Ifá

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
Lọ sí: atọ́ka, àwárí
Àwọn Odù mẹ́rindínlógún
Name 1 2 3 4
Ogbe I I I I
Oyẹku II II II II
Iwori II I I II
Odi I II II I
Irosun I I II II
Iwọnrin II II I I
Ọbara I II II II
Ọkanran II II II I
Ogunda I I I II
Ọsa II I I I
Ika II I II II
Oturupọn II II I II
Otura I II I I
Irẹtẹ I I II I
Ọsẹ I II I II
Ofun II I II I

Sixteen Principal Afa-du
(Yeveh Vodou)
Name 1 2 3 4
Gbe-Meji I I I I
Yeku-Meji II II II II
Woli-Meji II I I II
Di-Meji I II II I
Abla-Meji I II II II
Akla-Meji II II II I
Loso-Meji I I II II
Wele-Meji II II I I
Guda-Meji I I I II
Sa-Meji II I I I
Lete-Meji I I II I
Tula-Meji I II I I
Turukpe-Meji II II I II
ka-Maji II I II II
Ce-Meji I II I II
Ose orogbe II I II I
Fu-Meji II I II I


Ifá jé òrìsà kan pàtàkì láàrin àwon Yorùbá. Àwon Yorùbá gbàgbó wí pé Olódùmarè ló rán ifá wá láti òde òrun latí wá fi ogbón rè tún ilé ayé se. Ogbón, ìmò, àti òye tí olódùmarè fi fún ifá ló fún ifá ní ipò ńlá láàrin àwon ìbọ ní ile Yorùbá. “A-kéré-finú-sogbón” ni oríkì ifá.

Ìgbàgbó Yorùbá ni wípé ní ìgbà kan rí, ifá gbé òde-ayé fún ìgbà pípé kí o tóó padà lo sí òrùn. Ní ìgbà tí ifá fi wà ní ilé ayé, ó gbé ilé-ifè fun ìgbà péréte. Sùgbón ní ìgbà tí òrùnmìlà fi wà láyé yìí naa, a tún maa lo sí òde òrun léèkòòkan tí olódùmarè bá pèé láti wá fi ogbón rè bá òun tún òde-òrùn se. Nítorí náà gbáyégbórun ni ifá ńse.

Ìtàn so fún wa wipe omo méjo ni òrúnmìlà bí nígbà tí ó wà láyé, nígbà tí ó di ojo kan ti òrùnmìlà ńse odún ni òkan nínú àwon omo yìí tíí se àbíkèhìn pátápátá báse àfójúdi sí òrúnmìlà, ni òrùnmìlà bá binú fi ayé sílè lo sí òde orun. Ni ìfá bá relé olókun kòdé mó. Ó léni té bá ri i, e sá maa pè ní baba”. Sùgbón òrùnmìlà fún àwon òmo rè méjèèjo náà ní ikin mérìndínlógùn ó ní be e délé bee bá fówóó ní, eni tè é maa bi ninu.

Ìkín mérìndinógun náà ni à ń lò lòníí láti bèèrè nnkan lówó ifá.

DÍÈ LARA ÀWON OHUN ÈLÒ IFÁ DÍDÁ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Orísìírísìí ni àwon ohun èlò tí àwon babaláwo fi í da ifá ikin ifá ni àdáyéná nínú wón. Ikin ifá jé mérìndínlógún. Ohun èlò ifá-dídá míìran ni òpèlè, èyí ló wópò jù fún ifá dídá ní ayé òde òní. Àwon babalàwo máa ńsábàá lo ikin ifá (èkùró ifá) nígbà tí wón bá mbo ifá ní oòdèè won, wón a sì lo òpèlè fun ará òdé tí ó wáá da ifá lódòo won láti ibi èso igi òpèlè ni a ti ń mú òpèlè ifá.

Ohun èlò ifá dídà míìran ní ìróké tàbí ìrófá èyí jé óá gbóńgbó kan báyìí tí a ńmú lu opón ifá bí a bat í ńki ifà lo àwon olóyè ifá a máa fi ehín erin gbé ìrókée ti won.

Ohun èlò ifá dídá míìran opón ifá, nínú opón ifá ni a ní lati kó gbogbo ohun èlò ifá dídá tí a ti ká sílè wonyìí sí bá a bá ti ńdá ifá. Orísi opón ifá ló wà opón kékeré wà, opón ńlá sì wà pèlú.

Àwon babaláwo a máa ní owó eyo àti égúngún nínú ohun èlò ifá dídá won, owó eyo dúró fún béèni, egungún sì dúró fún béè ko nígbà tí a bá di ìbò béèrè nnkan lówó ifá-owó-eyo àti égúngún yìí tí a dì mówó ni à ń pè ni ìbò.

Gbogbo ohun èlò ifa dídá tí mo kà sílè yìí ni a ńkó sínú àpò kan tí àwon babaláwo ńgbé kó èjìká báyìí tí à ń pè ni àpòo jèrùgbá, enikéni tí o bá nko àpò yìí ni à ń pè ní akápò ifá tàbí babaláwò.

EBO IFÁ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ebo rírú se pàtàkì fún eni tí a bá dá ifá fún. bí ifá tí a dá fún ènìyàn bá se rere tàbí búbúru, oní tòhùn ni lati rúbo kí ohun tí ó dá ifá sí náà ó lè baà dará: lónà kìní:- Ebo ifá jé ounje fún òrìsà tí ifá bá so wí pé kí á rúbo, Fun àpeere, tí ènìyàn bá fé se nnkan. ti o ba bèrè lówó ifá, wón le so pé ki o lo rubo fun ògun, Ebo ifá jé ètùtù pàtàkì nítorí tí Babaláwo bání kí ènìyàn se nnkan óní láti se é, ki òun pàápàá ólè ba à ni ìgboyà wípé àteégún-àteésà, nítori èyí ní àwon babaláwo fi máa ńwí fún ení tí a ní kí ó rúbo pé kí ó wá oúnje fún àwon aládùgbóó re.

ÈSÙ ATI IFÁ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Bí a ba wo ilé àwon babaláwo, a ó ri i wí pé ère Èsù kìí wón nibè. Yangí ńlá kan o máa wà ní èbá ilé àwon babalawo. Yangí yìí dúró fún àmì Èsù. Ìgbà gbogbo ni àwon babaláwo máa gbé eboo lo si ibé, nwon a máa bu epo lé yangí náà lórí, a máa rin sún nígbà gbogbo.

Òpòlopò ni ese ifá tí o je mo Èsù. Nígbà míìran, Èsú jé ìrán ńsé fún ifá. Nígbà miran èwè, Èsú sí dá bí eni tí ńfún ifá ni agbára. Nínú ese ifá a lè rí ohun tí o jo bayin “…ni òrúnmìlà ba ti àse Èsù bonu”. ìtumò èyí ni wí pé bí ifá bá féé se nnkan lile ti ó rí bí idan, àse Èsù ló ní láti lò. Nígbà mìíràn, Èsù jé olùrànlówó fún ifá. Nígbà mìíràn, Èsù sì jé olùdánwò fún ifá.

Oríkì Èsù tí ó wà nísàlè yí ti fi hàn wà gba-n-gba pé Èsù kì ba enìkan sòré

Oríkì Èsù nìyí: “Òkú yan omo tié lódì átóńtórí omo olomo”.

IPÒ IFÁ LAARIN ÒÒSÀ YÓKÙ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Ifá jé agbòràndun fún gbogbo àwon òrìsà yókù. Bí eégún ilée baba eni ba féé bínú sí ni, láti odo ifá ni a ó ti gbò èyí wáá fún ifá ni ipo asojú fún gbogbo àwon irúnmolè yókù. Bí kò bá sí ifá, iyì àti olá ti àwon Yorùbá mbú fun gbogbo àwon òrìsà ilèe Yorùbá ró, tí ó sì nwà ońje sí won lénu.

Gégé bí a ti so síwájú, àwon omo òrúnmìlà ni òrúnmìlà fún ní ikin ifá mérìndínlógún nígbà tí ó padà lo si òrun tí ló sí wa sílé ayé mó.

Nígbà tí a bá ń sòrò ìkín, a kò ni se aláìménuba àwon ojú odù mereerindínlógún nítori ìkín mérìndínlógún náà ni à ń lò lónìí láti bèèrè nnkan lowo ifá. Àwon ojú odù mérìndínlógún àti bí wón se to tèle ara won:

(1) Èjì Ògbè

Eji ògbè Esè kínní

“Gbogbo orí àfín ewú

Abuké ló rerú òòsà mósò

Lààlààgbàjà ló ti isé è de

Adíá fún òrúnmìlà

Níjó ti ńlo rèmí omo olódùmarè sóbìnrin Esè kejì.

Eri ńlá níí sunkún ibú

Agbara giri nii sunkun ògbun

Adíá fun Aadelówo nífè

Nwón ní ó ká a kío móle

(2) Oyeku méjì,

(3) Ìwòrí méjì,

(4) Òdí méjì,

(5) Ìrosùn méjì,

(6) Owónrin méjì

(7) Obara méjì,

(8) Òkànrùn méjì,

(9) Ògúndá méjì,

(10) Ìká méjì,

(11) Ótúúrúopon méjì,

(12) Òtúá méjì

(13) Òsá méjì,

(14) Ìretè méjì

(15) Òsé méjì,

(16) Ofún méjì,

ÀWON OMO ODÙ[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

Léyìn àwon ojú odù méríndinlógún yìí, àwon òjìlérúgba odù míràn tún wà tí à ń pè ni omo odù tàbí àmúlù odù wón jé omo odù nitorí pé a gbà pé won se omodé si àwon ojú odù, à ń pè wón ni Àmúlù odù nítorí pé orúko odù méjì ni òkòòkan wón jé. F.A., èkíni nínú àwon odù wònyìí a máa je ogbeyèkú.

Àwon Yoruba ka àwon odu wònyú si òòsà pàtàkì jùlo, àwon ojù odú. F.A. Ese-ifa òwònrín méjì

(a) Ikin níi fagbáríí selé

Àtàrí ni o jóòrún ó pagbin ìsàlè

Olobonhunbonhun ni fapa ara re dá gbèdú.


Ninu asa Yoruba Ifá A ti rí i ni ojú ewé 46 Apa Kini ìwe yi irú ipò pataki ti Orìsà-nla tabi Obàtálá kó laarin awon òrìsà ati irúnmalè ile Yoruba. A ti gbó pelu pe jákè-jádò gbogbo ilè Yorùbá ni nwon maa mbó ó, nitoripe oun ni awon àgbà àtijó gbà ninu ìtàn ìsèdálè won pe o je igbákejì Olódùmarè, ti o si nràn an lówó lati tún enia dá nipa fífún un ni ojú, imú, eti, ati gbogbo èyà ara miran ti o ye ki èdá ní ki o fi lè di enia pipe. ...


Iwe fun kika[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]

  • J. F. Odunjo (1969), Eko Ijinle Yoruba, Alawiye Fun Awon Ile Eko Giga, Apa Keji, Longmans of Nigeria, Ojú-ìwé 78-87.
  • E. A Lijadu (1895) Ifa Mimo Alabalase United Star printers Ltd.
  • P.O. Ògúnbòwálé (1980) Àwon Irúnmalè Ilè Yorùbá Evans Brothers (Nigeria Publishers) Limited. ISBN 978-167-090-8.
  • Débò Awé (2006) Àkóyawó Àlàyé Àti Ìbéèrè lórí Àwon Ojú Odù Ifá Elyon Publishers Ilésá. ISBN 978-2148-25-3.