Anthony Joshua
Anthony Olúwafẹ́mi Ọláṣeéní Jóṣúà (tí wọ́n bí ní Ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún oṣù kẹwàá odun1989) jẹ́ gbajúmọ̀ Ajẹ̀ṣẹ́ ọmọ bíbí ṣagámù ni ìpínlẹ̀ Ògùn orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, ṣùgbọ́n tí ó ń ṣojú orílẹ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì gẹ́gẹ́ bí ajẹ̀ṣẹ́. Òun ni Ajẹ̀ṣẹ́, Ẹlẹ́ṣẹ̀ẹ́ (Afẹ̀ṣẹ́ kù bí-òjò) tó lágbára jùlọ ni àgbáyé lọ́wọ́́lọ́wọ́ báyìí látàrí àmìn-ẹ̀yẹ Ajẹ̀ṣẹ́ tí IBF, WBO, àti IBO tí ó ti gbà láti ọdún 2016 sí 2019. Lọ́jọ́ keje, oṣù Kejìlá ọdún 2019, ó na ẹlẹ́ṣẹ̀ẹ́ ẹgbẹ́ rẹ̀, Andy Ruiz Jr nínú ìjàdíje tí ó wáyé lórílẹ̀ èdè Saudi Arabia . Andy Ruiz Jr tí kọ́kọ́ nà án lóṣù karùn-ún ọdún 2019, tí ó sì gba gbogbo bẹ́líìtì àmìn ẹ̀yẹ rẹ̀. Ṣùgbọ́n gbogbo bẹ́líìtì àmìn ẹ̀yẹ yìí ni Anthony Joshua gbà padà báyìí. [1][2]
Bákan náà, òun ni alámì ẹ̀yẹ tí British and Commonwealth Heavyweight láti ọdún 2014 sí 2016. [3] [4]
Àwọn Ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Penn, Matt (2019-12-08). "Joshua vs Ruiz 2 LIVE: Anthony Joshua beats Andy Ruiz to win back world heavyweight titles". Express.co.uk. Retrieved 2019-12-08.
- ↑ "Ruiz Jr vs Joshua 2: Booking information for Anthony Joshua's epic rematch with Andy Ruiz Jr". Sky Sports. 2019-12-07. Retrieved 2019-12-08.
- ↑ "Anthony Joshua". Forbes. 2019-08-14. Retrieved 2019-12-08.
- ↑ "Anthony Joshua Profile - Anthony Joshua Wikipedia - Anthony Joshua Biography". LATEST NIGERIAN NEWS BREAKING HEADLINES NEWSPAPERS. 2017-05-02. Retrieved 2019-12-08.