Babaláwo
Babaláwo gbólóhùn yí jẹ́ gbólóhùn alákànpọ̀ (Bàbá) àti (Aláwo) tí ó túmọ̀ sí bàbá tí ó nímọ̀ ní awo ṣíṣe, yálà awo Ògbóni tàbí awo mìíràn. Àmọ́, Babaláwo túmọ̀ sí ẹni tí ó yanṣẹ́ awo ṣíṣe láàyò pàá pàá jùlọ̀ Ifá dídá láti máa fi ṣiṣẹ́ yẹ̀míwò fún àwọn ènìyàn. Irú ẹni yìí ma ń dáfá káàkiri ìgbèríko àti agbègbè rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú àṣe tí ifá bá paá. Babaláwo yàtọ̀ sí Oníṣègùn, nínú iṣẹ́ ìbílẹ̀ abínibí ilẹ̀ Yorùbá.
Iṣẹ́ Awo ṣíṣe gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ abínibí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
púpọ̀ nínú àwọn babaláwo ayé àtijọ́ àti díẹ̀ nínú àwọn tòde òní ni wọ́n jẹ wípé wọ́n bá iṣe awo ṣíṣe nílé tí wọ́n sì jogun ba lọ́wọ́ àwọn baba-ńlá baba wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìdílé àti abínibíbí wọn. Nígbà tí ọ̀pọ̀ má ń lọ fira wọn jìn tàbí ṣọfà sọ́dọ̀ Onífá kan láti mọ̀ tàbí kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ifá dídá. Lẹ́yìn ọọ̀pọ̀ ọdún wọn yóò mọ̀ nípa bí a ti ń dáfá tì wọ́n yóò sì dẹni ara wọn pẹ̀lú.[1]
![]() |
Àyọkà yìí tàbí apá rẹ̀ únfẹ́ àtúnṣe sí. Ẹ le fẹ̀ jù báyìí lọ tàbí kí ẹ ṣàtúnṣe rẹ̀ lọ́nà tí yíò mu kúnrẹ́rẹ́. Ẹ ran Wikipedia lọ́wọ́ láti fẹ̀ẹ́ jù báyìí lọ. |
àwọn ìtọ́ka sí[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]
- ↑ "Iwe fun Odu Ifa: Ancient Afrikan Sacred Text". Kilombo Restoration & Healing. Retrieved 2019-03-14.