí. Àwon méjì tí ó jé akíkanjú jùlo ìyen Ajebú àti Olóde ni a pa orúko won pò tí ó wá di “AJÉBU-OLÓDE” èyí tí à n pè ní ÌJÈBÚ-ÒDE títí di òní olóni yìí.

Èdè Ìjèbu ni àwon èyà yìí máa n so. A sì le rí won káàkiri ilè Nàìjíríà. Àpeere àwon ìlú tí a lè rí ni ekùn Ìjèbú ni Ìjèbú-Òde, Musin, Ata-Ìjèbú, Imòpè, Òdo-Pótu, Àgó-Ìwòyè, Ìjèbú-Igbó, Orù, Awà, Ìlápòrú, Ìsònyìn, Ìpàrí-Nlá, Òdokálàbà, Ìdowá, Merígò, Òdoogbolú, Òsosà àti béè béè lo.

Ìtàn so pé Ilé-Ifé ni wón ti sí wá. Àtipé wón pèlú àwon tí ó bá Odùduwà kúrò ní Mékà nígbà tí àwon Mùsùlùmí gbógun ti wón. Adétoun (2003:1) sàlàyé pé orí ìtàn àtenudénu ni ìtàn Ìjèbú àti ìsèdálè won dá lé. Òkan nínú àwon ìtàn wònyìí so pé Òbánta ni ó kó àwon Ìjèbú kúrò ní Ilé-Ifè wá tèdó sí Ìjèbú-Òde Ìtàn mìíràn fi ìdí rè múlè pé orísun àwon Ìjèbú ni Wàdáì. Olú-Ìwà ni eni tó se atónà won wá sí ilè Ìjèbú. Ajébu àti Olóde tèlé Olú-Ìwà nínú ìrìnàjò won wá sí agbègbè Ìjèbú. Wón sèdàá orúko ìlú Ìjèbú-Òde láti ara àpapò orúko Ajébu àti Olóde tí ó jé àtèté tó gbajúgbajà.

Adétoun gbà pé àwon Ìjèbú tí wón sí wá sí orílè-èdè Nàìjíríà ni a lè bá ní abé òwó méfà òtòòtò. Òwó àkókó ni wón wà lábé Olú-Ìwà tí àwon ègbón rè Ajébu àti Olóde tèlé àwon wònyìí ni wón te òpòlopò ìletò dó ní ìlú Ìjèbú-Òde. Òwó kejì ni àwon tó wà lábé Arisu ìbátan Olú-Ìwà. Ògborogondá tí a mò sí Òbánta tí o n wá Olú-Ìwà baba baba re tí ó ti kú kí ó tó dé ni ó jé ìpín keta.

Àjàlórun àti Balufé ni ó jé adarí òwó kerìn. Èbúmàwé àti Òsémàwé ni ó wà ní ìpín karùn ún. Àwon wònyìí ni ó n gbé ní Àgó-Ìwòyè. Òwó kefà ni Koyolu àti Elépèé àkókó tí wón wá láti Ilé-Ifè láti se àwárí òwó ti Obanta. Wón dé ní Òrùndún keje. Àwon wònyìí ni ojúlówó Ìjèbú-Rémo ní ìpìlè